YO/Prabhupada 0054 - Olukaluku nkan fun Olorun ni wahala



His Divine Grace Srila Bhaktisiddhanta Sarasvati Gosvami Prabhupada's Appearance Day, SB 6.3.24 -- Gorakhpur, February 15, 1971

Bee na ni awon Maayaavaadi fe fihan wipe otito to ga ju lo je niraakaara, tabi ohun ti ko ni ara. Olorun si fun yin ni ogbon : "Bee ni, o le se ikede eyi. E fihan ogbon ero ori yi, ni idi eyi, ni idi ohun." Bakanna, Olorun fun... Owe Bengali kan wa bi Olorun se nse ise, wipe okunrin kan, baale-ile, ngbadura si Olorun, " Oluwa mi, ma je ki arogun ole, ogun kolekole, ni ile mi la le oni. Jowo dabo re bo mi." Bee ni enikan nsadura, o si ngbadura bayi. Elo miran na nsadura, gege bi ole, "Oluwa mi, mo njade lo lati lo kole okunrin onile olona yi. Wa ba mi se ki nle ri nkan to da ji" Nisisnyi, kini ipo Olorun ? [Erin] Olorun wa ni okan olukaluku. Nitorina Olorun maa gba aduraa orisirisi. Ti jaguda ati ti ole ati ti onile-olona, orisirisi awon adura. Nitorina Olorun nse atunse.... Sugbon O si nse... Iyen ni ogbon Olorun, bi O se ntun kan se O fun olukaluku ni ominira. O si fun olukaluku ni awon irorun, sugbon won si nni lara. Nitori idi eyi, Olorun fi seniye fun awon olufokansin Re wipe "Ma se se ero kan kan. Iwo alailogbon, iwo alaiwulo, iwo ma fun mi ni wahala. [Erin]. Jare se iteribale fun Mi. Sà fi ero Mi se, inu re yi o si dun. Oun se ero, inu re ko si dun; Inu Emi na ko dun. [Erin] Inu emi na o dun. Opolopo ero l'onwa l'ojoojumo, mo si gbodo mu won se" Sugbon O je alaanu. Ti eni... Ye yathā māṁ prapadyante tāṁs... (BG 4.11).

Nitorinna yato si awon olufokansin Olorun, olukaluku nkan Fun ni wahala, wahala, wahala, wahala. Nitori idi eyi, won pe won ni duṣkṛtina. Duskrtina, tumo si, alabosi buruku, awon alabosi. Ma se ero kan kan. E gba ero ti Olorun. E kan maa ma fi Olorun ni wahala. Nitori idi eyi, olufokansin eniyan kii tile sadura fun ise dede re. Iyen ni olufokansin mimo. Ko nfun Olorun ni wahala koda fun itoju ara re paa pa. Ti ko ba ni itoju, a jiya, a ma gba awe, bakannaa, ko ni beere nkan kan lowo Olorun "Olorun, ebi npa mi. Fun mi l'ounje je" Daju daju, Olorun ma nsora fun olufokansin Re, sugbon ofin ti olufokansin ni lati ma fi ero kan kan si Olorun. Ki o ri bi Olorun se fe. A ni lati se gege bi ero Olorun.

Nitorina kini ero wa? Ero wa ni, Olorun wi pe, sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ (BG 18.66). Man-manā bhava mad-bhakto mad-yājī. Bee na ni ero wa se je nkan kan. A kan nkede fun Olorun, wipe"E fi okan sin Olorun." A ni lati fi apeere wa han, bi awa na se nfi okan sin Olorun, bi a se nsin Olorun, bi a se nka kiri igboro lati ke pe oruko Olorun, oruko ti kii se ti aye yi. Nisinyi a npin ounje mimo, aanu Oluwa. Bi agbara wa ba to, isé wa ni lati gba awon eniyan niyanju lati di olufokansin Olorun. Ko ju yen lo. Fun idi eyi, e le se ero yin, nitoripe ero Olorun ni yen. Sugbon iyen gbodo je nkan ti Olorun f'owo si. E ma da ero ti yin, ti ko ni ase sile. Nitorina, e ni lo ojise Olorun, lati fi ona han yin. Iyen ni oludari emi, alufa.

Bee ni ero nla-nla ati eto nla wa nbe. Nitorina a ni lati tele ipa ese awon mahajanas. Gege bi win ti so nibi, wipe: dvādaśaite vijānīmo dharmaṁ bhāgavataṁ bhaṭāḥ. O so wipe "Awa, iwon awa mahajanas ti won sa si bi, ojise Olorun, a mo eyi ti onse bhāgavata-dharma, nkan ti onse Kṛṣṇa dharma." Dvādaśa. Dvādaśa. Itumo dvaadasa ni oruko mejila, ti a ti so siwaju tele: svayambhūr nāradaḥ śambhuḥ... (SB 6.3.20). Mo ti se alaaye e tele. Bee ni Yamaraja so wipe, "Awa ni kan, eni mejila yi, awon ojise Olorun, la mo nkan ti o je bhāgavata-dharma." Dvādaśaite vijānīmaḥ. Vijānīmaḥ tumo si "awa la mo" Dharmaṁ bhāgavataṁ bhaṭāḥ, guhyaṁ viśuddhaṁ durbodhaṁ yaṁ jñātvāmṛtam aśnute. "Awa la mo" Nitorina, won gba nimoran, mahājano yena gataḥ sa panthāḥ (CC Madhya 17.186). Awon mahajanas yi, bi won ti se fi han, iyen ni ona otito lati ni oye Olorun, tabi igbala ti emi.

Bee ni a ntele Brahma-sampradāya na, akoko, Svayambhu. Brahmā. Brahmā, leyin na Nārada, lati Nārada, Vyāsadeva. Bayi, Madhvācārya, Śrī Caitanya Mahāprabhu, ni ona yi. Bee na lojo oni, nitoripe a ntele ipa ese ti Śrī Bhaktisiddhānta Sarasvatī Gosvāmī Prabhupāda, bee na eyi ni, ojo oni ni ojo ibi re.. A gbodo se iranti ojo yi towotowo. ki a si sadura si Bhaktisiddhānta Sarasvatī Gosvāmī wi pe "Awa se adehun lati fowo mu ise re. Nitorina fun wa ni okun, fun wa ni ogbon. A si wa l'aabo omo ise yin ti o nfi ona han wa." Bee ni a gbodo gbadura sadura bayi. Mo si l'ero wipe ni irole a ma pin prasadam, ounje ale Oluwa.