YO/Prabhupada 1080 - Isonisoki ti Bhagavad-gita - Oluwa ni Krishna. Oluwa fun awon egbe eyan kan soso ko ni Krishna je
660219-20 - Lecture BG Introduction - New York
Oluwa ti so dada ninu Bhagavad-gita l'apa to keyin, ahaṁ tvāṁ sarva-pāpebhyo mokṣayiṣyāmi mā śucaḥ (BG 18.66). Oluwa ma gba ojuse lori etoo na. Teyan ba teriba s'Oluwa, Oluwa ma gba sori ara re lati fun nigbala, lati yasi mimo lati gbogbo ibajade ese toti se.
- mala-nirmocanaṁ puṁsāṁ
- jala-snānaṁ dine dine
- sakṛd gītāmṛta-snānam
- saṁsāra-mala-nāśanam
Eyan le fo ara re lojojumo toba'n we pel'omi, sugbon eni toba we ninu omi mimo Ganga ti Bhagavad-gita, gbogbo idoti ninu ile aye re ma tan lesekese.
- gītā su-gītā kartavyā
- kim anyaiḥ śāstra-vistaraiḥ
- yā svayaṁ padmanābhasya
- mukha-padmād viniḥsṛtā
Nitoripe Eledumare fuin ara re lo soroto wa ninu Bhagavad-gita, Awon eyan le ma ka awon iwe mimo iyoku lati Veda. Tonba fetisile lori awon eto Bhagavad-gita lojojumo, gītā su-gītā kartavyā... Dandan ni ki awon eyan gba ona yi Gītā su-gītā kartavyā kim anyaiḥ śāstra-vistaraiḥ. Nitoripe lasiko tawayi, itiju awon eyan po gan, beena o lee gan lati mu okan won wa aori iwe mimo Veda. Iwe mimo kan soso yi le sise na nitoripe oun ni koko oro gbogbo awon iwe Veda, nipataki nitoripe Eledumare fun ara re lo so.
- bhāratāmṛta-sarvasvaṁ
- viṣṇu-vaktrād viniḥsṛtam
- gītā-gaṅgodakaṁ pītvā
- punar janma na vidyate
Bonse sowipe anikeni toba m'omi Ganga, om ani igbala, kama wa soro nipa Bhagavad-gita? Bhagavad-gītā ni adun ninu gbogbo Mahabharata, Visnu lo de salaaye re. Oluwa Krsna ni Visnu t'alakoko. Viṣṇu-vaktrād viniḥsṛtam. latenu Eledumare loti jade. Ati gaṅgodakaṁ, Ganga lat'ese Oluwa loti jade, Bhagavad-gita de jade latenu Oluwa na. Looto kosi'yato laarin enu at'ese Oluwa. Beena, o le yewa wipe Bhagavad-gita se pataki ju omi Ganga lo.
- sarvopaniṣado gāvo
- dogdhā gopāla-nandana
- pārtho vatsaḥ su-dhīr bhoktā
- dugdhaṁ gītāmṛtaṁ mahat
Bi maalu ni Gitopanisad se ri, Oluso maalu l'Oluwa si je, osi n' fa wara lati awon maalu. Sarvopaniṣado. Koko oro gbogbo Upanisada loje, wansi fi we maalu. Oluwa toje oluso maalu sin fa wara lat'ara maalu. pārtho vatsaḥ. Arjuna si dabi omo-maalu. su-dhīr bhoktā. Awon alakowe ati awon olufokansi awon loye kan mu wara yi. Su-dhīr bhoktā dugdhaṁ gītāmṛtaṁ mahat. adun yi, wara Bhagavad-gita, fun awon olufokansi ton keeko lowa fun.
- ekaṁ śāstraṁ devakī-putra-gītam
- eko devo devakī-putra ev
- eko mantras tasya nāmāni yāni
- karmāpy ekaṁ tasya devasya sevā
Nisin, oye ki gbogbo aye keeko lati Bhagavad-gita, ikeeko. Evaṁ śāstraṁ devakī-putra-gītam. Iwe mimo kan soso lowa, iwe mimo kan soso fun gbogbo agbaye, fun awon eyan aye yi, Bhagavad-gita ni iwe mimo na. Devo devakī-putra eva. Oluwa kan soso lowa, Sri Krsna de loje. eko mantras tasya nāmāni. orin adura kan soso, tabi adura kan, lati p'oruko re, Hare Kṛṣṇa Hare Kṛṣṇa Kṛṣṇa Kṛṣṇa Hare Hare, Hare Rāma Hare Rāma Rāma Rāma Hare Hare. Eko mantras tasya nāmāni yāni karmāpy ekaṁ tasya devasya sevā. Ise kan soso lowa lati sise fun Eledumare. Teyan ba keeko Bhagavad-gita, o ma jeko awon eyan gbiyanju gan lati ni esin kan, Oluwa kan, iwe mimo kan, ise kan tabi ise aye kan. Wan ti salaaye ninu Bhagavad-gita. Pe Olorun kan soso t owa ni Krsna. Krsna o kin s'Olorun awon egbe kan. Krsna, lat'oruko Krsna... Base salaaye tele,Idunnu to gaju nitumo Krsna.