YO/Prabhupada 0418 - Initiation Means Beginning of the Activities



Lecture & Initiation -- Seattle, October 20, 1968

Beena itebomi mimo yi... Opolopo ninu awon akeko wa, awon imi ninu awon akeko wa ma ni itebomi ni irole yi. Ese keta ninu iparapo pelu egbe wa yi nitumo itebomi mimo yi. Ipo kini ni śraddhā, igbagbo die. Gege bi awon akeko wa ton los'oja , lati korin, opolopo awon eyan ton funwa lowo, elomi ton ra iwe wa " Eyi pada si odo metalokan". ibere igbagbo niyen: "Oh egbe to dara gan leleyi. Eje kin ni asepo pelu wan." Ādau śraddhā. Lehin na, toba si ni anfaani die si, o le wa si awon ikeko wa. " O daa, e jeki wo nkan ti awon eyan egbe imoye Krsna yi n'se." Beena won ma wa. Ipo keji niyen. Aanu fun egbe wa ni ipo kini. Iparapo pelu wa ni ipo keji gege bi eyin na ti wa lati gbo nkan ti mon so. Beena, teyan ba ni igbagbo tabi igbagbo re ti ni ilosiwaju si, o ma wa sori ipo keji. ipo keta ni .... Ādau śraddhā tataḥ sādhu-saṅga atha bhajana-kriyā (CC Madhya 23.14-15). Nisin, ibere aye tuntun nitumo itebomi mimo yi. Ibere ise. Basele ni imoye Krsna ni pipe nitumo itebomi yi. Konsepe itebomi ni opin gbogbo nkan. Ipo keta loje. Eni toti se itebomi yi gbodo tele awon ofin na, ipo kerin niyen, ogbodo korin Hare Krsna ni iwonba kanna lojojumo, diedie gbogbo awon asise toni ba tan. kini awon asise wanyi? Ati sofun awon akeko wa kon ma ni asepo pelu okurin tabi obirin tio kin se iyawo tabi oko won, kon ma jeran mo, kon ma moti mo, kon ma ta tete mo. Awon nkan merin wanyi. Beena awon nkan merin wanyi si po gan ninu awujo wa, nipataki awon ilu geesi. sugbon awon akeko wanyi ton gba itebomi mimo yi ton si korin, wansi fi awon nkan merin wanyi sile laisi isoro kankan. Nkan ton pe ni anartha nivrtti, Ipo kerin leleyi. Ipo karun to wa niwipe okan re daju si nkan ton se: " Beeni." Gege bi ikan ninu awon akeko wa, Mr. Anderson, mio ti ri, sugbon nitoripe oti ni asepo pelu awon olufokansi, oti ko leta wipe "Mofe fun gbogbo aye mi si ise imoye Krsna yi." Nkan ton pe ni nistha niyen. Tato niṣṭhā tato ruci. Wan ma ni itowo fun ise yi itumo Ruci niyen. kilode tu awon omo-okurin wanyi sen jade? Wanti ni ifarasi fun orin kiko yi. Itowo wa ninu re fun won. Bibeko ilokulo asiko loje fun won. Wan keeko, wan ti dagba. Nitorina won ni ifarasi. Ton ba fokan si, ton ni ifarasi, tathāsaktis. Ti ifarasi yi ba wa, lehin na won mani asomo si eto na. kole fi sile. Moti gba awon leta to po gan. Awon akeko tio le sise pelu awon olujosin, won ma lo, sugobn won ko leta pe " Mio le lo. Mio le lo." Oti ni ifarasi. Se ti ri? Umāpati lo ko leta yi simi, pe oni isoro kole gbe mo, kole gbe mo tabi kole kuro. O wa ni Dallas. Se ti ri bayi? Kole kuro ninu egbe yi, kole gbe pelu awon olufokansi to ku. Sugbon fun igba die lowa. Beena nkan ton pe ni asaktih niyen. Tathāsaktis tato bhāva. Die die lon po si, idunnu tayeraye, nitoripe on ronu nipa Krsna nigbogo'gba. Ipo to gaju yi, pe o nife Krsna ni pipe. Ilana to wa niyen.