YO/Prabhupada 0440 - The Mayavadi Theory is that the Ultimate Spirit is Impersonal



Lecture on BG 2.8-12 -- Los Angeles, November 27, 1968

Prabhupāda: Tesiwaju.

Olufokansi: Ninu Śvetāśvatara Upaniṣad, wan salaaye wipe Olorun ni oluso gbogbo awon eda aye yi, ninu gbogbo orisirisi ise tonse Eledumare yi si wa ninu okan gbogbo awon eda. Awon eda mimo nikan ton l'oju lati ri ninu ati n'ita awon eda, lon le ni alaafia tayeraye. Otooro kannna lon salaaye si Arjuna, ati gbogbo awon eda laye yi ton sebi wipe won keeko sugbon kos'ogbon kankan lori won. Olorun gan to salaaye pe Oun, Arjuna atiawon Oba ton pejo lori ile ogun, pe eda tayeraye ni gbogbo won, ati wipe Olorun fun ara re lon toju gbogbo won."

Prabhupada: Lati ese iwe wo? Ka fun wa.

Olufokansi: " Kosigba t'emi, tab'eyin tabi awon oba... (BG 2.12)"

Prabhupada: Nisin, " Kosigba kankan t'emi, tab'eyin tabi awon eyan wanyi." Nisin O salaaye wipe, "Emi, iwo, ati..." Eyan talakoko, tikeji ati tiketa. O wani pipe. "Emi, iwo ati awon iyoku." Beena Krsna sowipe, " Kos'asiko kankan temi, iwo, ati awon eyan wanyi to wa lori ile ogun yi ti wa tipe tipe." Itumo re niwipe " Teletele, Emi, iwo, ati awon iyoku, gbogbo wan lon wa." Leyokankan. Imoye awon Mayavadi ni emi to gaju lori eto pe Olorun o kin seyan. Lehin na bawo ni Krsna sele sowipe " Kos'igba kankan temi, eyin ati awon eyan wanyi o wa laaye"? Itumo re niwipe, " Mo wa laaye beyin na se wa laaye, gbogbo awon eyan wany na to wa ni waju wa si wa laaye tipetipe. Kos'igba kankan." Nisin, kini idaaun teni, Dinadayala? Krsna sowipe kosi'gba tawa paapo. Eyan ototo ni gbogbo wa. Osi sowipe, " Kosi'gba tawa ... Kosi'gba kankan tawa ma se alai wa laaye." Itumo re niwipe teletele awa base wayi, lasiko tawayi na asi wa gege na, lojoowaju asi ma wa base wa nisin. Nibo wa ni eto aimasi laaye tiwa? Ni asiko to koja, nisin, lojowaju, asiko meta lowa. Huh? Nigbogbo asiko tawayi eda nigbogbo wa je. Lehin na nigbawo l'Olorun di alaiseyan, tab'emi, tab'eyin? Nibo laaye na wa? Krsna ti salaaye wipe, "Kos'asiko kankan temi, eyin tabi awon oba wanyi tabi awon jagunjagun... Konse pe awa osi laaye teletele." Beena teletele gbogbo wa lawa laaye, lasiko tawayi, kosejo na. Asi wa laaye. Akeeko temi leje, Olouko nimo je siyin, sugbon gbogbo wa si wa loototo. teyin o be feran nkan timon so, e le fimisile. Nkan tose yin leyan toyato niyen. Beena teyin o ba feran Krsna, kosi besele ni imoye Krsna, nkan to seyin leda otooto niyen. Beena eto yi si lo bayi. Gege na ti Krsna o ba nife siyin, o le ma daun si imoye teni fun. konsepe nitoripe eyin tele awon ofin wanyi, Krsna gbodo daaun gba nkan teyin se. Rara. Toba rowipe " Iranu leniyi se, mio le gba sokan," A tiyin segbe kan. Beena Oun na lese bose fe, eyin na lese besefe, gbogbo wa lale se basefe na. Nibo ni eto aima seyan yi tiwa? Kosejo na. Teyin o ba nigbagbo ninu Krsna ati awon Veda, lehin gbogbo nkan na, Krsna ni Olorun gbogbo eda. Lehin na tawa o ba ni igbagbo, bawo lase fe ni ikosiwaju ninu imoye wa? Kolese se. Beena kosejo pe eyan ototo nigbogbo wa. Oro awon olori leleyi. Nisin, leyin oro awon olori, egbodo fi ogbon ati ijiyan fi ro. Seyin le sofun nibi ti awon eyan o kin jiyan? Rara. Ele sewaadi fun ara yin, ninu awon ebi, ninu awon awujo, ninu awon orile-ede, kos'àdéhùn kankan Ninu ile isofin, ati ni ilu yi na. Kasowipe ninu ile isofin, gbogbo awon eyan gbodo ronu nipa ilosiwaju orile-ede na, sugbon wa ronu nipa nkan to wa lokan won. Awon eyan rowipe " Ilosiwaju ilu si wa pelu nkan timo fe." Bibeko, kilode ti awon eyan sen dibo fun ipo Olori? Gbogbo eyan sowipe " Nixon se pataki fun America." Elomi sin sowipe, " Mose pataki fun America." Beena, kilode eyin mejeji? teyin mejeji ba je olugbe America. Kosejo pe eyato. Ironu Mr. Nixon yato si ironu Mr. bayi bayi. Ninu ile isofin, ni iparapo awon orile-ede, gbogbo eya lon ja fun nkan ton ro. Bibeko, kilode toje pe awon ipe-àkíyèsí-sí orisirisi wa laye yi? Kosi biti eto aima seyan yi wa. Eyan ototo ni gbogbo wa je. nibikibi, eyna ototo laje. Agbodo gbabee. Agbodo lo ogbon ori wa, lati mo, lati gba nkan ti awon olori ti so. Lehin ele ni idaaun si ibere na. Bibeko o le gan.