YO/Prabhupada 1063 - Funwa ni irorun lati ise ati abajade ise wa



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Fun apẹẹrẹ ninu aye ti awa yi, awa n;gbadun ise wa, ijeere ise wa. ka gba pe onisowo ni mi mo si fi ọgbọn kara mọ isẹ gan ti mo si ti wa ko ọrọ nla jọ sinu ile ifowopamọ. Nigbana emi o si jẹ onigbadun. Bakanna, ka sowipe mo ti bere ise mi pelu owo to po, Sugbọn ka sọ pe mo ti padanu gbogbo owo mi sinu owo; Bákan náà, ní gbogbo iriri aye a o gbadun ere isẹ wa Eyi ni a npe ni karma, kadara.

Bẹ awọn nkan wanyi, isvara, jiva, prakrti, tabi Eledumare, tabi awon eda, ile aye yi, akoko ayeraye, ati awon aṣayan iṣẹ-ṣiṣe, gbogbo wọn ti ni alaye ninu iwe mimọ Bhagavad Gita. Ninu awọn maarun wọnyi, Oluwa, awọn ẹda alaye, ìṣẹdà aye ati akoko awon mẹrin yi ni wọn jẹ ainipẹkun. Ifarahan ti prakriti le wa fun igba diẹ, sugbọn kii se ẹtan Awọn ọjọgbọn kan sọ pe awọn ifarahan ti ìṣẹdà aye jẹ ẹtan ṣugbọn gẹgẹ bi imoye Bhagavad Gita tabi gẹgẹ bi imoye ti awọn Vaiṣṇavas, won o gba ifarahan ile aye yi bi eke. Ifarahan ti aye ki se ohun ti a gba bi ẹtan; a ti gba bi ohun gidi, sugbọn o wa fun igba diẹ. A le fiwe awọsanma ti o nkọja loju ọrun, tabi ti igba ojo ba bẹrẹ leyin igbati asiko omi ojo yi ba bere, awon ewe tuntun asi jade lori ibikibi, ale jerisi. Ni kete bi igba ojo ba ti da ati ni gbara ti awọsanma ba ti kuro,. Nigbogbogba, gbogbo awọn irugbin ti ojo mu dagba ni wọn o gbẹ. Bákan náà, ifarahan isẹda yi nsẹlẹ ni akoko si akoko, Toba ya o ma yewa, a ma mo, lati inu awon iwe Bhagavad-gita. Bhūtvā bhūtvā pralīyate (BG 8.19). Bákan náà, ifarahan isẹda yi nsẹlẹ ni akoko si akoko, duro fun igba diẹ lẹhinna a si farasin. Bayi ni ise ti prakriti. Ṣugbọn ayipo yi nsisẹ titi ayeraye. Nitorina ni prakriti se jẹ ainipẹkun. Nkan eke ko loje. Nitoripe Oluwa ti gba pe, mama prakrti, " Prakrti Mi." Apareyam itas tu viddhi me prakṛtiṁ parām (BG 7.5). Bhinnā prakṛti, bhinnā prakṛti, aparā prakṛti. Iṣẹdà aye yi jẹ agbara Ọlọrun Ọba ti o ti pinya, bakanna si ni awọn ẹda alaye se jẹ agbara ti Ọlọrun Ọba na, won o pinya Wọn tan mọra titi ayeraye. Nitorina Oluwa, ẹda alaye, ìṣẹdà aye ati akoko gbogbo wọn ni wọn ni ibatan ti wọn si wa fun ayeraye. Sibẹsibẹ, ohun kan miiran wa, karma, ti ki ise fun ayeraye. Nitõtọ ipa karma ti le wa ko lọjọ lori. A njiya tabi a ngbádùn awọn ere isẹ ọwọ wa lati igba ainipẹkun, sugbọn a le se ayipada awọn iyọrisi karma wa tabi aṣayan iṣẹ wa, ayipada na si da lori asepe ti ìmọ wa. A nkopa ninu orisirisi akitiyan isẹ. Laisi-aniani a ko mọ iru akitiyan ti a le se ti o le fun wa ni irọrun ninu awọn isẹ ati iyọrisi wọn, Eyini na tun ni alaye ninu Bhagavad Gita.

Imoye ti o gaju ni ipo ti īśvara, Ọlọrun Ọba. Ipo isvara, tabi Eledumare, imoye to gaju loje. Awọn jīvas, tabi awọn ẹda alãye, bi wọn se jẹ ẹya ara Ọlọrun Ọba, awọn na tun ni imọ sinu ara wọn awọn na tun ni imọ sinu ara wọn. Ẹda alãye ati isẹda aye awọn mejeji ni wọn ti tumọ si prakriti, ṣugbọn ọkan ninu awọn mejeji, jiva, ni o ni imọ sinu. Ikeji Prakriti ko ni imọ sinu. Eyini ni iyatọ. Nitorina ni a se npe jiva-prakriti bi eyi ti o gaju nitori awọn jiva ni imoye ti o jẹ irukanna pẹlu ti Oluwa. Ti Oluwa ni imọye ti o gaju lọ, sibẹsibẹ, ko si ẹni ti o gbọdọ ro wipe jiva, awọn ẹda alãye, na jẹ onimọ-ye to gaju lọ. Rara. Ẹda alãye ko le fi igba kan di onimọ to gaju lọ ni ipo kipo asepe rẹ, ati idamọran wipe o le jẹ bẹ jẹ ero isinilọna. Ka nimọ sinu o le jẹ bẹ, sugbọn ki ise ni pipe tabi mimọ to ga julọ.