YO/Prabhupada 1070 - Ise ifarasi Oluwa l'esin tayeraye fun awon eda aye yi



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Iṣẹ-ṣiṣe ni ẹsin ayeraye ti awọn ẹda alãye Ni tọka si erongba ti sanatana-dharma, a gbọdọ gbiyanju lati ni oye ero ẹsin lati idi itumọ ọrọ na ninu ede Sanskrit. Dharma ntọkasi si eyi ti o wa nigbagbogbo tẹlẹ pẹlu ohun kan pato. Bi a ti sọ tẹlẹ, nigba ti a ba sọrọ nipa iná o ti wa ni opin ọrọ ni akoko kanna wipe ooru ati imọlẹ ni wọn ba ina se pọ laisi ooru ati imọlẹ, ina ko ni itumọ lọrọ. Bákan náà, a gbọdọ se iwari ipa ti ko le se mani fun ẹda alãye kọọkan, apa ti o jẹ ojugba rẹ nigbagbogbo. Ibakan ojugba na ni o jẹ iwa rẹ ayérayé, bẹni iwa ayérayé yi ni ẹsin ayeraye rẹ. Nigba ti Sanatana Goswami beere lọwọ Śrī Caitanya Mahāprabhu nipa svarūpa __ ati salaaye tele nipa svarupa ti gbogbo eda -alaaye svarupa tabi ipo ti ara ẹda, Oluwa si dahun, wipe ipo ti ara ẹda, ti ẹda alãye kọọkan ni lati se iṣẹ fun Eledumare. Ti a ba se itupalẹ gbólóhùn ti Oluwa Caitanya yi, a le ri nirọrun pe gbogbo ẹda alãye kọọkan ni o nse iṣẹ nigbagbogbo lati sise fun elomi. Ẹda alãye kan nse iṣẹ fun awọn ẹda alãye miiran ni ipa orisirisi. nipa ṣise bẹ, ẹda alãye ngbadun aye. Awọn ẹranko ti wọn rẹlẹ nsin awọn eniyan bi awọn iranṣẹ se nsin oluwa wọn. A nsin oluwa B, B nsin oluwa D, ati D nsin oluwa E ati bẹ bẹ lọ Labẹ awọn ayidayida wọnyi, a le ri wipe ọrẹ kan nsin ọrẹ keji, iya nsin awọn ọmọ rẹ, aya nsin ọkọ, ọkọ nsin iyawo ati bẹ bẹ lọ. Ti a ba se iwadi ninu ẹmí yi siwaju si, a o ri pe ko si ẹniti o da silẹ ninu asayan iṣẹ-ṣiṣe ninu awujọ awọn ọmọ eniyan nibo lo wa le ti a ko ri si'se kankan. Oniselu fi eto àkọsílẹ rẹ han fun gbogbo eniyan lati fi da wọn loju agbara rẹ fun iṣẹ. Awọn oludibo na fun awọn oselu ni ibo wọn to niyelori pelu ireti, pe wọn o se iṣẹ to niyelori fun awujọ. Onisowo nsin awọn onibara, awọn onisẹ-ọwọ na nsin awọn olowo. Awọn olowo-ọlọrọ nsin ẹbi, awọn ẹbi na nsin ipinlẹ ninu awọn ofin ti agbara ayeraye ti awọn ẹda alãye ainipẹkun. Ni ọna yi a ti le ri wipe ko si ẹda alãye kan ni imukuro ni iṣẹ-ṣiṣe fun ẹda alãye miiran, nitori naa a le pinnu wipe iṣẹ ni ibakan ojugba ti awọn ẹda alãye, ati nitori naa a le pinnu laifokan pe iṣẹ-ṣiṣe ni ẹsin ayeraye ti awọn ẹda alãye. Nigbati eniyan ba jẹri iru ẹsin kan pataki ti o tọkasi akoko ati igba ti wọn bi, ki o si wa pe ara rẹ ni Hindu, Musulumi, Kiriyo, Buddhist tabi ọmọ lẹhin ẹlẹgbẹ-nsẹgbẹ miran, awon ẹsin bayi o paraapo pelu sanātana-dharma. Ẹlẹsin Hindu le yi igbagbọ rẹ pada ko di Musulumi, tabi Musulumi le yi igbagbọ rẹ pada ko di Hindu, tabi Kiriyo le yi igbagbọ rẹ ati bẹ bẹ lọ Sugbọn ni igbakugba iru iyipada igbagbọ yi ko ni ipa lori ojúṣe ayeraye rẹ ti iṣẹ-ṣiṣe fun awọn miran. Ẹlẹsin Hindu, Musulumi tabi Kristiẹni ni igbakugba jẹ iranṣẹ ti ẹnikan. Bayi, lati jẹri iru igbagbọ kan ni pato ni ki a kọ ẹhin si sanatana-dharma wa. sugbon ibakan ojugba ẹda alaaye, eyini ni iṣẹ-ṣiṣe ni sanatana-dharma. Nitootọ nipa iṣẹ ni a fi jọmọ Oluwa Atobiju. Oluwa Atobiju ni onigbadun ju lọ, awa ẹda alaaye si jẹ awọn iransẹ Rẹ ayeraye. Fun igbadun Rẹ ni a se sẹda wa ti a ba si kopa ninu igbadun ayeraye pẹlu Ẹni Isaju Eledumare, inu wa a dun. A ko le ni idunnu ni ọna miran Ko ṣee ṣe lati ni idunnu ni adani, gẹgẹ bia ti salaaye tẹlẹ pe ni adani, ko si ẹya ara kan, ọwọ, ẹsẹ, ọwọ-ika, tabi ẹya ara kan, ti o le ni idunnu lai sowọpọ pẹlu inu-ikun, bakanna, ko ṣee ṣe fun awọn ẹda alãye lati ni idunnu lai se iṣẹ imọlẹ tọkantọkan fun Oluwa Atobiju. Nisin, ẹsin awọn orisirisi orisa akunlẹbọ tabi ki a ma s’àjo iṣẹ fún wọn ko ni ifọwọsi ninu Bhagavad Gita nitoripe... O jẹ imẹnukan, ninu ori iwe Keje Bhagavad-gītā ẹsẹ ogun (Bhagavad-gītā Apa meje, ese-iwe ogun), Oluwa so wipe, kāmais tais tair hṛta-jñānāḥ prapadyante 'nya-devatāḥ. Kāmais tais tair hṛta-jñānāḥ. Awọn ti afẹ aye ti pa oye wọn rẹ, fi ara wọn fun isin awọn orisa akunlẹbọ, ati pe ki ise Oluwa Ọlọrun Atobiju ni nwọn nsin.