YO/Prabhupada 0057 - we Okan ni mimo



Lecture on SB 6.1.34-39 -- Surat, December 19, 1970

Revatīnandana: A ngba awon eniyan niyanju lati ma kepe Hare Krishna, a bi bee ko?

Prabhupāda: Bee ni. Iyen ni ona kan soso fun akoko yi. Ni pa ki ke pe Hare Krishna, nkan eni... Agbada oye gbodo di mimo toto. Nigba na lo le ri gba, o le ri imo ti emi gba. Laisi wipe a we okan ni mimo, a je nkan ti o soro gidi gan lati ni oye ati lati gba imo nipa ti emi. Gbogbo awon eto atunse - brahmacārī, gṛhastha, vānaprastha - won wa beeni fun wiwe mimo. Bhakti na si je ilana iwemimo, vidhi-bhakti. Sugbon ti a ba fi ara wa sinu ise esin Olorun, iyen na a si so wa di mimo. Tat-paratve... Sarvopādhi... Bi o ba se nd'ologbon tabi se nni idagbasoke ninu oye wipe oun je iranse Oluwa fun aye ailopin, oun yi o di mimo. Oun yi o di mimo. Sarvopādhi tumo si wipe oun ko le...Sarvopādhi A gbiyanju lati mu upaadhi re kuro, ipe loruko re, pe, "Emi omo Amerika," "Emi omo Indian," "Emi eyi," "Emi ohun." Bee na ni ise bayi, nigbati e ko nba fi ti ero ara lo mo patapata, nigbana ni e di nirmalam. O di nirmala, alaini ibawon. Ati titi di igba ti ero aye yi ba ngbode wipe "Emi eyi," "Emi ni tohun," o si wa ninu... Sa bhaktaḥ prakṛtaḥ smṛtaḥ. (Ni egbe:) Koko dara dara, kii se be yen. Sa bhaktaḥ prakṛtaḥ smṛtaḥ. Arcāyām eva haraye... Ninu ilana yi paapa, nigbati won fi ara won sise esin Olorun, arcāyāṁ haraye yat-pūjāṁ śraddhāyehate, ti o si nse pelu ifokansi pupo, sugbon na tad bhakteṣu cānyeṣu, sugbon ko ni iba se idaro pelu awon elomiran tabi ko mo ipo eni ti o je olufokansin, nigbana sa bhaktaḥ prakṛtaḥ smṛtaḥ: "A npe ni onigbagbo yepere, onigbagbo yepere"; Nitorina a gbodo gbe ara wa soke lati ipo ifokansin yepere si ipo keji nibi ti a ti le mo iyi eni ti o je olufokansin, tani alaini gbagbo, tani Olorun, tani alaini kaferi. Ise-iyato si yi wa nbe. Ati ni ipo paramahamsa, ko si iru ise-iyato si be na. O ri pe gbogbo eniyan lo nfi ara fun ise Oluwa. Ko nse ijowu eni kan kan, ko ri nkan kan, eni keni. Sugbon ipo miran ni yen. A o gbodo se afarawe, gbiyanju lati farawe, a le kiyesi wipe paramahamsa ni ipo to gaju lo ni ipa ti di mimo ati pipe. Gege bi oniwasu a gbodo s'apeere... Gege bi mo se so fun odo mokunrin yi, "Joko ba yi." Sugbon ti o ba je paramahamsa ko ni so be. Eniti o je paramahamsa, a rii, sugbon fun oun: "O wa daradara ni bo se wa." O rii. Sugbon a ko gbodo farawe paramahamsa. Nitoripe a je oniwasu, a je oluko, a ko gbodo farawe paramahamsa. A gbodo fi abe ge oro, bi o ti ri.

Revatīnandana: Ipo yin gbodo ju ti paramahamsa lo, Prabhupada.

Prabhupāda: Mo réléju é lo. Mo réléju é lo.

Revatīnandana: E ti l'ewa ju. Bi o ti le je wipe paramahamsa ni yin, e si nse iwasu fun wa.

Prabhupāda: Rara, Emi réléju é lo. Emi ni o rélé ju ninu gbogbo awon eda Olorun. Mo kan ngbiyanju lati se pa asé ti Oluko igbala mi. Ko ju yen lo. Iyen gbodo je ise olukalulu. E se ni gbiyanju. E se gbogbo igbiyanju yin lati pa asé imoran to ga laseyori. Iyen ni ona ti o joju julo nipa ise ilosiwaju. A le wa ni ipo ti o rélé julo, sugbon ti a ba gbiyanju lati se ojuse ise ti won fi se ojuto wa, a o si di pipe. Bi o ti le wa ni ipo ti o rélé ju lo, sugbon nitori wipe o nse yanju lati se ojuse nkan ti a fi loo, nigbana o di alaini ibawon. Iyen ni fi fi se ifiyesi.