YO/Prabhupada 0084 - Ki e kan di Olufokansi Olorun
Lecture on BG 2.22 -- Hyderabad, November 26, 1972
Bee na idamoran wa ni lati gba imoran l'owo Krishna, eni ti o je pipe, Atobi Ju lo Olorun-Oba Metalokan. A gba iwe mimo, to tumo si alainibawon. Ko si asise. Bi igbati mo nrin ni bi ile-malu, awon okiti, igbe malu ti won ko le ra won. Bee ni mo se nse alaaye fun awon omo-eleyin mi wipe, ti eranko, e se yonu mi, ti won ba ko igbe eniyan jo sori ara won nibi yi, ko si eni to ma wa bi. Ko si eni ti o ma wa sibi. Sugbon igbe malu, bi won ti po to bi okiti ogan nibi yi. sibe na a nrin koja ninu re laini irora. Bee na ni ninu awon vedas won so wipe, "Igbe Malu je nkan mimo." Eyi ni a npe ni shastra. Ti e ba jiyan, "Bawo lo se leri be? Igbe eranko lo je." Sugbon awon Vedas... Nitoripe imo na je pipe, to je be wipe paapa ninu ijiyan ko si bi a se le fi ye yan bi igbe eranko se le je mimo, sugbon o je mimo. Nitorina imo Vediki wa ni pipe. Ti a ba si gba imo lowo awon Vedas, a o ni pa akoko nu pupo fun iwadi tabi iwadi. A ni ife a ti se iwadi pupo. Gbogbo nkan lo wa ninu awon Vedas. Kilode ti e fi npa akoko nu?
Bee ni eyi ni imo Vediki. Imo Vediki tumo si oro Olorun Oba. Iyen ni a npe ni imo Vediki. Apauruseya. Ko nse oro ti o jade l'enu eniyan lasan bi emi. Bee na ti a ba gba imo Vediki, ti a ba gba, ododo oro bi Olorun se wi, tabi iranse Re... Nitori wipe iranse Re ko ni so nkan kan ti Olorun o ba o wi. Nitorina lo se je iranse. Awon ti won se isokan Krishna je iranse Olorun nitoripe eniti o nse isokan Olorun ko ni so isokuso koja oro Olorun. Iyen ni iyato. isokuso, alaibikita, won a soro koja Olorun. Olorun so wipe, man-manā bhava mad-bhakto mad-yājī māṁ namaskuru (BG 18.65), sugbon alaibikita akowe ma so wipe, "Rara, ki se fun Olorun. Nkan miran ni. Nibo le ti ri eleyi? Olorun so tara ra wipe, man-manā bhava mad-bhakto mad-yājī māṁ namaskuru (BG 18.65), Bee na kilode ti e fi nfona? Kilode ti e nso nkan miran: "Nkan ti o wa ninu Krishna"? E ma ri... Mi o fe daruko. Opolopo awon alaibikita akowe ni won wa. Won nse itumo bayi Nitorina bi o ti le je wipe Bhagavad-Gita je iwe imo ijinle india, opolopo ni won nsi lona. Nla... Nitori awon alaibikita akowe won yi, awon afenuwi-alakowe. Nitoripe won kan nsi tumo.
Nitorina ni a se nse afi han Bhagavad- Gita Gege Bi O Se Ri Olorun Krishna so wipe, sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja (BG 18.66). A wa so wipe, a nse iwasu egbe yi. " E fi okan yin fun Oluwa. Ki e kan di olufokansin Olorun. E fi ori bale..." E gbodo fi ori bale fun eni keni. E ki se eni to ga julo. E ni lati pon enikan le lati ri ise gba. Iyen je... Bi e ti le ni ipo to dara, e si ma pon ni le. Ko da ti e ba ni ipo alakoso, ti e ba di alakoso olorile ede, e ni lati pon awon omo orile ede yin le: "E jo e dibo fun mi. E jowo, ma fun yin ni opolopo amuludun." Bee ni e gbodo pon ni le. Ododo oro ni yen. E le je eniyan pataki. Sugbo e gbodo pon enikan le. E gbodo gba enikan gegebi oga. Kilose ti e o ni gba Olorun, oga atobiju? Kilo je isoro nbe? "Rara o. Ma gba egbe gberun awon oga, ayafi Olorun." Eyi ni imo wa. "Ma gba egbe gberun awon oluko, ayafi Krishna. Eyi ni ipinnu mi." Bawo ni inu yin se le dun? Idunu se ni nigbati a ba gba Olorun nikan.
- bhoktāraṁ yajña-tapasāṁ
- sarva-loka-maheśvaram
- suhṛdaṁ sarva-bhūtānāṁ
- jñātvā māṁ śāntim ṛcchati
- (BG 5.29)
Eyi ni eto shanti, alaafia. Olorun so wipe ki e gba pe "Emi nikan ni onigbadun. Eyin ki se onigbadun;" E ki nse onigbadun. E le je alakoso orile-ede, tabi akowe, e le je enikeni ti e le je. Sugbon e ki nse onigbadun. Onigbadun ni Olorun. Eyi gbodo je mi mo. Gege bi ninu yin.... Mo ti wa, mo nbo, wa fi esi fun iwe iranse ti mo gba lati odo Iranlowo Igbimo Andhra. Kini ajo igbimo iranlowo le se ti inu Olorun o ba dun si? Nipa sise akojo owo lasan? Rara, iyen ko le se se. Bi ojo se nro nisinyi. Bayi e o si ri anfaani. Sugbon riro ojo iyen wa l'owo Olorun, ki se nipa agbara yin lati kowo jo.