YO/Prabhupada 1077 - Oluwa tosi wa ni pipe, kosi iyato kankan laarin Oruko re at'Oun fun ara re



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Nítorí ti Oluwa jẹ Idi ohun gbogbo, ko si iyatọ nibẹ laarin Oluwa ati awọn orukọ Rẹ Oruko imi fun Śrīmad-Bhāgavatam ni bhāṣyo 'yaṁ brahma-sūtrāṇām. asọye lori Vedanta-sutra lo je. Bee na gbogbo awọn iwe mimọ wọnyi, taba yi ironu ọkan wa, tad-bhāva-bhāvitaḥ, sadā. Sadā tad-bhāva-bhāvitaḥ (BG 8.6). Eni ti o nfi gbogbo'gba kopa ni... Gẹgẹ bi awọn ti ifẹ aye jọba l’ọkan wọn se nkà awọn iwe afẹ aye, iwe iroyin, akọọlẹ, iwe, bẹ bẹ lọ, awon imoye ati sayensi to pọ, awon nkan wanyio lati awon ironu orisiri. Bakanna, ti a ba rọpo kika iwe wa, pẹlu awọn iwe Vediki, gẹgẹ bi Vyasadeva se salaaye, ni ọna yi o ṣee ṣe fun wa lati ranti Ọlọrun Ọba ni akoko ikú. Ọna kan soso ti Oluwa funraRẹ daba ni yi. Ki tilẹ se nidaba, o jẹ otitọ. Nāsty atra saṁśayaḥ (BG 8.5). "Ko si iyemeji." Tasmat, Oluwa si salaaye wipe, tasmāt sarveṣu kāleṣu mām anusmara yudhya ca (BG 8.7). O fun Arjuna ni imọran pe mām anusmara yudhya ca. Ko si da ni imọran fun Arjuna ki o kan ma se ranti Rẹ nikan ki o si fi ojúṣe rẹ silẹ Rara, Oluwa ki da imọran ti ko wulo. Ni ile aye yi, lati le bojuto ara ẹni a ni lati ṣiṣẹ. Iṣẹ na si ni ìpín si mẹrin lawujọ: brāhmaṇa, kṣatriya, vaiśya, śūdra. Awọn kilasi ọmọwe wọn nsiṣẹ ni ọna kan, awọn kilasi isakoso wọn nsiṣẹ ni ọna miiran, Awọn kilasi onisowo awọn na nsiṣẹ ni ọna miiran, ati awọn alagbaṣe, ti gbogbo wọn ni wọn tọjú ojúṣe kan pato. Ninu awọn awujọ eniyan, boya o jẹ alagbaṣe, onisowo, alakoso tabi agbẹ, tabi paapa ti o ba tilẹ jẹ ọkan ninu awọn kilasi to ga julọ ati ki o jẹ alakọwe eniyan, ọmọwé tabi akẹkọ imọ-ijinlẹ, o ni lati siṣẹ lati ṣetọju aye rẹ, ninu ìjàkadì aye.

Nitorina Oluwa sọ fún Arjuna pe "ko wulo ko fi ojúṣe rẹ silẹ, sugbọn nigba ti o ba nkopa ojúṣe rẹ ki o ma ranti Ọlọrun (mām anusmara) (BG 8.7). eyiini yio jẹ ki o ṣee ṣe fun ọ lati ranti Ọlọrun ni akoko ikú. Ti o ko ba fi iranti Ọlọrun se iwahu nigbogbo igba, ninu ìjàkadì aye re, nigbana ko ni le ṣee ṣe. "Ko le ṣee ṣe. Oluwa Caitanya na ti salaaye nkan na, kīrtanīyaḥ sadā hariḥ (CC Adi 17.31). Kīrtanīyaḥ sadā. Ma fi orukọ Oluwa Ọlọrun kọrin nigbagbogbo". Ọlọrun ati orukọ Ọlọrun wọn ko yatọ sira. Nítorí náà, ilana Oluwa Ọlọrun fun Arjuna pe mām anusmara (BG 8.7), "Ranti Mi," ati asẹ ti Oluwa Caitanya ki a ma "fi orukọ Oluwa Ọlọrun kọrin nigbagbogbo" jẹ ẹkọ kanna. Nibi Krsna so wipe " Ranti Mi nigbogbogba, tabi ranti Krsna, Oluwa Caitanya ki a ma "fi orukọ Oluwa Ọlọrun kọrin nigbagbogbo" Beena kosi iyato kankan nitoripe Krsna ati oruko Krsna nkankan lon je Ni ipo ifise ko si iyatọ nibẹ laarin ijuwe ati ohun ti a njuwe. Bẹ bi Oluwa ti jẹ idi gbogbo nkan, ko si iyatọ laarin Oluwa ati awọn orukọ Rẹ. o yẹ ki a se niwa lati ma kepe orukọ Oluwa nigbagbogbo. tasmāt sarveṣu kāleṣu (BG 8.7). Nigbagbogbo, wakati mẹrin-le l’ogun lojumọ, ati se eto awọn akitiyan aye ni iru ọna ti a le se E ni ranti wakati mẹrin-le l’ogun. Bawo ni eyi ṣee ṣe? Bẹẹni, o ṣee ṣe. O ṣee ṣe. Awọn ācāryas se apẹẹrẹ yi funni. Kini apẹẹrẹ na? Ti obirin adelebọ ba nifẹ si ọkunrin miran, botilẹjẹpe o l'ọkọ, sugbọn o si nifẹ ọkurin miran. Ki a si mọ pe iru ifẹ nà lagbara gan. Eyi ni a npe ni parakiya-rasa. Boya ọkunrin tabi obinrin. Ti ọkunrin ba nifẹ fun obinrin kan miiran ju aya rẹ, tabi ti obinrin ba nsomọ ọkunrin miran ju ọkọ re lọ, sisomọ yi lagbara gan. Eyini lagbara gan. Bẹ ni awọn acarya funwa ni apẹẹrẹ yi nipa alagabagebe obinrin ti o nifẹ fun ọkọ ẹlomiran, o nfi gbogboigba lero ololufẹ na, ati ni igba kanna, fihan ọkọ rẹ pe on sisẹ gan nigba ti o ba nse isẹ ojumọ rẹ ki ọkọ rẹ ma le ni fura si asomọ rẹ. Bẹ ni o se nranti nigbagbogbo bi o se npade ololufẹ rẹ l'alẹ, ani o ma fi sọra se iṣẹ ile rẹ pupọ, Bakanna ni, o yẹ ki a ma ranti Ololufẹ to ga julọ, Śrī Kṛṣṇa, ati ni igba kanna ṣe awọn ojuse aye wa gan dara julọ Eyini see se. A nilo ori ifẹ to lagbara fun eleyi.