YO/Prabhupada 0137 - Kini opin aye



Lecture on BG 7.4 -- Nairobi, October 31, 1975

Harikeśa: Isotumo - Ile, omi,afẹfẹ,ina, ofurufu, okan, ogbon ati iyi-ara eke - awon nkan mejo wanyi lowa ninu agbara mi l'aye yi".

Prabhupāda:

bhūmir āpo 'nalo vayuḥ
khaṁ mano buddhir eva ca
ahaṅkāra itīyaṁ me
bhinnā prakṛtir aṣṭadhā
(BG 7.4)

Kṛṣṇa ti salaaye nipa ara re. Olorun ti Salaaye nipa eni t'Olorun je. Imoye to daju niyen. Kosi basele roriwo nipa eto Olorun. Alailopin ni Olorun je. Oro re kole yewa. Ni alakoko Kṛṣṇa sowipe, asaṁśayaṁ samagraṁ māṁ yathā jñāsyasi tac chṛṇu (BG 7.1) Odindin ni itumo Samagram. Ounkooun ti ori-oro na ba je, Olorun ni apapọ gbogbo nkan. Nitorina lo sen salaaye nipa ara re pe...

Ni alakoko, nitoripe awa oni ìròyìn kankan lori Olorun - sugbon alefoju ri gbogbo ile, gbogbo okun aye yi, gbogbo ofurufu lori wa, ati ina. Orisirisi nkan ni aye yi. Okan wa na nkan aye yi loje pelu iyi-ara w. Gbogbo eyan lon ronu pe " Nkan bayi bayi nimo je.... Kartāham iti manyate. Ahaṅkāra-vimūḍhātmā. Iyi ara niyen. iyi-ara eke ni itumo iyi-ara tan so. Sugbon iyi-ara gidi sii wa. ahaṁ brahmāsmi ni iyi-ara gidi, " ara ilu India nimi", "ara-ilu America nimi", "ara-ilu Africa nimi", "brāhmaṇa nimi," "kṣatriya nimi", nkan bay bayi nimi", - iyi ara eke ni gbogbo eleyi iyi-ara eke, ahaṅkāra. Nigbogbo'gba ni awon nkan yi yikaa kiri gbogbo wa. Ibere imoye wa niyen. Nibo ni gbogbo ile yi tiwa? Niboni omi yi tiwa? Niboni ina yi towa? Awon ibeere adayeba loje. Niboni ofurufu tiwa? Bawo ni awon irawo yi se po bayi? Awon ibeere eni to l'ogbon leleyi. Ibere aye imoye leleyi. Nitorina awon eyan to logbon, die die ni wanma bere sini beere nipa Olorun, Kṛṣṇa.

Kṛṣṇa wan'be, Kṛṣṇa de ti salaaye ara re, " Bayi bayi nimo je". Sugbon íròjú towa niwipe awan eyan o fe mo nipa Krsna, sugbon awa fe roriwo nipa Olorun. Aisan wa niyen. Krsna ti salaaye ara re; Olorun salaaye nipa ara re. Sugbon awa o fe gba awon oro yi, ale jiyan tabi ale nigbagbo ninu Olorun tio lori tabi ese. aisan wa niyen. Nitorina ninu ese-iwe to kehin wanti salaaye,

manuṣyāṇāṁ sahasreṣu
kaścid yatati siddhaye
yatatām api siddhānāṁ
kaścin māṁ vetti tattvataḥ
(BG 7.3)

Ninu iwonba awon eyan to po repete yi, iwonba die lofe ni oye re, " Kini opin aye? Eyan wo ni Olorun je? Iru ibasepo wo nimoni pelu re...." Koseni tonifesi.. Sa eva go-kharaḥ (SB 10.84.13). Awon eyan feran ile-aye yi bi aja ati ologbo. Ipo aye wa leleyi. Bi ile-aye yi seri niyen. Sugbon iwonba die ninu awon eyan, manuṣyāṇāṁ sahasreṣu, loni oye nipa eto yi. lati iwonba awon bayi...

Lati monipa ipo wa laye yi ni itumo aini-asise, odaju fun pe ara re ko loje, emi loje, Brahman. brahma-jñāna, Imoye to gaju niyen.