YO/Prabhupada 0078 - E kan ma gbiyanju pelu igbagbo lati gboro



Lecture on SB 1.2.16 -- Los Angeles, August 19, 1972

Nitorina śuśrūṣoḥ śraddadhānasya vāsudeva-kathā-ruciḥ. Ninu ese to koja, won ti se alaye, yad anudhyāsinā yuktāḥ (SB 1.2.15). A ni lati fise se lati maa ronu nigba gbogbo. Ida na ni yi. E ni lati mu ida isokan Olorun yi. Igba na ni e yege. Abe ni laju koko. Bee na... Bawo la se le ri ida yi? Won s'alaye ona na nibi wipe e kan ma gbiyanju, pelu igbagbo, lati gboro. E ma ri ida na gba. Ko ju yen lo. Ni ododo, egbe isokan Olorun wa yi ntanka. A ngba ida na ni iko-kan, nipa gbigbo oro nikan. Mo bere egbe yi New York. Iyen je mi mo fun gbogbo yin. Mi o ni ida kan teletele Bi ise awon esin miran, won a mu iwe mimo lowo kan ati ida ni owo keji: "E gba iwe mimo yi; bi beko ma ge e lori." Eyi na je ona iwasu miran. Sugbon emi na ni ida, sugbon ki se iru ida kan na. Ida yi - ka fun awon eniyan l'aye lati gboro. Ko ju yen lo.

Vāsudeva-kathā-ruciḥ. Bee na gbere ti o ba ti ni ruci... Ruci. Ruci tumo si adun. "Ah, oro Olorun ni yi, o dara gan. Je ki ngbo." Dede yi ni kan e ti gba ida na, lesekese. Ida na wa ni owo yin. Vāsudeva-kathā-ruciḥ. Sugbon odo tani ruci na wa? Adun yi? Nitoripe, bi mo ti s'alaye ni igba pupo, adun na, gege bi didun ireke. Gbogbo eniyan lo mo wipe o dun gan, sugbon ti e ba fun eni ti o nsarun iba-aponju, o ma koro lenu re. Gbogbo eniyan lo mo wipe ireke je didun, sugbon eni ti o nsa aisan, iba-aponju, ireke a koro lenu re. Gbogbo eniyan lo mo. O je ododo.

Bee na ruci, adun gbigbo oro vāsudeva-kathā, kṛṣṇa-kathā, alaare ohun aye yi ko le mo didun. Ruci yi, adun. Lati ni adun yi awon ise ipinlese wa. Kini nkan nna? Ekinni ni imoyi: " Oh, o dara gan." Ādau śraddhā, śraddadhāna. So śraddhā, So śraddhā, imoyi na, eyi ni ibeere Nigba na ni sādhu-saṅga (CC Madhya 22.83). Leyin na ni idarapo: O dara, awon eniyan yi nkorin won sin soro nipa Olorun. Je ki nlo joko lati gbo pupo si." Eyi ni a npe ni sādhu-saṅga. Awon ti won se olufokansin, lati darapo mo won. Eyi ni ese keji. Ese keta ni bhajana-kriyaa. Ti ajosepo wa ba nlo dede, nigba na ni o ma wu ni lokan, "Kilode ti emi na o ni di omo eleyin?" Bee ni a gba ifilo, "Prabhupada, ti o ba le fi ti anu re gba mi bi omo leyin re. Eyi ni ibeere bhajana-kriya. Bhajana-kriyaa tumo si lati wa ninu ise Olorun. Eyi ni ese keta.