YO/Prabhupada 1061 - Ninu Bhagavad-gita, lati ni oye nipa ooto oro marun orisirisi ni koko oro re je



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Koko ọrọ Bhagavad-gita jẹ oye ijinlẹ ti ipilẹ òtítọ marun. Be ni Oluwa Krsna, ti sọkalẹ wa, yadā yadā hi dharmasya glānir bhavati (BG 4.7), lati tun fi eredi aye gidi mulẹ nigba ti eniyan ba gbàgbé ero naa, eredi ile aye ẹya ẹda eniyan, lehin na dharmasya glanih loje, idamu fun ise eda eyan. Ti oran ba se ri bayi, ninu ọpọlọpọ, awọn eniyan ti wọn ti daji, ti o fi inu l’oye ipo rẹ, ani oun si ni ẹni na ti wọn sọ iwe mimọ Bhagavad Gita yi fun. Okunkun aye yi ti gbe wa mi bi ẹkun, ṣugbọn ãnu Oluwa pọ to bẹ lori awọn ẹda alaaye, paapa awọn eniyan, fun idi eyi ni O se sọ Bhagavad Gita, ti o ṣi fi Arjuna ọrẹ rẹ ṣe akẹkọ.

Bi Arjuna se jẹ ojisẹ Oluwa Ọlọrun, iye rẹ kọja gbogbo aimọkan, ṣugbọn Arjuna wa fi aimọkan se wahu lori papa oju ogun Kurukṣetra lati le se ibéèrè lọwọ Oluwa Ọlọrun nipa awọn isoro aye, ki Oluwa le se alaye wọn fun anfani iran awọn ọmọ eniyan lọjọ iwaju ki o se ètò ipinnu aye rẹ ki o si le huwa ni ibamu ati ki o se isẹ rẹ, isẹ aye ọmọ eniyan ni aṣepé.

Bẹẹ ninu Bhagavad-gita yi awọn oko ọrọ ibẹ jẹ oye ijinlẹ ti ipilẹ òtítọ marun. Ni akọkọ o ti salaye imọ Ọlọrun. O jẹ ti iwadi alakọkọ ti imọ ijinlẹ Ọlọrun. Imọ ijinle ti Ọlọrun ti ni alaye nibi. Lẹhinna ipo ti o jẹ ofin fun awọn ẹda alãye, jīvas. Isvara ati jiva. Olorun, Eledumare, isvara loruko re je. Oludari nitumo Isvara, ati jiva, awon eda alaaye yi.. Jīvas, awọn ẹda alãye ti wọn ndari wọn, wọn ki ise īśvara Ti mo ba sọ pé "ko si ẹniti o ndari mi, ati pe mo jẹ ominira, o jẹ alainironu. Ni gbogbo ọwọ ni ẹda alãye ti ni idari, O kere ju ninu igbesi aye hilahilo rẹ Bẹ lo jẹ ti koko-ọrọ inu Bhagavad-gita kan īśvara, oludari ti o ga julọ, ati jīvas, awọn ẹda alãye ti wọn ndari. Prakriti, awọn ohun elo ti isẹda. ati akoko, iye ọjọ aye ti gbogbo agbaye, tabi asehan ti isẹda ati iye asiko, tabi asiko taye raye. ati karma ti o tumo si aṣayan iṣẹ-ṣiṣe. Gbogbo nkan, gbogbo agbaye, ọna-isalu kun fun orisirisi akitiyan. Awon eda nipataki, gbogbo ẹda alaaye ni wọn nkopa ninu orisirisi akitiyan. Bẹẹ ninu Bhagavad Gita a gbọdọ kọ ohun tí Ọlọrun jẹ, isvara, jiva,kini awọn ẹda alaaye jẹ, kini prakriti, kini agba aye, bi akoko se nse ndari rẹ, ati kini akitiyan awọn ẹda alãye.

Lara awọn ipilẹ koko ọrọ marun wọnyi ninu Bhagavad-Gita o ti wa ni idasilẹ, wipe Ọlọrun Eledumare, tabi Krsna, tabi Brahman, tabi oludari to ga julọ, tabi Paramātmā Ẹ le lo orukọ ti ẹ ba fẹ. Sugbọn oludari to ga julọ. Oludari ti o ga julọ wa. Oun ni atobi julọ Didara awọn ẹmi alààye dabi ti oludari to ga julọ Gege bi oludari to gaju, Olorun, Oluwa ni iṣakoso lori gbogbo asayan àlámọrí ti isẹda Bi yio se wa ni alaye ninu awọn ori iwe ikẹhin Bhagavad Gita wipe isẹda aye ko ni ominira tikararẹ. Ni abẹ akoso Ọlọrun Ọba ni o ti nṣiṣẹ. Mayādhyakṣeṇa prakṛtiḥ sūyate sa-carācaram (BG 9.10). " Isẹda aye yí nṣiṣẹ labẹ itọsọna mi." "mayādhyakṣeṇa, "labe itosona ijoba mi."