YO/Prabhupada 0656 - Those Who Are Devotees, They Have No Hate for Anyone



Lecture on BG 6.6-12 -- Los Angeles, February 15, 1969

Olufokansi: " Eyan toni ilosiwaju gan ninu eto yi kolese isasoto kankan - laarin awon ton nife fun, awon ore at'ota, awon ton ni itara si at'awon ton ni iwa rere, Awon ton je elese at'awon tio ni nkankan se pelu gbogbo eto yi - pel'okan to daju (BG 6.9)."

Prabhupada: Beeni. Aami ilosiwaju leleyi. Nitoripe ninu ile aye yi, isiro nipa eni toje ore tabi ota siwa, lori ibasepo pelu ara eda lowa, tabi igbadaun iye ara. sugbon imo nipa Oluwa tabi Otitio to gaju, kosiru isiro bayi. Kokooro imi niwipe gbogbo awon eda aye yi wa labe itanraeni. kasowipe dokita, dokita loba alaisan. O ni warapa lara, iranu lon so. Iyen o wipe koni fun ni'wosan. Asi toju re bi ore. botilejepe alaisan yi ma pe l'oruko tio da, pel'eebu, beena asi fun logun. gege bi Oluwa Jesu Kristi se so, " Ema korira si awon elese sugbon fun ese na." Elese ko. Nkan to da niyen. Nitorpe elese na ko mo nkankan. Were ni. Teyin ba korira si, lehin na bawo lesele fun nigbala? Nitorina awon tonje olufokansi, awon tonje oniranse fun Olorun, awon eyan wanyi o ni ikorira s'enikankan. gege bi Oluwa Jesu Kristi, nigbaton fe kan mo'gi, O si bere lowo Olorun: "Oluwa mi, edakun e dariji won. Won o mo nkan tonse." Ipo awon olufokansi niyen. Beeni. Nitoripe wan sa tele ironu ile aye yi, beena awa o le binu siwan. Enikeni. Beena egbe impye Krsna yi si da tojepe kose ikorira fun awon eyan. Gbogbo eyan lole wa. Edakun ewa sibi. Ekorin Hare Krsna. E gba Kṛṣṇa prasāda ke gbo imoye to da nipa Bhagavad-gita, kesi gbiyanju latgi yonju ile aye yin. Ilana eto imoye Krsna yi niyen. Oluwa Caitanya loda egbe yi sile. Yāre dekha, tāre kaha 'kṛṣṇa'-upadeśa (CC Madhya 7.128). "Enikeni teyin ba pada,nibikibi teyin ba lo, e ko awon eyan yi ni imoye Krsna." Kṛṣṇa-kathā. Awon oro lati Oluwa Krsna. Eyin na ma ni idunnu lehin na eyin na ma ni ilosiwaju. tesiwaju.

Olufokansi: " Awon eyan ninu eto mimo gbodo gbiyanju lati gbokan le Eledumare. O ye ko gbe nibi ti awon eyan o si oye kosi gbiyanju lati ni idari lori okan re. Oye ki gbogbo ife okan re ati iwa lati ko nkan jo tan."

Prabhuapda: Beeni. Ibeere aye mimo niyen. Ninu apa iwe yi, Oluwa Krsna ma funwa leeko nipa awon ofin yoga. Beena o bere nibi. Awon eyan mimo gbodo gbokan le eda to gaju. Krsna tab'Olorun ni eda to gaju yi. Oun l'eda to gaju, gege bi mose salaaye teletele, nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām (Kaṭha Upaniṣad 2.2.13). Oun ni eda towa tayeraye. Oun ni edato gaju. Beena gbogbo ilan yoga yi wa lati le gokan eda to gaju yi. Awa o le di eda to gaju yi. Oye ko ye yin. Olorun l'eda to gaju. dvaita-vāda leleyi je. Apa meji. Olorun yato simi nitumo Apa meji yi Oun leda to gaju. Mo kere si. Alagbara loje, mosi kere. Alainipari loje, iwonba kekere nimi. Ibasepo wa niyen. Beena nitoripe iwonba kekere niwa, awa gbodo gbokanle eda tog aju yi. Lehin na oyeko danikan gbe. Fun ara re. Nkan tose pataki ju leleyi. Itumo danikan gbe niwipe ko gbodo gbe pelu awon eyan tio ni imoye Krsna tabi Olorun. Oye kogbe nibi ti awon eyan o si. Ninu aginju, Nibi ti awon eyan o si. Sugbon lasiko tawayi o soro gan lati losinu aginju lati wa ibi ti awon eyan o si. Ibi t'awa eyan osi nibi ton soro nipa Imoye Olorun nikan. Ibi tose paamo niyen. Ibi to se paamo niyen. lehin na? Oye ko ni idari lori okan re. Bawo losefe ni idari lori okan re? Oye ko gbokonale eda to gaju tabi Krsna. Iyen nikan.

Sa vai manaḥ kṛṣṇa-padāravindayoḥ (SB 9.4.18). Loojo to koja mo salaaye, teyin ba fi Krsna sinu okan yin.... Bi orun ni Krsna seri. Kosejo okunkun ninu okan wa. Kosejo bayi. Gege bi ina orun, kosejo okunkun. Beena, teyin ba gbokanle Krsna nigbogbo'gba, māyā yi tabi itanraeni yi kole wole sinu e. Koni le wole sinu e. Ilana towa niyen. Oye ko bo lowo awon ifeokan ati iwa lati ni awon nkan to po. Aisan ile aye yi niwipe mofe ni nkan bayi bayi - ati ife okan. Ounkoun toba sonu, ma sukun fun, ounkoun t'awa o bani, a ma bere lati ni ife okan fun. Beena, brahma-bhūtaḥ prasannātmā (SB 9.4.18) - eni toba ni imoye Oluwa, imoye Krsna, kole ni ife okan fun awon nkan aye yi mo. Ife okan soso toni ni lati sise fun Krsna. Itumo re niwipe ife okanre ti yasi mimo. Eyin o lese kema ni ife okan kankan. Kolese se. Eda leyin je, egbodo ni ife okan. sugbon ife okan wa lasiko yi, ko da. " Mofe gbadun iye ara mi pelu awon nkan aye yi." Sugbon teyin ba nife okan fun Krsna, ife fun awon nkan aye yi matan. tesiwaju.