YO/Prabhupada 0206 - Ninu awujo Vediki ko sooro owo
Morning Walk -- October 16, 1975, Johannesburg
Prabhupāda: aṣiwère ni gbogbo wan je, gege be o ye ke ko wan l'ogbon. Nkan te ma se niyen. aṣiwère ni gbogbo wan je Ko si ibeere pe eleyi yato si iyoku, O logbon. Rara, aṣiwère ni bogbo wan je. l'akọkọ e mu gbogbo wa bi aṣiwère, ke de kọ won l'ogbon. Nkan ta fe ni ye L'enu bayi ile aye yi kun fun awon aṣiwère. O ye ka kọ won l'ogbon. Ti won ba mu s'okan iwaasu imọ ohun Krsna (Oluwa) e yan won si ototo. Gege bi emi na se kọ yin. Mo ti fun yin ni ikẹkọ brāhmaṇa Gege na awon ton ba mura lati gba ikẹkọ to ma se won ni brāhmaṇa, e pe won ni brāhmaṇa. Elomi ni ikẹkọ kṣatriya, e pe ni kṣatriya. Gege bayi, cātur-varṇyaṁ māyā sṛṣ...
Harikeśa: Se kṣatriya na le kọ awon eyan.
Prabhupāda: Hm?
Harikeśa: Se O le ya awon eyon si ototo na gege bi Brahmana?
Prabhupāda: rara, rara, rara. E wo le ma ya won s'oto.. E ya gbogbo awon eyan s'oto, emu won bi śūdra. Nigbano..
Harikeśa: E mu won s'oto.
Prabhupāda: E mu won s'oto, awon iyoku ti won ba je kṣatriya tabi vaiśya, iyen bo si pe śūdra lo je. O tan. O de rorun. Ti ko ba le gba ikeko to ma so di ẹlẹrọ, ko le si ilosiwaju ninun aye re. O ma wa bo se wa. Kon se dondon. Bayi loye ka ṣeto ilu wa. Kon se dondon. Awon Śūdra na si ni iwulo
Puṣṭa Kṛṣṇa: Laye isin owo ni imoriya eto ẹkọ. Amo Kini imoriya laye ati ijo ni aṣa Veda?
Prabhupāda: ko si nilo fun owo. Awon brāhmaṇa man kọ laisi idiyele. Ko si oro owo. ẹnikẹni to ba fe di brāhmaṇa tabi kṣatriya, tabi vaiśya le gba eko ni ofe. Awon Vaiśya o fi be nilo fun eko kiko. Awon Kṣatriyas nilo díẹ. Awon Brahmana nilo fun gan sugbon ofe ni fun won. Eyan gbudo wa brāhmaṇa guru (Oluko) to le kọ yan l'ofe. Otan. Sugbon ni isin ti eyan ba fe se eto ẹkọ ogbudo ni owo repete. Sugbon na in asa Veda ko si oro owo. Ofe ni eto ẹkọ
Harikeśa: Se idunnu lo wa je imoriya ni asa Veda?
Prabhupāda: Bee nani. Gbobo eyan sa tele idunnu. Eyi lo ma fun wa ni idunnu. Ti awon eyan ba ni alaafia ni aye wan gege na wan ni idunnu Kon se pe ka ma ro nu " Ti mo ba ni ile to tobi igbano ni inu mi a dun" boba ya awon ton ro nu bayi l'on ma se igbẹmi ara ẹni. Nkon to se le ni yen. Eni na ro nu pe " ti mo ba ni ile to tobi, Idunnu mi a dun" sugbon nigbati ibanuje ba ti bo si okan re, asi pa ara re. Nka to se ni yen. Idunnu ti aye fe ni yen. awon aṣiwere won yi o mo nkon ti idunnu je. Nitorina ni gbogbo wa se ni lati gba ìbójútó ti Krsna (Oluwa). Eyi je imo ohun Oluwa. O se so fun mi pe ni Orile -ede yin iwọn igbẹmi ara ẹni po gan?
Puṣṭa Kṛṣṇa: Beeni.
Prabhupāda: Kilode ? Orile -ede yin si ni owo to po gan kilode to je pe awon eyan pa aran won ni bi? O de so wipe ni Orile-ede yin eyan o le je talaka.
Puṣṭa Kṛṣṇa: Beeni, ni bi o ma le gan at di talaka.
Prabhupāda: Beeni. Ki lo de ton wa pa ran won. kilode? Ti gbogbo eyan ni Orile-ede yin je Olowo kilode ton se gbemi ara won? Hm? Se wo ni idaaun? Ajo: Se aini idunnu l'on fa?
Prabhupāda: Beeni. Kosi idunnu kan kan