YO/Prabhupada 0082 - Olorun wa nibi gbogbo



Lecture on BG 4.24 -- August 4, 1976, New Mayapur (French farm)

Olufokansin: A so wipe Olorun wa ninu elemi, ninu okan eda alaaye.

Prabhupada: Olorun wa nibi gbogbo.

Olufokansin: Nipa ti eda abi nipa ti agbara?

Prabhupada: Nipa ti agbara Re. Nipa ti eda na, sugbon nipa ti eda a ko le ri iyen pelu oju wa yi. sugbon a le mo agbara. Se alaye ero yi pupo pupo si. Bee na nigbati a ba ti di eni atunbi ni ikun rere, nigba na iwe ese yi, pe gbogbo ohun ni se emi, brahma, sarvaṁ khalv idaṁ brahma... Alagba olufokansin, ko nri nkan miran afi Olorun.

Olufokansin: Srila Prabhupada, se iyato gidi kan wa laarin agbara ti aye at agbara ti emi?

Prabhupada: Bee ni, iyato, iyato pupo lo wa. Apeere kan na, ti ina ijoba. Orisirisi nkan ni won nse se, agbara to yato. Ero agbohun-oro na paapa nse se, ina ijoba. Nipa agbara kan na, ina ijoba. Nitorina Olorun so wipe ahaṁ sarvasya prabhavaḥ (BG 10.8). Oun ni orisun gbogbo nkan.

Olufokansin: Won se ni alaye ninu Bhagavad-Gita wipe eniyan nyi ara pada ni igbesi aye yi na. sugbon a ri wipe eniyan dudu ko ndi funfun, tabi wipe o wa ni kan bakan, nkankan wa ti o duro bakan ninu ara koda bi o se nyi pada. Kini nkan na? Bawo lo se ri be, ti ara nyi pada sugbon a si le da eni na mo lati odo titi di arugbo.

Prabhupada: Bee na nigba ti oye yin ba tun losiwaju si e o ri wipe ko si iyato laarin dudu ati funfun. Gege bi ododo se njade, opolopo awo lo wa. Bee na ni o se nwa lati orisun kan na. Nitori idi eyi ko si iru iyato na, sugbon lati fi ewa si ni opolopo awo se wa. Ninu oorun awo meje lo wa, ati lati inu awo meje yi, aimoye-awo njade sita, lati inu orisun awo funfun kanna, nigba na si ni orisirisi awo njade. Se o ye wa abi beko?

Olufokansin: Srila Prabhupada, ti Olorun ba ti da gbogbo nkan ati pe gbogbo nkan nforibale fun ase Re, se a le so ni daju kini nkan to dara tabi ko dara?

Prabhupada: Ko sin nkan to dara tabi eyi ti ko dara, eleyi je ero okan wa, Sugbon ni agbele imoran, ninu aye asan yi gbogbo nkan ni ko dara.