YO/Prabhupada 0194 - Awon eyan gidi leleyi



Lecture on SB 7.6.4 -- Toronto, June 20, 1976

Gege na gbogbo wa gbudo gba sastra-vidhi, itumo re niwipe ilosowaju gidi fun awujo wa leleyi. Nitoripe lehin aye kan sikeji ati gbagba ibasepo pelu Olorun, aye kan sos tani, lara eda eyan tani yi, ale ji ibasepo yi soke pelu Olorun. Ninu Caitanya-caritamrta wan sowipe: anādi bahir-mukha jīva kṛṣṇa bhuli' gelā ataeva kṛṣṇa veda-purāṇa karilā. Kini di fun awon Veda wanyi, Purana wanbe? Nipataki ni Orile-ede India, ani orisirisi awon iwe mimo Veda. L'alakoko awon Veda merin- Sama, Yajur, Rg, Atharva. Lehin na imoye Vedanta-sutra. Ijuwe Vedanta, awon Purana. Iyonda nitumo awon Purana Awon eyan lasan o le no iye nipa ede Veda. Nitorina lati oju itan akoole lon salaaye awon ofin Veda. Nkan ton pe ni Purana Mahā-purāṇa l'oruko Śrīmad-Bhāgavatam. Koni alebu kankan, Śrīmad-Bhāgavatam, nitoripe ninu awon Purana iyoku, awon nkan aye wa ninu wan, sugon ninu Maha-purana, Śrīmad-Bhāgavatam, awon ise mimo nikan lowa ninu e. Nkan ta fe niyen Gege na Vyasadev ti ko Śrīmad-Bhāgavatam yi labe ilana Narada. Maha-purana. gege na agbudo gba anfaani yi. Orisirisi awon iwe mimo ton wa ninu e. Idi fun ile-aye eda leleyi. Kilode teyin sen ti segbe kan? Nkan tawa fese ninu egbe imoye Krsna yi ni bawo lasele pin imoye awon Veda ati Purana, ki awon eda eyan bale gba lati fi tun ile-aye wan se, ko bale ni ilosiwaju. Bibeko, to ba kan sise la taro daale bi elede.. Elede n sise lataaro d'aale lati waadi " Nibo ni igbe wa? Nibo ni igbe wa?" Lehin to ba ti je igbe yi tan, to sonra die.. Awon elede sanra gan nitoripe igbe ni gbogbo awon nkan ton se pataki ninu ounje. gege bi awon oni sayensi nipa ilera se so, hydrophosphate po ninu igbe. Nkan pataki ni hydro phosphate je. Awon eyan le towo tonba fe. ( Erin) Sugbon oto oro nimon so. Elede man sonra nitori igbe ton je.

Gege na ati dabi awon elede ko l'opin aye yi. Agbudo d'eyan mimo. Awuno eyan leleyi. Nitorina ninu awujo veda - brāhmaṇa, ipo kini awon okurin. Koseyan kankan ninu ipo kini ninu awujo awon eyan nisin. Lati ipo keta, kerin, karun.. nigbogbo wan wa. Satya-śama-dama-titkṣa ārjava jñānaṁ-vijñānam āstikyaṁ brahma-karma svabhāva-jam (BG 18.42). Okurin lati ipo kini leleyi. Oto oro, o feran alafia, o l'ogbon gan, o rorun, oni ifaramo, osi nigbagbo ninu awon sastra. Awon aami eyan ninu ipo kini leleyi. Nibo ni okurin lati ipo kini yi wa ninu gbogbo agbaye? ( isinmi) ... egbe imoye Krsna yi fe da apa awon okurin lati ipo kini, ki awon eyan bale ri wipe, " oh, awon eyan gidi leleyi." Gege a ibeere mi niwipe, eyin teti wa sinu egbe imoye Krsna yi, E gbiyanju lati se wan l'eyan lati ipo kini. Awon ma niife yin wansi gbiyanju lati tele. Yad yad ācarati śreṣṭhas tat tad evetaro janaḥ (BG 3.21). Ti awon okurin lati ipo kini ba wa, awon eyan ma niife wan. wan gbiyanju lati tele wan, toba tie le fun wan lati tele Wan gbiyanju lati tele. Tat tad eva, sa yat pramāṇaṁ kurute lokas tad anuvartate. gege na okurin ti ipo kin yi si wa. Toba huwa, awon eyan ma tele. Ti oluko o ban fa ciga, beena awon akeko na o ni fa ciga. Sugbon ti oluko ban fa ciga, bawo ni awon akeko....? Wan fa ciga ninu ile-iwe. Moti ri ni New York. Ni orile-ede India iru nkan bayi o ti bere. Sugbon koni pe bere, nitoripe awon na tin ni ilosiwaju. (Erin) Awon asiwere wanyi, wan ni ilosiwaju to ma mu wa lo si oorun apadi.

Gege na, Prahlada Maharaja ti salaye, ema lo asiko yin ni ilokulo lori awon eto bi oro-aje ati awon iranu wanyi. Egbiyanju lati di elesin Mukunda. Lehin na ile aye yin ma ni ilosiwaju.