YO/Prabhupada 0403 - The Purport to Vibhavari Sesa



Purport to Vibhavari Sesa

Nigbati Rāma, farahan bi Oluwa Rāmacandra, osi fiku pa Ravana,rāvāṇāntakara. Mākhana-taskara, ni ilu Vrndavana wan si mo bi ole bota. Ni asiko to kere, o si man ji bota lati ikoko awon gopi. Nkan tosi feran ju lati se niyen, nitorina lonsen pe ni mākhana-taskara, mākhanacora. Gopī-jana-vastra-hari, osi ji aso awon gopi, nigbaton we. awon oro t'okan t'okan leleyi. Niotoor awon gopi si feran Krsna. Wansi gbadura si Kātyāyani-devī, orisa Kātyāyani, nitoripe gbogbo awon omo-obirin pelu ojo ori bi re, si fe koje oko wan. Beena, Ojo ori kanna ni Krsna je pelu won, bawo losele je oko fun gbogbo awon gopi? Sugbon osi gba. Nitoripe awon gopi sife di iyawo si Krsna, Nitorina ni Krsna se gba oro ton fi loo. lati le fun won ni ore-ofe re, osi ji awon aso won, nitoripe oko le ji aso iyawo re, Koselomi tole fowokan. Nitorina lose sele, sugbon awon eyan o mo. Nitorina agbodo gbo Krsna-lila lati awon eda ton je pipe, tabi awa ogbodo gbo awon apa wanyi. Bibeko koni ye wa idi funwipe Krsna se ji awon aso na, kasi bere sini rowipe o feran obirin, beeko. Olorun loje. Oun lon piyesi gbogbo ife-okan awon olufokansi. Beena Krsna o ni ise kankan lati lo ri awon gopi ni ihoho, sugbon ntoripe won fe di iyawo re, beena osi piyesi ife okan won. Ebun, " Beeni, Oko nimo je si yin, moti mu aso re. nisin e gba aso yin ke ma losile. " Nitorina lonsen'pe ni gopī-jana-vastra-hari. Brajera rākhāla, gopa-vṛnda-pāla, citta-hārī vaṁśī-dhārī. Brajera-rākhāla, oluso maalu ni ilu Vrndavana, ati gopa-vṛnda-pāla, Ohun ife okan re ni bosele fun awon oluso maalu nitelorun, ati baba re, pelu arakurin baba re na, oluso maalu ni gbogbo won, lati jeki inu won dun. Beena won pe ni gopa-vṛnda-pāla. Citta-hārī vaṁśī-dhārī, nigbato ba fon fere na, asi je ki inu awo eyan dun, citta-hārī. O si ji okan gbogbo awon eyan. Yogīndra-vandana, botilejepe Krsna sin sere bi oluso maalu ni ilu Vrndavana, gege bi awon omo abule ton sere pelu awon ore re, sugbon, yogīndra-vandana loje. Alagbara idan nitumo Yogīndra. Dhyānāvasthita-tad-gatena manasā paśyanti yaṁ yoginaḥ (SB 12.13.1) yoginaḥ, awon ton sasaro, kilon waadi? Kṛṣṇa yi> Won waadi Kṛṣṇa. beena afi tonba le gbokan le Kṛṣṇa, ofin yoga yi ati agbara idan yi a poo won lori. Yoginām api sarveṣāṁ mad-gata-antara (BG 6.47). Yogi, t'ipo kini gbodo fi Krsna sinu okan re. Pipe yoga niyen. Nitorina lonsen pe ni yogīndra-vandana, śrī-nanda-nandana, braja-jana-bhaya-hārī. Botilejepe awon alagbara idan sin gbadura si, sugbon osi n'gbe ni ilu Vṛndāvana bi omo-okurin Nanda Maharaja, awon omo-ilu Vrndavana, si ni ifokonbale labe idaabo Krsna. Navīna nīrada, rūpa manohara, mohana-vaṁśī-vihārī. Navīna nīrada, sanmo nitumo nīrada, kikodi ara re si jo sanmo tuntun to sese jade. Sanmo tuntun, dudu, rūpa. Sugbon osi lewa gan. awon o si rowipe dudu lewa ninu aye yi, sugbon nitoripe ara re je pipe, botilejepe dudu, osi lewa si gbogob eyan. Rūpa manohara. Mohana-vaṁśī-vihārī, toba si duro pelu fere re, botilejepe o dudu, sugbon gbogbo eyan si nife si. Yaśodā-nandana, kaṁsa-nisūdana, awon eyan si feran bi omo iya Yasoda, Oun ni apani Kamsa, ati nikuñja-rāsa-vilāsī, osi n'jo, ijo rasa ninu nikunja, vaṁśī-vaṭa, nikuñja. Kadamba-kānana, rāsa-parāyaṇa, awon igi kadamba si po. ododo ton hu ni ilu Vrndavana ni Kadamba, o si lewa gan, oorun re si dara. Beena Kadamba-kānana, osin jo ijo rasa re labe igi kadamba. Ānanda-vardhana prema-niketana, phula-śara-yojaka kāma. osi fe ki ifekufe okan awon gopi si po si, bayi inu wan asi dunsi. Ānanda-vardhana prema-niketana, nitoripe oun ni ile gbogbo igbadun. Awon gopi si man wa lati gbadun nitoripe oun ni ile gbogbo igbadun. gege bi awa sen losi odo lati pon omi. Beena, t'awa bafe ni igbadun pipe, agbodo losi enito ni gbadun pipe, Krsna. Ānanda-vardhana, igbadun yi ma posi. Igbadun aye yi ma din ku. Kosi besele gbadun re fun igba to po, o ma dinku, sugbon igbadun mimo, teyin ba ni igbadun mimo lati Krsna, nigbogbo igba loma po si. Igbadun yin ma posi, eyin na ma gbadun si. Beyin sen gbadun si, beena ni igbadun na sen posi. Kosi ipaari. Phula-śara-yojaka kāma, oun ni orisa ife to gaju. Orisa ife lon fi ife sinu okan awon eyan ninu aye yi. Beena ninu odo metalokan, oun ni orisa ife to gaju. Oun lon jeki ife awon gopi posi. Won si gbadun bayi, kosejo pe ife na ti dinku. Ife won sin posi, Krsna sin fun won si laisi nkan aye yi nibi, Won si n'jo, otan. Gopāṅganā-gaṇa, citta-vinodana, samasta-guṇa-gaṇa-dhāma. Won si mo fun gopāṅganā. Onijo vraja-dharma nitumo Gopāṅganā. Gopāṅgaṇa-gaṇa, citta-vinodana, won ronu nipa Krsna nikan. Won si feran Krsna gan, kosi bonsele fi Krsna sile ninu okan won, citta-vinodana, osi mu okan awon gopi, citta-vinodana. Samasta-guṇa-gaṇa-dhāma, Oun loni gbogbo amuye to gaju. Yamunā-jīvana, keli-parāyaṇa, mānasa-candra-cakora. Mānasa-candra-cakora, oni eye kan tonpe ni cakora. O man wo ina osupa. Beena, Oun ni osupa laarin awon gopi, wan si toju e. Oun l'emi odo Yamuna, nitoripe osi man sere gan ninu odo Yamuna. Nāma-sudhā-rasa, gāo kṛṣṇa-yaśa, rākho vacana. Bhaktivinoda Ṭhākura sin bere lowo gbogbo eyan, "Nisin e korin awon oruko orisiri Olorun yi, kesi ni gbala." Rākho vacana mano: "Okan mi, daakun jerisi oro yi. Ma yipada, ma korin oruko mimo Krsna yi."