YO/Prabhupada 0154 - Ohu-ijagun yin ma wa ninu mimu nigbogbo 'gba
Room Conversation -- May 7, 1976, Honolulu
Tamāla Kṛṣṇa: Ninu iwe irohin "Back to Godhead" eyin salaaye nipa Marx, e sowipe oniranu loje, esi sowipe iranu ni imoye Marx je.
Prabhupāda: Beeni, Kini imoye to gbe jade? Ijiyan Dialectitude?
Tamāla Kṛṣṇa: Dialectitude ti aye yi.
Prabhupāda: Awon na ti ko nkan lori Dialectic t'emi.
Hari-śauri: ti Harikeśa.
Prabhupāda: Harikeśa.
Tamāla Kṛṣṇa: Beeni, oti ka si wa. On sewaasu, ni Orile-ede Europe ni õrùn nigbami. Awa ti ni iroyin. So ti ko leta sin yin?
Prabhupāda: Beeni. Bi mo se gbo niyen, sugbon semo boya dada lowa?
Tamāla Kṛṣṇa: sugbon lati iroyin ti mo gbo nigbami o man lo si awon ilu Europe ni apa õrùn. Nisin mo gbo pe o wa ni ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì , ni jẹ́mánì ati awon ilu Scandinavia. Oni awon ton tele, wan sin lon kakiri ton pin awon iwe yin. awon ilu wo lo tun lo?
Elesin: Czechoslovakia, Hungary, Budapest.
Tamāla Kṛṣṇa: On lo si awon ilu Komunisiti ni Europe.
Elesin: Wansi gbe iho sinu oko wan lati le fi awon iwe na pamo, konba ma ri tonba de ààlà awon ilu yi. Ninu oko wanyi wanti fi awon iwe yin pamo. Ton ba ti wo awon ilu wanyi wan ma pin fun awon akeko to wa n'be.
Tamāla Kṛṣṇa: Iyika.
Prabhupāda: O da gan.
Elesin: O sowipe nigbami to ban soro, awon ton se isotunmo man so nkan mi to yato nitoripe...
Tamāla Kṛṣṇa: Nigbami o man gbagbe - diedie lon salaaye fun wan - awon oro to daju. Sugbon nigbami to ban soro nipa imoye Krsna, eniton se isotunmo fun a dake, kode ni soro mo ninu ede ilu wan mo. Nigbami oman gbagbe ara re a de bere sini soro nipa Krsna, pe Olorun lo je eni ton se isotunmo a de wo. Sugbon diedie lon ba wan soro, gbogbo nkan ko lon gbe jade.
Prabhupāda: Oti sise toda.
Tamāla Kṛṣṇa: Eyan to daju loje, osi l'ogbon gan.
Prabhupāda: gege bayi .. Ologbon leyin je, ele s'eto bayi. Opin wa ni bawo lasele pin awon iwe yi. Eto t'alakoko leleyi. Ninu Bhāgavata wanti salaaye wipe ati ni ara yi pelu orisirisi apa. gege bi Arjuna se joko lori kẹkẹ elesin. kẹkẹ yi si ni eyan to wa, pelu awon ẹṣin, ile yi si wa , ati ọfa pelu àkàtàmpó . sugbon wan fi wan fis'apeere. Awa lelo awon nkan yi fi pa awon ota imoye Imoye Krsna lehin na a le fi gbogbo awon nan yi sile,... gege bi ogun, teba ja tan , ele fiku pa wan. gege bi ara wa, okan wa ninu re, awon iye ara wa si wa ninu re. gege na ele lo lati fi ni idari lori iseda ile-aye yi. lehin na ele fi ara yi sile kesi pada lo sile ni ijoba Orun.
Tamāla Kṛṣṇa: Se awon elesin bi teyin ton sise lati ti egbe yi siwaju..
Prabhupāda: besele jeki awon ohun-ijagun di mimu. Wanti salaaye eto yi na. Teba sise fun oluko yin,ohu-ijagun yin ma wa ninu mimu nigbogbo 'gba. lehin na ele gba iranlowo lati Krsna. Awon oro Oluko lon je ki ohun-ijagun wa di mimu. yasya prasādad bhagavata... ti inu Oluko wa ba dunsi, lehin na lesekese ni Krsna ma ranwa lowo. A fun yin l'agbara. fun apeere teba ni ada to mu gan, sugbon teyin o ba l'agbara, ki lema se pel'ada na? Krsna ma fun yin l'agbara, besele ba awon ota yin ja ati besele pa wan. Gbogbo nkan lo salaaye. Nitorina ni Caitanya Mahāprabhu (se sowipe) guru-kṛṣṇa-kṛpāya (CC Madhya 19.151), E jeki ohun-ijagun yin wani mimu pelu awon ilan Oluko yin, Krsna a si fun yin l'agbara lati ni idari lori awon ota yin. Moti salaaye nipa apeere yi ni ale anaa. Ese-iwe kan si wa, acyuta bala, acyuta bala. Se Puṣṭa Kṛṣṇa wa nibi?
Hari-śauri: Puṣṭa Kṛṣṇa?
Prabhupāda: jagunjagun ti Krsan ati iranse Arjuna ni wa. teba si tele ilana ton fun wa, ema pari awon ota yin. Kosi bonsele l'agbara, boba tie po ju yin lo ni'gba ogorun. gege bi awon Kurus ati awon Pandava. Awon eyan yi o l'agbara, yatra yogeśvaraḥ kṛṣṇaḥ (BG 18.78). Efi Krsna s'odo yin, gbogbo nkan asi lo dada. Tatra śrīr vijayo.