YO/Prabhupada 0400 - The Purport to Sri Sri Siksastakam



Purport to Sri Sri Siksastakam, CDV 15

ceto-darpaṇa-mārjanam bhava-mahā-dāvāgni-nirvāpaṇaṁ
śreyaḥ-kairava-candrikā-vitaraṇaṁ vidyā-vadhū-jīvanam
ānandāmbudhi-vardhanaṁ prati-padaṁ pūrṇāmṛtāsvādanaṁ
sarvātma-snapanaṁ paraṁ vijayate śrī-kṛṣṇa-saṅkīrtanam

Oluwa Caitanya funwa ni ese-iwe mejo nipa ise apifunni re, nkan to fe ka se. Won salaaye nipa won ninu awon ese iwe mejo wanyi, Śikṣāṣṭaka lon pe won. itọsọna nitumo Śikṣā, mejo nitumo āṣṭaka. Ninu awon ese-iwe mejo wanyi pere o ti paari gbogbo itosona re, awon akeko re, awon Gosvami mefa ti salaaye ninu iwe to po gan.

Oluwa Caitanya sowipe koko oro to wa ni paraṁ vijayate śrī-kṛṣṇa-saṇkīrtanam: gbogbo ogo fun orin kiko Hare Kṛṣṇa mantra tabi egbe Kṛṣṇa saṇkīrtan. Gbogbo ogo. Gbogbo isegun. Bawo lose je isegun, gbogbo isegun? Oti salaaye, pe ceto-darpaṇa-mārjanam. teba korin Hare Kṛṣṇa mantra yi, gbogbo awon nka idoti wanyi towa ninu okan wa, nitori awon idoti ile aye yi, gbogbo e loma kuro. Oti funwa l'apeere wipe okan wa dabi digi. T'eruko ba po lori digi, eyan o le ri oju ara re ninu digi na. Nitorina, agbudo nu dada. Beena ninu ile aye tawa yi, okan wa ti kunfun eruku, toti kojo nitori asepo wa pelu iseda aye yi lati aimoye igba seyin. Beena taba korin Hare Krsna mantra yi, eruku yi ma jade. tio ba tie je lesekese, o ma bere sini kuro. lesekese ti gbogbo eruku digi okan wa batan, lesekese leyan ma ri oju re na, nkan to je. Idanimo re gidi nitumo oju yi. Teyan ban korin Hare Kṛṣṇa mantra, oma yewipe ara re koloje. Asise wa niyen. Asise wa nitumo eruku yi, pe awa ti gba ara tab'okan bi emi. Ni otooro ara wa ko laje tab'okan wa. Emi ni wa. Lesekese taba mowipe ara wa ko laje, lesekese bhava-mahā-dāvāgni-nirvāpaṇam. Ina ile aye yi ton jo, tabi ina isoro aye yi, lesekese loma paare. Koni si isoro mo. Ahaṁ brahmāsmi. Bonse salaaye ninu Bhagavad-gītā, brahma-bhūtaḥ prasannātmā. Lesekese teyan ba ni oye nipa idanimo re to daju bi emi, inu re ma dun. Inu wa o dun. Nitori asepo pelu ile aye yi, nigbogbo igba lawa ni isoro. Tawa ban korin Hare Krsna mantra, lesekese lama wa sori ipo idunnu ninu aye wa. Bhava-mahā-dāvāgni-nirvāpaṇam. nkan ton pe ni ominiran leleyi. Teyan ba ni idunnu, tio ni isoro kankan, ipo yi ni ominiran nitoripe gbogbo eda, idunnu ni iwa ti emi gbogbo wa. Gbogbo itiraka aye yi niwipe on wa idunnu laye re, sugbon kole ri. Nitorina, l'awa o se ni aseyori ninu aanfani lati ni idunnu. Sugbon a leni ilosiwaju tawa ban korin Hare Krsna mantra yi. Ibajade ohun mimo yi leleyi. lehin igbala yi, idunnu aye yi ma dinku. Idunnu teyin fe gbadun ma dinku. E mu fun apeere, ji jeun. tawa ba fe je ounje to da, lehi igba taba ti jeun die, koni wu wa je mo. Itumo re niwipe ninu aye yi, eyikeyi idunnu taba ni, oma dinku. Sugbon idunnu mimo, Oluwa Caitanya sowipe ānandāmbudhi-vardhanam, bi omi okun ni idunnu mimo yi je. Sugbon ninu ile aye yi, ati ni irisi pe omi okun o le kun. Omi okun o le koja iye toje. Sugbon omi okun mimo le kun. Ānandāmbudhi-vardhanam. Śreyaḥ-kairava-candrikā-vitaraṇam. Bawo losele je? O ti funwa ni apeere osupa, ti osupa ban jade. gege bi osupa lati ojo osupa tuntun, lojo kini dabi ila kekere to te. lojo keji, lojo keta asi tobisi, die die loma tobi si. gege na, idunnu ile aye mimo yi ma kun si gege bi osupa b'ojo sen lo, titi a fi de ojo t'osupa ba kun, beeni. Beena ceto-darpaṇa-mārjanam bhava-mahā-dāvāgni-nirvāpaṇam, śreyaḥ-kairava-candrikā-vitaraṇam vidyā-vadhū-jīvanam. Lehin na ile aye wa ma kun fun imoye nitoripe itumo aye mimo ni aye tayeraye, tokunfun idunnu, ati imoye. Ti imoye wa ba posi, idunnu wa na ma po. Śreyaḥ-kairava-candrikā-vitaraṇaṁ vidyā-vadhū-jīvanam, ānandāmbudhi-vardhanaṁ. Gege bi omi okun loje, sugbon asi po si. Ānandāmbudhi-vardhanaṁ, sarvātma-snapanaṁ. O si da tojepe, teyan ba ti wa lori ipo yi, eyan ma bere sini ronu wipe " Nisin moti ni itelorun." Sarvātma-snapanaṁ. Gege b'eyan toba ti we tan, lesekese loma sooji. Beena, idunnu lat'ojo kan si keji ma je ka ni itelorun.