YO/Prabhupada 1071 - T'aba ni asepo pelu Oluwa, ta ba sise fun, lehin na inu wa ma dun



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Ti a ba ni asepo pelu Oluwa, sowọpọ pẹlu Rẹ, lẹhin na inu wa a dun A le se raniti pe nigba ti a ba darukọ Krishna, ki ise orukọ ẹsin kankan ni a ntọka si. Krishna tumọ si idunnu to ga julọ. O si ni ifọwọlelori pe Oluwa Atobiju ni orisun tabi abà ti gbogbo idunnu. Gbogbo wa ni a nlepa idunnu. Ānanda-Mayo 'bhyāsāt (Vedanta sutra 1.1.12). Awọn ẹda alààyè, bi Oluwa, ni wọn ni ẹkúnrẹrẹ imoye, beni a si nlepa idunnu. Idunnu. Idunnu Oluwa wa titi lailai ti a ba si se asepọ pẹlu Oluwa, se ifọwọsowọpọ pẹlu Rẹ ki a si kopa ninu asepọ Rẹ, nigbana awa na yoo si ni idunnu. Oluwa sọkalẹ sinu aye ikú yi lati fi idaraya rẹ, eyi ti o kún fun ayọ, ni Vrndavana han wa. Nigba ti Oluwa Śrī Kṛṣṇa wà ni Vrndavana, akitiyan rẹ pẹlu awọn ọmọkunrin olusọ-agutan ọrẹ rẹ, pẹlu awọn ọrẹ rẹ ọmọbinrin, pẹlu awọn olugbe miiran ni Vrndavana ati pẹlu awọn malu gbogbo wọn ni wọn kún fun ayọ. Gbogbo awọn araalu Vrndavana lapapọ wọn nse ilepa Re wọn o mọ nkankan ju Krishna lọ. Ṣugbọn ani Oluwa Ọlọrun mu ọkan baba rẹ Nanda Maharaja kuro ninu isìn orisa Indra, nitori o fẹ fi ni idi mulẹ daju wipe awọn eniyan o nilo lati sin eyikeyi orisa akunlẹbọ. Oluwa Atobiju nikan ni o to sin, nitori ìlépa wọn nigbẹhin ni lati pada si ibugbe Rẹ. Ibugbe Oluwa Śrī Kṛṣṇa ni sapejuwe ninu Bhagavad Gita, ori iwe Kẹdogun, ẹsẹ kẹfa:

na tad bhāsayate sūryo
na śaśāṅko na pāvakaḥ
yad gatvā na nivartante
tad dhāma paramaṁ mama
(BG 15.6)

Ẹsẹ yìí funni ni apejuwe ti ọrun alakeji... Dajudaju ero aye wa ni a fi npe ọrun, a si nro ni itanmọ pẹlu oorun, osupa, irawọ ati bẹ bẹ lọ, Sugbon Oluwa sowipe ni sanmo tayeraye yi, orun o wulo. Na tad bhāsayate sūryo na śaśāṅko na pāvakaḥ (BG 15.6). sugbọn ko si ilo nibẹ fun oṣupa. Itumo Na pāvakaḥ niwipe kosi'wulo fun ina monamkna tani ina lati tanna nitori ọrun ẹmi ti ni itana tẹlẹ nipasẹ Brahma-jyotir, Brahmajyoti, yasya prabhā (BS 5.40), imọlẹ ti o nti ọdọ Oluwa Atobiju wa. Nisinyi lasiko ti awayi, ti awon eniyan ntiraka lati de aye ọrun miiran, sugbọn ko soro lati ni oye ibugbe ti Oluwa Atobiju. Eyini ni Ibugbe ti o ni tọka si bi Goloka, ni isalu ọrun. Apejuwe rẹ ti wa ni ẹwà ninu Brahma-samhita, goloka eva nivasaty akhilātma-bhūtaḥ (BS 5.37). Bi otilẹjẹpe, Oluwa ngbe titi ayeraye ninu ibugbe Rẹ Goloka, sibẹ O jẹ akhilātma-bhūtaḥ, O ti see sumọn lati aiye yi, ati fun ipa yi Oluwa nwa lati fi ara rẹ gidi han, sac-cid-ānanda-vigraha (BS 5.1) Nigbati O ba fi ẹya yi han, ko si idi fun wa lati ma gbiro nkan ti O jọmọ.