YO/Prabhupada 0117 - Hotẹẹli ofe ati ibugbe ofe
Lecture on SB 7.9.24 -- Mayapur, March 2, 1976
Eyi ni ero na, lati di iranṣẹ ati lati di iranṣẹ-binrin. Eleyi jẹ apẹrẹ ti ọlaju eniyan. Olukaluku awọn obirin yẹ ki o gbiyanju lati di iranṣẹbinrin ti ọkọ rẹ, o si yẹ ki gbogbo ọkunrin gbiyanju lati di iranṣẹ ti Olorun ni igba ọgọrun. Eleyi jẹ ọlaju India , ki se wi pe "Ọkọ ati iyawo, a wa dogba ninu awọn ẹtọ." Wipe, ni Yúróòpù, Amẹríkà, irunkan bayi sele. "idogba awọn ẹtọ." Iyen ki se ilana Vediki. Ilana aiye ọlaju Vediki ni pe ọkọ yẹ ki o je iranṣẹ olododo ti Olorun, ati ki awọn aya jẹ iranṣẹbinrin olododo ti awọn ọkọ.
Nitorina nihinyi o ti wa wipe,, upanaya māṁ nija-bhṛtya-pārśvam (SB 7.9.24). Eyi ni ibasepo ti o dara ju.. Nigba ti Nārada Muni ti nse apejuwe bi ọkunrin se yẹ ki o huwa, bi obinrin se yẹ ki o huwa ... A ti wa ni jíròrò bayi ninu ero agbohunsilẹ wa, e ma gbo nipa re. Wipe ko si iru ohun na bi lati di ọgá. Asan ni. Iwo ko le di ọgá. Ahaṅkāra-vimūḍhātmā kartāham iti manyate (BG 3.27). Iwo ko le di ọgá. Jīvera svarūpa haya nitya kṛṣṇa dāsa (CC Madhya 20.108-109). Boya ọkunrin tabi obinrin, gbogbo eniyan ni iranṣẹ ti Olorun. A ni lati se oṣiṣẹ de bi wipe, bawo ni a se le di iranṣẹ ti o dara ju, iranse nikan ko, sugbon iranse ti awon iranse toku. Eyi ni a npe ni iranṣẹ paramparā. Iranse ni oluko igbala mi je fun oluko igbala re, iranse ni emi na si je fun oluko igbala mi. Bákan náà, a rò pé "iranṣẹ ti awọn iranṣẹ." Ko si ni ibeere ti di... Eyi ni aisan aye (CC Madhya 13.80).
- kṛṣṇa bhuliya jīva bhoga vāñchā kāre
- pāsate māyā tāre jāpatīyā dhāre.
Lesekese ti aba ti ni igberaga - "Bayi emi yio di ọgá. Emi o kan ma pase. Emi o ni tele enikankan" - ise māyā niyen.
Beni aarun na se nlọ bẹrẹ lati ori Brahma s'isalẹ kan awọn eèrà. Prahlāda Mahārāja ti ni oye nkan ti a npe ni ipo igberaga asan a ti d'oga. O si wipe "Mo ni oye nipa igberaga eke yi" Edakun e funmi ni ise... Nija-bhṛtya-pārśvam. Itumo Nija-bhṛtya-pārśvam niwipe gege bi olukọṣẹ ọkunrin Olukọṣẹ, olukọṣẹ kan ma kose l'odo akọsẹmọsẹ ọkunrin. Bi ere bi ere, olukọṣẹ na kẹkọọnípa bawo ni lati ṣe awọn nkan. Nitorina o si wipe, nija-bhṛtya-pārśvam. Ki se wipe lẹsẹkẹsẹ emi o sì di iranṣẹ akọsẹmọsẹ gidigidi, ṣugbọn jẹ kí n ... Idi fun egbe wa niyen. teyan ba wasibi fun ounje ofe, ati yara ofe, wiwa re si ibasepo wa je asan. O si gbodo ko bi lati maa sise. Nija-bhṛtya-pārśvam. Awon ti won nsise, won... O yẹ ki o kọ ẹkọ lọdọ rẹ bi o ti n see se fun wakati merinlelogun; lẹhinna didarapo wa mo egbe yi yio jẹ aseyori. Ati ti a ba gbà a wipe "Eyi jẹ ẹya egbe ibi ti a ti le ni hotẹẹli ofe, ibugbe ofe, ati igbadun lofe", lẹhinna gbogbo egbe yoo wa ni ibaje. E ṣọra gan. Gbogbo awon GBC, won gbodo ṣọra gan ki iru iwa bayi ma se alekun. Eni kòòkan yẹ ki o ni itara gidigidi lati see se, lati ko bi won se nsee se. Nija-bhṛtya-pārśvam, Nigbana ni aye yio jẹ aseyori.
E ṣeun pupọ.