YO/Prabhupada 0052 - Iyato laarin Bhakta ati Karmi

Revision as of 18:48, 14 October 2018 by Vanibot (talk | contribs) (Vanibot #0023: VideoLocalizer - changed YouTube player to show hard-coded subtitles version)
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Lecture on SB 1.2.9-10 -- Delhi, November 14, 1973

Eyi ni iyato laarin bhakti ati karma. Karma je igbadun ara, bhakti si je sise ti ife Olorun. Nkan kan na. Nitorina ko ye opolopo nkan ti o se iyato laarin bhakta ati karmi Eniti o je karmi nse ife ti ara re, eniti o si je bhakta nse ife ti Olorun. Igbadun kan gbodo wa nbe. Sugbon nigba ti a ba se ife ti Olorun, iyen ni a npe ni bhakti. Hṛṣīkeṇa hṛṣīkeśa-sevanaṁ bhaktir ucyate (CC Madhya 19.170). Itumo Hrsika ni awon ipa ara, awon ipa ara ti won ti ya si mimo. Mo ti se alaaye eleyi tele, wipe

sarvopādhi-vinirmuktaṁ
tat-paratvena nirmalam
hṛṣīkeṇa hṛṣīkeśa-
sevanaṁ bhaktir ucyate
(CC Madhya 19.170)

Bhakti ko ni wipe ka fi ise sile. Bhakti ki nse ero kero ti awon alaragbigbona nipa esin. Iyen kii se bhakti. Bhakti tumo si wipe ka fi gbogbo ipa ara se ise fun itelorun Olori aye. Iyen ni a npe ni bhakti.

Nitori idi eyi oruko Olorun miran ni Hrisikesha. Hrisika tumo si awon ipa ara. ati pe hrisika Isa, Olusakoso ipa ara. Nitoto, awon ipa ara wa won o le sise nipa ti ominira won. Eleyi le ye wa. Oluwa ndari sona. Sarvasya cāhaṁ hṛdi sanniviṣṭo mattaḥ smṛtir jñānam apohanaṁ ca (BG 15.15). Mattaḥ smṛtir jñānam apohanaṁ ca. Ologbon sayensi nsise nitoripe Olorun ndari re, kii se wipe o nsise ni ominira re. Iyen ko le se se. Sugbon oun fe ko ri be. Nitorina Olorun nfun ni awon iranwo. Sugbon ni ododo, Olorun ni nse. Won se ni alaaye ninu awon iwe Upanishads. Laisi pe Olorun nsise, laisi pe O nriran, laisi pe Olorun nriran, iwo ko le riran. Gege bi won se s'alaaye imole oorun ninu iwe Brahma-samhita. yac-cakṣur eṣa savitā sakala-grahāṇāṁ Oorun je ikan ninu awon oju Olorun.

yac-cakṣur eṣa savitā sakala-grahāṇāṁ
rājā samasta-sura-mūrtir aśeṣa-tejāḥ
yasyājñayā bhramati sambhṛta-kāla-cakro
govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi

Nitorina, bi oorun ti nse ikan ninu awon oju Olorun, nitoripe oorun nyo nibe, nitoripe oorun nriran, nitorina eyin nriran. E ko le riran pelu ominira yin. E pon oju yin le pupo. Kini iwulo oju yin ti ko ba si imole oorun? E ko le riran. Ina ijoba yi paapaa, iyen na wa lati inu oorun. Bee na daju daju nigba ti Olorun ba riran, eyin na le riran. Bo se ri ni yen.

Bee ni ipa ara wa... Won so ninu Bhagavad Gita wipe, sarvataḥ pāṇi-pādaṁ tat. Sarvataḥ pāṇi-pāda...Owo ati ese Olorun tan ka kiri, olowo gbogboro. Kini iyen tumo si? Owo mi, owo yin, ese yin - iyen nse ti Olorun. Gege bi enikan le so wipe mo ni eka ile ise kari aye. Bee ni awon eka ile-ise na nsise lowo abojuto eni ti o ga julo. Bakanna, ni Olorun. Nitori idi eyi a npe Olorun ni Hrshikesha, Hrishikesha Bee na iponju ni... Itumo Bhakti ni pe ki a fi awon hrshika wa, awon indriyas wa, awon ipa ara wa, fi sise lodo olori aye ti o nse akoso awon ipa ara. Iyen ni asepe ile aye wa. Iyen ni asepe wa... Sugbon dede ti a ba ti le ni ero lati lo awon ipa ara wa fun igbadun ti ara, Iyen ni anpe ni karma. Iyen ni a npe ni aye asan. Nitorina, fun bhakta ko si nkankan to nse ti aye yi. Iyen ni īśāvāsyam idaṁ sarvam (ISO 1). Bhakta ri wipe gbogbo nkan ni o je ti Olorun. Īśāvāsyam idaṁ sarvaṁ yat kiñca jagatyāṁ jagat, tena tyaktena bhuñjīthā. Gbogbo nkan ni o je ti Olorun. Nitorina nkan ki nkan ti Olorun ba fi fun wa... Gege bi oga kan.. Oga na fi nkan fun iranse re, "O le fi eyi se igbadun." Iyen ni, prasadam, anu Oluwa. Prasāde sarva-duḥkhānāṁ hānir asyopajā... Aye ni yen. Ti e ba di eni ifokansin Olorun, ti e ba ni oye wipe gbogbo nkan ni ti Olorun, awon owo ati ese mi paapaa, awon na je ti Olorun, gbogbo ipa ara mi, won je ti Olorun, nitorina won gbodo se lilo fun Olorun, "iyen ni anpe ni bhakti.

anyābhilāṣitā-śūnyaṁ
jñāna-karmādy-anāvṛtam
ānukūlyena kṛṣṇānu-
śīlanaṁ bhaktir uttamā
(Brs. 1.1.11)

Iyen ni Olorun se, hun hun, Iyen ni Arjuna se. O fe se ife ti ara re ni pa kiko ogun jija, sugbon leyin ti o gbo imoran ti Bhagavad Gita o gba wipe "Bee ni Olorun ni Atobiju".

ahaṁ sarvasya prabhavo
mattaḥ sarvaṁ pravartate
iti matvā bhajante māṁ
budhā bhāva-samanvitāḥ
(BG 10.8)

Won se alaaye awon nkan won yi ni toto ninu Bhagavad Gita. Eyi ni eko ibere eko ni pa ile aye ti emi. Ati ti imoran Bhagavad Gita ba si da wa loju nitoto, a si jowo emi wa fun Olorun. Eyi ni ife Olorun. Sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja (BG 18.66). Ife Re ni yi. Ti a ba gba eto yi ni ododo, iyen ni a npe ni shraddha. Shraddha. Kaviraja Goswami ti se alaaye re siwaju, nkan ti shraddha tumo si.