YO/Prabhupada 1075 - Awa sin seto ile aye wa to kan ninu aye yi



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Igbesi aye yi jẹ igbaradi fun aye atunwa. Oluwa so wipe anta-kāle ca mām eva smaran muktvā kalevaram (BG 8.5). "Ẹnikẹni ti o se ìrántí Oluwa Eledumare nigbati o ba nfi ara rẹ silẹ, ni anfaani lẹsẹkanna la ti ni ara ẹmi ti sac-cid-ananda-vigraha (BS 5.1). Ilana bi a se nfi ara yi silẹ ati gbigba ara miran ninu ile aye na tun ti s’eto fun. Eniyan pade ikú lẹhin ti iru ara ti yio gbe wọ ni aye atunwa ti ni ipinnu. Sugbọn awọn alasẹ giga ni wọn ṣe ipinnu yi. gege ba sen ni ilosiwaju tabi ifaseyin ninu ise wa. Bakanna ni ibamu pẹlu awọn akitiyan wa... Igbesi aye yi jẹ igbaradi fun aye atunwa. A nse igbaradi fun aye atunwa nipa awon akitiyan ti ile aye yi. Nitorina, ti a ba le mura, ninu aye yi lati ni igbega si ijọba Ọlọrun, o ti daju nigbana, lẹhin ti a ba fi ara yi silẹ... Oluwa so wipe yaḥ prayāti, eni to ba lo, sa mad-bhāvaṁ yāti (BG 8.5), mad-bhāvam... Oluwarẹ yio ni anfaani ara ẹmí kanna bi ti Oluwa. Bi a ti salaye ṣaaju tẹlẹ, awọn orisirisi eniyan mimọ ni wọn wa Awọn brahma-vādī, paramātma-vādī ati awọn olufọkansin.. Ninu Brahma-jyotir (ọrun imọlẹ) awọn ibugbe ọrun ni wọn wa nibẹ. bi a ti wi tẹlẹ, awọn aimoye ibugbe ọrun ni wọn wa nibẹ. Iye awọn ibugbe ọrun wọnyi tobi ju gbogbo awọn aye ti wọn wa ninu agbaye yi jina, jina. ekāṁśena sthito jagat (BG 10.42) ni ile aye yi jẹ. Ikan ninu awọn afa mẹrin gbogbo agbaye yi lo jẹ. afa mẹta lori mẹrin to ku jẹ isalu ọrun ninu apa kan lorin merin yi, ninu afa ilẹ yi awọn ọkẹ ati awọn ọkẹ aimoye agbaye bi eleyi t'awa ti jeerisi nisin. ninu agbaye kan aimoye awon isogbe to wa. awọn ọkẹ aimoye agbaye ati awọn aye ọrun pẹlu awọn oorun, awọn irawọ ati awọn osupa ti wọn o lonka ni wọn wa nibẹ. sugbon ikan ninu merin ni gbogbo agbayi yi ninu iseda aye. afa mẹta lori mẹrin to ku jẹ isalu ọrun. Nisin, mad-bavam yi, Ẹni ti o ba fẹ darapọ mọ aye ti Brahman to ga julọ, wọn a si darapọ mọ Brahma-jyotir ti Oluwa Atobiju. brahma-jyotir ati awon isogbe mimo iyoku ninu brahma-jyotir nitumo Mad-bhāvam awon ẹlẹsin, ti o fẹ ni irẹpọdun pẹlu Oluwa, wọn ma wọ inu aye ọrun Vaikuṇṭha. Awọn aye ọrun Vaikuṇṭha wa ni aimoye, ati Oluwa, Ọlọrun Eledumare nipa apero awọn ilọpo Rẹ bi Narayana ọlọwọ mẹrin pẹlu orisirisi orukọ, bi Pradyumna, Aniruddha ati Govinda... ọpọlọpọ awọn ainiye awọn orukọ ni o wa fun Narayana ọlọwọ merin yi. Beena ikan ninu awon isogbe wanyi, mad-bhavam na niyen, iyen na wa ninu iseda mimo. Nitorina ti aye ba de opin eyikeyi ninu awọn eniyan mimọ le fi boya Brahma-jyotir, Paramātmā tabi Śrī Krishna Eledumare gbiro, ni ọnakọna, gbogbo wọn ni wọn o wọ inu isalu ọrun. sugbọn olufọkansin nikan, tabi ẹniti o ni asepọ timọtimọ pẹlu Oluwa Ọba, ni o ma wọ inu ajule ọrun Vaikuṇṭha tabi ajule ọrun Goloka Vrndavana. Oluwa so wipe, yaḥ prayāti sa mad-bhāvaṁ yāti nāsty atra saṁśayaḥ (BG 8.5). "ko si iyemeji nibẹ." Igbagbọ wa gbọdọ duro sinsin lori eyi. Ẹ ti nfi gbogbo aye yin nka Bhagavad-gita, sugbọn ti Oluwa ba sọ nkan ti ko ni ibamu pẹlu ero wa, a kọ ọ Ki ise ọna kika iwe mimọ Bhagavad-gita niyi. o yẹ ki iwa wa jẹ bi ti Arjuna: sarvam etaṁ ṛtam manye, "Mo gba gbogbo ohun ti iwọ ti sọ gbọ." Bakanna, igboran. Nitorina nigbati Oluwa wi pe ni akoko iku ẹnikẹni ti o ba ronu Rẹ bi, Brahman tabi Paramātmā tabi bi Ọlọrun Eledumare, dajudaju yio lọ sinu sàkaani ọrun, ko si iyemeji nipa eyi. Ko si ọrọ pe a ko le gbà gbọ. ipilẹsẹ ti gbogboogbo na tun ti ni alaye ninu Bhagavad-gītā bi o se le ṣee ṣe lati wọ ijọba ọrun nipa fifi Ọlọrun nìkan gbiro ni akoko iku. Nitoripe ipilẹsẹ ti gbogboogbo na ti ni imẹnuba:

yaṁ yaṁ vāpi smaran bhāvaṁ
tyajaty ante kalevaram
taṁ tam evaiti kaunteya
sadā tad-bhāva-bhāvitaḥ
(BG 8.6)