YO/Prabhupada 0613 - The Six Things we have to take Particular Care
Lecture on BG 2.13-17 -- Los Angeles, November 29, 1968
Nandarāṇī: ti awon onile ba'n gbiyanu lati toju awon omo won ninu imoye Krsna, ise imi si Krsna niyen. Soye kon sise fun, ise bi onje sise fun, nkan to wa fun Krsna nikan, tabi kon fokansi itoju awon omo won nile, se ise bayi to? Se ise too to leleyi?
Prabhupada: Beeni, Nkan towa niwipe agbodo ni imoye Krsna yi. Gege bi ina monamona. Teyin ba mu okun ina kan fi kan imi, teyin ba fi won kan ara won, ina monamona ma tan. Beena ti imoye Krsna wa ba sopo dada, beena kosejo boya o wa dada tabi ko wa dada. Nitoripe ninu agbaye to w ani pipe kosiyato kankan. Lesekese teyin bafi kan sinu ina monamona...nkan ton pe ni ipinle awon akeeko niyen. Nitoripe latikan sikejo ni asopo yi tin wa, tawa ba fowokan Oluko tosi ni iru asopo bayi, beena asopo monamona yi wa nibe. Kosejo pe o wa dada tabi beeko. Evaṁ paramparā-prāptam imaṁ rājarṣayo viduḥ (BG 4.2). O kan ye ka wo boya ina monamona yi ni asopo to daju. Ti asopo yi ba wa dada, o daju pe ina monamona yi ma tan. Beena ninu ipo aye wa awon isoro to po gan wa, sugbon bi mosen sofun yin na pe, ema kanju lati ni awon ijeere to wa nibe lesekese. Oye ka tele. Oye ka tele. Tat-tat-karma-pravartanāt. Ilana ti Rupa-Gosvami fun wa niyen. Awon nkan mefa toye ka mu ni pataki, ati awon nkan mefa toye ka paati lati ni imoye Krsna.
Beena utsāhād dhairyān niścayāt. Ofin t'alakoko niwipe eyan gbodo gbiyanju gan. O ye ko mo pe Krsna ti sowipe, na me bhaktaḥ praṇaśyati, " Awon olufokansi mi o le ni aimaseyori." Beena " Ejekin di olufokansi ti Krsna to daju. Mo gbodo di olufokansi Krsna to daju gan. " Nkan ton pe ni igbiyanju niyen. Lehin na dhairyāt. "Moti di olufokansi Krsna, sugbon inu mi o du, kilode?" Beena nitoripe eyin tidi olufokansi, igbiyanju yi ma wa nibe, sugbon oye ke ni'suru na. Ati niścayāt. Itumo Niścayāt niwipe oye ko dayinloju " Oh Krsna ti sowipe awon olufokansi re o le se aimaseyori, beena emi na o ni se aimaseyori, botilejepe mi o ri nisin. Eje kin sise mi." Utsāhād dhairyān niścayāt tat-tat-karma-pravartanāt. Sugbon egbodo sise yin bos ye. Sato vrtteh. Eyin o gbodo huwa etan. Iwa to daju, lai tan awon eyan je nitumo Sato vṛtteḥ. Sato vṛtteḥ, ati sādhu-saṅge, ati ninu akojo awon olufokansi. Beena eyan gbodo gbiyanju, o gbodo ni suru, ogbodo da loju nkan tonse, eyan gbodo sise re, eyan gbodo ni asepo pelu awon olufokansi to ku, ati wipe eyan o gbodo huwa etan. Awon nkan mefa. ti awon nkan mefa wanyi ba wa, o daju pe eyin ma ni ilosiwaju.