YO/Prabhupada 0119 - Gbogo igba ni Ẹmí fi n'ruwe



Lecture on BG 2.1-10 and Talk -- Los Angeles, November 25, 1968

Prabhupāda: Beeni.

Śrīmatī: Se ohun ti ogbó je niyen, bi emi se nfi ara sile, se iyen lo mu e dàgbà?

Prabhupāda: Rara, ẹmí o n'darugbo. Ara ni o nni iyipada, iyen ni éto atunwa. Iyen a ni alaaye toba ya,

dehino 'smin yathā dehe
kaumāraṁ yauvanaṁ jarā
tathā dehāntara-prāptir
dhīras tatra na muhyati
(BG 2.13)

Gbogo igba ni Ẹmí fi n'ruwe. Ara a si maa yipada. Eyi ni lati ye wa. Ara n'yipada. Iyen je nkan ti gbogbo eniyan loye. Gẹgẹ bi ni'gba ewe rẹ ara rẹ wà ... Gege bi omode yi, ara re yato. Ati nigbati ọmọ nàà yio je odo omobirin, iyen a je ara ti o yatọ. Ṣugbọn ẹmí ọkàn wa nibẹ ninu ara yi ati ti ara t'ohun. Nítorí náà, èyí ni ẹri pé ẹmí ko ni ayipada, ara a yipada. Eyi ni ẹri wa. Mo n lero igba ewe mi. Eyi tumo si wipe emi kanna ni "Emi" ti o ti ti wa tẹlẹ ni igba ewe mi, emi si ranti ni igba ewe mi bi mo se n seyi, ati t'ohun.. Sugbon ara ti igba ewe na ko si mọ.. Iyen ti lọ Nitorina o jẹ pinnu ọrọ pé ara mi ti yi pada, sugbon Èmi ni eni kanna. Ṣe bee ko? Eyi jẹ òtítọ ti o rọrun. Nítorí náà, ara yi yio yipada, sibe emi o si wa nibe. Mo ti le tẹ sinu ara miran, iyen ko se pataki, ṣugbọn emi o si tun wa nibe. Tathā dehāntara-prāptir dhīras tatra na muhyati (BG 2.13). Bi ara mi se nyipada paapa ninu igbesi aye yi, bakanna, iyipada igbẹhin ko tumo si wipe Èmi ti ku. Mo tẹ sinu ara miran ... Iyen tun salaye, vāsāṁsi jīrṇāni yathā (BG 2.22), pe mo ti yipada. gẹgẹ bi nigbati emi o kì nse sannyāsī, mo ti ma nwọ aso gẹgẹ bi eyikeyi okunrin jeje. Bayi mo ti yi imura mi pada . Iyen ko tunmọ si wipe mo ti kú. Rárá. Mo ti ti yi ara mi pada , o pari. Mo ti yi imura mi pada.