YO/Prabhupada 0478 - Here is a Television Box Within Your Heart



Lecture -- Seattle, October 18, 1968

Prabhupāda: Govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi.

Ajo: Govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi.

Prabhupāda: Beena asin gbadura si Govindam, Eledumare, eda t'alakoko. beena ohun yi, govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi, sin lo s'odo re. O si le gbo. Eyin o le mo nkan ton gbo. See so? Rara. Nipati, ninu asiko sayensi tawa yi, pelu awon aworan, awon iroyin redio, ton wa lati aimoye mili, eyin si le gbo Kilode ti Krsna o le gbo adura teyin gba? Bawo lese le so? Kose ni tole jiyan. Beena, premāñjana-cchurita-bhakti-vilocanena santaḥ sadaiva hṛdayeṣu vilokayanti (Bs. 5.38). gege b'eyin sen wo aworan lati aimoye maili, tab'ohun redio, beena teba si mura, eyin na le ri Govinda ni gbogbo gba. Kole rara. Wanti salaaye ninu Brahma-saṁhitā, premāñjana-cchurita-bhakti-vilocanena. Beena egbodo mura oju yin, pel'okan yin na. telefisonu wa ninu okan yin. Ipo to gaju yoga niyen. Kon sepe eyin gbodo ra telefisonu. O wa nbe, Oluwa na sin wan'be Ele ri, ele gbo, ele ba soro, sugbon afi teyin bani ero yi. E tunse, otan. Ona lati tunse ni imoye Krsna yi. Bbeko gbogbo nkan lo wa, eyin sini ero to daju ninu ara yin. teyin ba fe tunse, egbodo wa eyan to mo se, beena eyin gbodo gba iranlowo lowo eni to mo. lehin na ema riwipe, ero yin sise. Kole lati mo. Koseni tole sowipe kose se. Ninu sastra awa ti gbo wipe. Sādhu śāstra, guru vākya, tinete kariya aikya. Ale ni imoye eto mimo yi lori ona meta. Sadhu. Awon eda mimo nitumo Sadhu, awon eda ton ti ni imo ara won, sadhu. ati sastra. Iwe mimo nitumo Sastra, awon iwe mimo, Veda. Sādhu, śāstra, ati guru, akeko mimo. Ona meta na leleyi. teyin ba fi oko yin lori ila meta wanyi, Oko yin ma los'odod Krsna. Tinete kariyā aikya. Gege lori ila reluwe tonba wa dada, oko reluwe na ma koja dada losibi ton lo. Nibi na, awon ila meta lowa - sādhu, śāstra, guru: awon eyan mimo, gbigba awon eda mimo, tabi oluko mimo, ati igbagbo ninu awon iwe mimo. Otan. Lehin na oko yi ma lo dad, laisi isoro kankan. Sādhu śāstra guru vākya, tinete kariya aikya.

Beena nibi ninu Bhagavad-gita, Eledumare ti salaaye nipa ara re, Krsna. Beena teyin ba sowipe, "Bawo nimose femo pe Krsna lo sobe? Enikan lo f'oruko Krsna fi ko pe "Krsna sowipe" Rara. Ila awon akeko s'oluko leleyi. Ema ri ninu iwe na, Bhagavad-gita, Nkan ti Krsna so ati bi Arjuna se ni oye re. Wanti salaaye awon nkan wanyi. ati sadhu, awon eda mimo, lati ibere Vyāsadeva, Nārada, titi de awon ācāryas, Rāmānujācārya, Madhvācārya, Viṣṇu Svāmī, ati eyito keyin ju, Oluwa Caitanya, bayi na, wan se gba: " Beeni, Krsna lo so." Beena ijerisi to wa niyen, Ti awon eda mimo ti gba.. Wan o paaro. Awon olori yi ti gba pe " Beeni, Nkan ton pe ni sadhu niyen. nitoripe awon eda mimo, sadhu yi ti gba, nitorina lose je iwe mimo. Nkan ogbon ori leleyi. Ti awon adajo ba gba iwe kan, oye ko ye wape iwe ofin niyen je. Eyin o le sowipe "bawo nimo sefe gba ofin na?" Ijerisi towa niwipe awon adajo na ti gba. Ti awon ologun ba gba, nkan to daju ni fun awon ologun niyen. Beena, ti awon eda mimo ba gba Bhagavad-gita bi iwe mimo, eyin o le jiyan. Sādhu śāstra: awon eda mimo ati iwe mimo, nkan meji, ati oluko mimo, meta, awon ila meta wanyi, Sadhu loma jerisi awon iwe mimo ati oluko mimo na ma gba awon iwe mimo. Ilana to rorun. Kosi ijiyan kankan. Nkan ton ko sinu awon iwe mimo yi, awon eda mimo ti gba, nkan to si ko ninu awon iwe mimo yi, oluko mimo ma salaaye boseje, Otan. Ona to daju ni iwe mimo. Gege bi awon adajo ati elejo - iwe ofin loje. Beena, fun oluko, iwe mimo... Itumo eda mimo yi leyan tole jerisi awon itosona Veda. itumo awon iwe mimo ni nkan ti awon eda mimo ti jerisi. ati oluko mimo ni eyan ton tele awon iwe mimo. beena awon nkan ton jegbe si nkankana egbe lon je ai ara won. Otooro to wa niyen. Teyin ba ni ogorun dollar, at'okurin toni ogorun dollar na, temi na ba ni ogorun dollar na, egbe ni gbogbo wa. Beena, sādhu śāstra guru vākya, ti awon ila meta wanyi ban so nkankanna, aye wa ma ni aseyori