YO/Prabhupada 0655 - The Purpose of Religion is to Understand God, and to Learn How To Love God



Lecture on BG 6.6-12 -- Los Angeles, February 15, 1969

Olufokansi: " Bhagavad-gita ni sayensi nipa imoye Krsna. Koseni tole ni imoye Krsna pelu ikeeko iwe lasan."

Prabhupada: Beeni. Nitoripe eyin tini awon iwe-eri: M.A., Ph.D., D.A.C., eyin le ni oye nipa Bhagavad-gita, kolese se. Sayensi pipe leleyi. Eyin gbodo ni iye ara to yato lati ni oye nipa re. Eyin gbodo ya iye ara yin si mimo pelu ise ifarafun s'Oluwa. Bibeko, awon alakowe pataki gan, bi awon dokita ati awon alamodaju Ph.D., wonse asise nipa eyan ti Krsna je. Kole ye won. Kolese se. Nitorina ni Krsna se wa boseje. Ajo 'pi sann avyayātmā (BG 4.6). Botilejepe alainibere loje, Asi wa lati fi hon wa bi Olorun seri, seri bayi? Tesiwaju.

Olufokansi: " Eyan gbodo s'orire gan lati ni asepo pelu awon eyan ton wa ninu imoye mimo yi. Eni toni imoye Krsna si ni imoye to daju pelu ore-ofe Krsna."

Prabhupada: Beeni, pelu ore-ofe Krsna. Konse pelu ikeeko lasan. eyin ... agbodo ni ore ofe Krsna, lehin na ale ni oye nipa Krsna. Lehin na le ri Krsna. Lehin na ale soro pelu Krsna, lehin na ale se gbogbo nkan. Eyan loje. Eda to gaju. Imoye Veda niyen. Nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām (Kaṭha Upaniṣad 2.2.13). Eda to gajui loje, tabi eda tayeraye. Gbogbo wa lawa tayeraye. Nisin awa ti ni idimu ninu ara eda yi. Awa ti pade ibimi ati iku. Sugbon looto awa o ni ibimo ati ikun kankan. Emi tayeraye niwa. bi ise mi seri, bi awion ife okan mi seri, beena nimo sen paaro ara eda kan sikeji, ikan sikeji. Nkan ton sele niyen. Looto mio ni ibimo tabi iku kankan. Wanti salaaye ninu Bhagavad-gita, ninu apa keji, ele ka: na jāyate na mriyate vā. Awon eda aye yi o le ni ibimo tabi kan ku. Beena, Olorun wa tayeraye, eyin na wa tayeraye. Nigbateyin ba ni ibasepo tayeraye pelu eda towa tayeraye... Nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām. Oun l'eda to gaju laarin gbogbo eda. Oun lo gaju laarin gbogbo awon eda tayeraye. Beena, pelu imoye Krsna, ti iye ara wa ba yasi mimo, ema ni imoye yi lehin na ema ri Olorun. Tesiwaju.

Olufokansi: Eni toni imoye Krsna ni imoye to daju, pelu ore-ofe Krsna, nitoripe oni itelorun pelu ise ifarafun s'Oluwa. Pelu imoye to daju yi, eyan le di pipe. Pelu imoye pipe yi eyan le nigbagbo to daju, sugbon pelu imoye lasan eyan le ni idamu lokan pelu awon idamu wanyi. Awon eda ton ti mo nipa araeni, awon lon ni idari lori ara won, nitoripe wan ti teriba fun Krsna. Oun lo gaju nitoripe koni nkankan se pelu imoye aye yi.

Prabhupada: Beeni, toba tie jepe alaimowe leeyan na je. Tio ba tie mo ABD, o le ni imoye nipa Olorun, toba le sise fun ise ifarafun yi. eyan le je alakowe, pelu ikeeko giga, sugbon kole monipa Oluwa. Oluwa o le bosabe awon ipo aye yi. Oun l'emi to daju. Beena, ilana to wa lati ni oye nipa Olorun konse nkan lasan. Konsepe nitoripe talaka niyin eyin o le ni oye nipa Olorun. tabi nitoripe olowo niyin, beena ele ni oye nipa Olorun. Rara. Nitoripe eyin o mowe ka, nitorina eyin o le monipa Olorun, beeko. Nitoripe eyin je alakowe, nitorina ele ni oye ipa Olorun. Rara, beeko. O ju bayi lo. Apratihatā. Sa vai puṁsāṁ paro dharmaḥ. Ninu Bhagavata wan sowipe, ofin ipo kini niyen. Bhagvata o sowipe esin Hindu yi lo gaju, tabi esin Kristeni lo gaju, tabi esin Musluma lo gaju, tabi eyikeyi esin. Awa ti aimoye esin sile. Sugbon Bhagavata sowipe, awon ofin esin lo gaju. Ewo ninu re? Sa vai puṁsāṁ paro dharmo yato bhaktir adhokṣaje (SB 1.2.6). Esin tole je ke ni ilosiwaju ninu ise ifarasi ati ife fun Oluwa. Otan. Itumo esin t'ipo kini leleyi. Awa o le sowipe esin bayi bayi lo gaju, esin bayi bayi lo kere ju. Beena amuye meta lowa ninu ile aye yi. Beena gege bi awon amuye yi sewa, beena ni esin na ma ri. Sugbon lati ni oye nipa Olorun nidi lati ni oye nipa Olorun. ati basele mo lati nife fun Oluwa. Idi to wa fun niyen. Gbogbo ilana esin. toba le koyin lati nife Oluwa, lehin na t'ipo kini loje. Bibeko iranu lasan ni. Ele se gbogbo ofin esin na dada, sugbon eyin o nife kankan fun Olorun. Ife okan yin fun awon nkan aye yi lon popsi, esin gidi koniyen. gege bi Bhāgavata se so: sa vai puṁsāṁ paro dharmo yato bhaktir adhokṣaje (SB 1.2.6). Apratihatā. Ahaituky apratihatā. Ilana esin yi koni idi kankan. laiisi si idimu kankan. Teyin ba le wa sori ofin esin bayi, lehin na ema ri wipe inu yin ma dunninu gbogbo nkan. Bibeko kolese se.

Sa vai puṁsāṁ paro dharmo yato bhaktir adhokṣaje (SB 1.2.6). Adhokṣaje. Oruko imi fun Oluwa ni Adhokṣaja. Itumo Adhokṣaje niwipe o le fi ipaari si gbogbo awon eyan ton gbiyanju lati ri Oluwa soju. Adhokṣaje. Imoye isedanwo nitumo Aksaja. Eyin o le ni oye nipa Olorun pelu imoye isedanwo, rara. Eyin gbodo ko nipa re l'ona imi. Pelu igboran ati iwa to resile ati sise ise ife. Leyin na eyin le ni oye nipa Olorun. Beena Eyikeyi ninu awon esin tole ranyin lowo, lati ni ife Olorun yi laisi nkankan.. " Monife Olorun nitoripe on peese awon nkan timo fe fun igbadun iye ara mi." Ife ko niyen. Ahaituki. Laisi nkankan... Alagbara l'Oluwa. Baba mi l'Oluwa. Lati nife re nise mi. Otan. Kosejo pasipaaro. " Oh, Oluwa sin peese ounje mi, nitorina nimose nife Oluwa." Rara. Oluwa sin peese ounje lojojumo fun awon erank, ologbo ati aja. Baba gbogbo eda l'Olorun je. On peese ounje fun gbogbo awon eda. Beena ife ko niyen. Kosidi kankan fun ife gidi. T'Olorun o ba funmi ni ounje mi lojojumo, mole nife Olorun na. Ife niyen. Ife niyen.

Caitanya Mahāprabhu sowipe: āśliṣya vā pāda-ratāṁ pinaṣṭu mām (CC Antya 20.47). " Boya E fami mora tabi ke f'ese teemi mole tabi kema wa siwaju mi. Tojepe ibanuje ti mumi lokan nitoripe eyin o si pelu mi. Beena mo si feran yin." Ife mimo Oluwa niyen. Nigbata ba wa sori ipo yi fun ife Olorun, lehin na a le ri igbadun yi. Bi olorun se kun fun igbadun yi, eyin na kunfun igbadun. Ipo to gaju niyen. Tesiwaju.