YO/Prabhupada 0048 - Ilaju Aaryan
Lecture on BG 2.2-6 -- Ahmedabad, December 11, 1972
Anārya-juṣṭam, "ki ise nkan ti o pon nile fu eni ti o mo awon iwa igbenisoke laye" Aaryan. Aaryan tumo si awon onilosiwaju. Nitorina irewesi Arjuna ni oju ogun o je apeere nkan ti o ye alaise-Aaryan. Aaryan, gege bi won se sapejuwe ilaju Aaryan ninu Bhagavad Gita, ipin merin ni Olorun Atobiju Oloriaye dasile. Bi a ti so siwaju, dharmaṁ tu sākṣād bhagavat-praṇītam (SB 6.3.19). Eto esin eyikeyi gbodo ye wa wipe : " Olorun ni o da sile" Omo eniyan ko le da eto esin sile. Nitorina eto Aaryan yi, eto ilosiwaju, ohun ni: cātur-varṇyaṁ mayā sṛṣṭaṁ guṇa-karma-vibhāgaśaḥ (BG 4.13). Olorun so wipe, "Emi ni Mo fi han fun ibojuto eto iselu ti o dara" Brāhmaṇa, kṣatriya, vaiśya, śūdra. Arjuna je omo idile ajagun, Kshatriya. Nitorina isiyemeji re lati ja loju ogun ko nse nkan ti o ye awon Aaryan. Ki idile oba wa di alaifi t'ipa se, eleyi o bo si. Awon ajagun, ti won ba nja loju ogun, pipa eniyan ki ise ese fun won. Bakanna, alalufa, nigba ti won ba nse irubo, nigba miran won a fi eranko rubo; sugbon eyi ki ise iru fin tabi won da ese. Fifi eran rubo yi ki ise fun eran jije. Se lati fi se itewo ohun awijo [mantra] Vediki. Boya awon alalufa ti won se irubo boya won npe awon awijo Vediki na ni bo se ye, won a se idanwo nipa fifi eran kan se irubo leyin na won a tun yi pada si ayee. Iyen ni irubo eranko. Nigba miran o le je awon esin, tabi awon malu ni won fi nrubo. Sugbon igba ti a wa yi, akoko ti Kali, o je nkan ti a ka leewo nitoripe ko si iru aafa-irubo be mo. Gbogbo awon irubo ni won ti f'odi si ninu akoko yi.
- aśvamedhaṁ gavālambhaṁ
- sannyāsaṁ pala-paitṛkam
- devareṇa sutotpattiṁ
- kalau pañca vivarjayet
- (CC Adi 17.164)
Irubo awon esin, irubo awon malu, ise ra ni agan, ati bibi omo lowo, aburo oko okunrin, awon nkan yi se nkan ewo ni akoko yi.