YO/Prabhupada 0476 - Dependence is Not Bad if There is Dependence on the Proper Place



Lecture -- Seattle, October 7, 1968

Mio mope mo gbodo teriba, latile ni aye pelu idunnu, mogbodo teriba. Gege bi omo kekere, toba teriba si nkan ti awon obi re fe, ile aye re ma dun. Ti omo-obirin ba teriba si ife awon obi re, Ilana towa niyen, ilana Veda Awon obinrin gbodo gbekele enikan. Ti awon obinrin bafe se bose wuwon, ile aye re ba kun fun ibanuje. Emi ko ni mo da awon nkan wanyi sile, Mon soro lori awon ofin Veda to daju. Manu-samhita, awon ofin Veda, olori agbaye, Manu... Manu ni baba agbaye. Beena o si ko iwe ofin funwa. Awon Hindu ni oriled-ede India sin tele awon ofin ninu iwe-ofin Manu Samhita Beena ninu iwe Manu-samhita yi, wan salaaye wipe, na striyaṁ svatantram arhati. O sowipe awon obinrin o gbodo wa laini eyan ton toju won. Lehin na? Kiloye kan se? Titi digba ti oma se igbeyawo, obinrin na gbodo wa pelu awon obi re. lesekese toba ti se igbeyawo, ogbodo gbe pel'oko re. ti oko re ba ti jade... nitoripe ninu asa Hindu, oko ogbodo wa ninu ile re titi digba to ma ku. Rara. ti awon omo re ba ti dagba, asi fi iyawo re sile ati awon omo, lehin na asi di sannyasi, gege bi mose di nisin. Moni awon omo mi, ati awon omo-omo mi, Iyawo si .. sugbon mio ni nkankan se pelu e mo. bawo ni iyawo mi ase toju ara re na? O ti ni awon omo toti dagba. Beena kosi isoro kankan. beena nkan buru ko loje teyan ba nigbekele, kadaa ibi toda lo gbe igbekele re si. Kosi baba kankan tio ni toju omo-obinrin re tio ti se igbayawo, tabi awon omo-obirin at'okurin re tio t se igbeyawo. Ninu asa Hindu, ise baba ati ti'ya ti tan lehin igba ti awon omo re ba se igbeyawo, okurin tab'obirin. Ise na po gan. Lehin na ni ise won ma tan. Mon soro lori eto igbekele. Nkan buruku kol'eto na. Moti ri ibi ti awon obinrin ti teriba fun oko won.. Beena awon obirin to po gan wa ni India, inu won si dun gan, ile aye won si daa. Agbodo ko bonsen se awon nkan wanyi. Ominiran eke yi o da rara. Niotooro awa o ni ominiran kankan. mole ronu nipa ominiran yi, sugbon kosi ominiran kankan. Iranse iye ara mi nimo je. Kāmādīnāṁ kati na katidhā pālitā durnideśa. Gbogbo wa lan sise fun iye ara wa. Nibo ni ominiran na wa? Mole sowipe moni ominiran lati baba mi, lati ipinle mi, lati orile-ede mi, lati awujo mi, sugbon iranse iye ara mi nimo je. Nibo ni ominiran na wa? Beena agbodo mo nipa ipo wa, pe ni gbogbo nkan awa gbodo gbekele nkan. Nitorina pipe aye mi, ma wa tinba nigbekele lori Oluwa, Krsna. Ona abayo si gbogbo isoro wa leleyi. imoye Krsna yi ri bee. E gbiyanju lati mo nipa ipo yin, kesi teriba fun Oluwa Krsna. Lehin na inu yin ma dun. Nkan to rorun ni. Lesekese teyin ba teriba s'Oluwa, lesekese leyin ma ni idunnu. Mām eva ye prapadyante māyām etāṁ taranti te.