YO/Prabhupada 0036 - Ipinu ile-aye wa

Revision as of 18:45, 14 October 2018 by Vanibot (talk | contribs) (Vanibot #0023: VideoLocalizer - changed YouTube player to show hard-coded subtitles version)
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Lecture on BG 2.1-11 -- Johannesburg, October 17, 1975

Nitorina ni igba ti nkan aye yi ba di wuruwuru fun wa, Kini a ma se - ka se abi ka ma se, eyi ni apeere - asiko ati sunmo olukoni, guru ni yi. Eyi ni imoran ti o wa nibi, a le ri. Pṛcchāmi tvāṁ dharma-sammūḍha-cetāḥ. Ni igbati a ko ba mo bi a se ma gbe gba, a ko nse iyato larin nkan ti o je ipa esin tabi ko beko, ti a ko lo ipo wa bi o se ye. Iyen ni kārpaṇya-doṣopahata-svabhāvaḥ (BG 2.7). Igba yen ni a ni lo fun olukoni, guru. Eyi ni imoran Vediki. Tad-vijñānārthaṁ sa gurum evābhigacchet śrotriyaṁ brahma-niṣṭham (MU 1.2.12). Iyen ni sise. Eyi ni ilaju, wipe a ndo ju ko orisirisi isoro aye. Eyi je iwa idanida. Ninu aye asan yi, ile aye asan ni isoro aye. Padaṁ padaṁ yad vipadām (SB 10.14.58). Itumo ile aye assan ni wipe, ni gbogbo ese ni ewu wa. Ile aye ni yen. Nitorina a gbodo gba ito sona lati odo guru, lati odo oluko, lati odo oluko igbala bi a o se te siwaju, nitori eyi... A o ma se alaaye niwaju, wipe ipinu aye wa, bi o ti le kere ju, ninu ara omo eniyan, ni igba ilaju awon Aryaa ipinu omo eda ni lati mo ipo idabi re, "Tani emi. Tani mo je" Ti a ko ba mo nkan ti a je, " Tani mo je," o je wipe a ko ju awon aja ati ologbo lo. Awon aja, ologbo, won o mo nkan. Won ro wipe awon ni ara won. A o se alaaye ni iwaju. Nitorina ni nu iru ipo aye bayi, ni igbati nkan ba yi wa loju... Ka ti le wi ni ododo, gbogbo igba ni nkan yi wa loju. Nitori idi eyi o wa ni pataki lati sunmo oluko ododo. Nisinyi, Arjuna nsunmo Krishna, olukoni ti ko ni ifarawe. Ko ni ifarawe. Guru, tabi Oluko tumo si Oluwa olorun. Oun ni oluko gbogbo wa, parama-guru, oloko akoko. Nitorina enikeni ti o ba je ojise Olorun, guru ni oun na. A o se alaaye eyi ni nu iwe ori Kerin. Evaṁ paramparā-prāptam imaṁ rājarṣayo viduḥ (BG 4.2). Nitorina Krishna nse apeere ibi ti a gbodo jowo ara wa ati lati gba oluko. Olorun ni yi. Nitorina a gbodo gba Olorun tabi ojise re gege bi guru. Ni igba na ni gbogbo isoro yin yi o si wa si opin. Bi beko ko le se se, nitori oun le so nkan ti o dara fun yin, ati nkan ti ko dara fun yin. O nbere, yac chreyaḥ syān niścitaṁ brūhi tat (BG 2.7). Niścitam Ti e ba fe imoran, tabi akiyesi, niscitam, ti ko ni tabi tabi, ti ko ni idani lenu, ti ko ni asise, ti ko ni itanije, iyen ni a npe ni niscitam. E le ri eyi gba l'owo Olorun tabi ojise Re Eyin ko le ni imoran to daju lati owo eni ti ko wa pipe fun ra re, tabi atanni je. Iyen ki ise imoran to daju. Ni ode oni o ti di araa; eni keni ndi guru won a si maa so nkan ti o wu won, "Mo ro wipe," "Ni ipa iro mi." Eyi ki ise Oluko, guru. Itumo Guru tumosi wipe o nfi iwe mimo se eri. Yaḥ śāstra-vidhim utsṛjya vartate kāma-kārataḥ: (BG 16.23) "Eni keni ti ko ba fi eri re ka le, lati inu iwe mimo, nigba naa, na siddhiṁ sa avāpnoti, "Ko le ni aseyo ju ni igba ki igba," na sukham, "Ko si boya idunnu ninu aye," na parāṁ gatim, "ka ma wa so ti igbega ni aye miran." Awon imoran naa ni yi.