YO/Prabhupada 0023 - E gba imoye Krishna ki iku tode



Sri Isopanisad Invocation Lecture -- Los Angeles, April 28, 1970

Nisinyi, won so fun wa nibi pe, gbogbo aye na ni akoko ti re, ti a ti gbe si le ni pa agbara Nkan to pe ju lo. Gbogbo ida-nbaye tun tobi gidi gan, ara ti aye yi. Ko ju ba yi lo. Gege bi ara yin; gbogbo nkan ni o wa ni ifarawe. Sayensi ode oni, ofin ifarawe. Oun ti o kere ju lo, nkan kinkini, bi era, o ni aye afarawe re, eyin na e si ni aye afarawe yin. Bakanna ara nla-nla yi, o le se to egberun lona egbe-gberun aye la ye, Sugbon ko ni wa nbe ti ti lai lai. Iyen lo daju. Nitoripe o tobi gidi gidi gan, nitori eyi o le wa nbe fun egbe-egberun aye, sugbon yi o ni opin. Eyi ni ofin iseda. Ti akoko na ba si wa si opin, ifarahan fun igba die yi, yi o si di ipare. nipa ero pipe ti eyi ti o pe, Eyi ti o pe julo. Ni igba ti akoko yin ba pe, o pari, oga, ninu ara yi. Ko si eni ti o le da duro. Ero yi ni agbara pupo. Eyin ko le wipe, "Je ki nduro" Otile ti sele ri. Ni igba ti mo wa ni India, ni Allahabad, ikan ninu wa, ore ojumo kan, o je eniti o lowo pupo. O wa nku lo. Ni o ba bere si se ekun ti dokita oniwosan re, "Se e ko le fun mi ni odun merin pere kun ojo aye mi? Mo ni ero kan, se e ri. Ti mi o ti pari." Se eri. Āśā-pāśa-śatair baddhāḥ. Elesu ni yi. Ero okan oni kalu ku ni pe " Ah, Mo si fe se nkan yi. Mo ni lati seyi." Rara. Awon oniwosan, tabi awon Baba oniwosan, tabi Baba re, ko si oni sayensi ti o le da duro. "Ah, rara, oga. Ko si odun merin. Ko tile si iseju merin. E gbodo lo ni kia kia." Ofin na ni yi. Nitorina ki akoko na to de, a gbodo se ni pataki lati se aseyanju isokan Olorun. Tūrṇam yateta. Tūrṇam tumo si a yara bi asa, kia kia e gbodo se aseyanju lati se isokan Olorun. Anu... To tele, ki iku to de, ki iku to nbo to de, e gbodo pari ise ti eni se. Iyen ni ologbon. Bibeko iku a bori re. E seun.