YO/Prabhupada 0007 - Itoju Krishna ma wa

Revision as of 18:41, 14 October 2018 by Vanibot (talk | contribs) (Vanibot #0023: VideoLocalizer - changed YouTube player to show hard-coded subtitles version)
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Lecture on SB 1.5.22 -- Vrndavana, August 3, 1974

Brahmānanda: Brahmana, ojise Oluwa, ko gbodo gba ise owo osu.

Prabhupāda: Rara. Bi o ti lè ma fi ebi ku. Ko ni gba isè kisè. Iyen ni Ojise Oluwa, brāhmaṇa Bakanna ni Kṣatriya, ati pelu vaisya Sudra nikan Vaisya yi o wa ise-aje miran. Oun o wa ise-aje miran Itan kan wa ni pa eyi ti o damoran Okunrin kan wa ti oruko rè njè, Ogbeni Nandi, lojo kan anna ni ilu Kalakuta, O lo ri awon ore rè kan lati bi won wipe " Si ti e ba le fun mi ni oye kan, mo le bèrè ajé. O so wipe, "Alajé ni yin? A bi bèko.? "Bèèni" Ah, oun bééré owo lôwô mi? Owo wa ni ta. O le bééré wo" O ba ni wipe, "Emi o ri " "Iwô o ri? Ki ni ohun na?" "Eleyi, oku éku le leyi" "Oye ti o nwa lati fi bèrè oja ni yen" E o ri nkan.

Ni igba ta anwi yi iyan nmu ni Kalakuta, iyan nbè ni lu lasiko naa. Nitorina awon ijoba municipal wa polongo wipe eni keni ti o ba le mu oku eku wa si ibisè won yi o gba affa meji Bi ogbeni se mu oku eku lô si ôdô awon oni municipal ni yen Won si fun ni affa meji. Bèèni o ba lô ra eso awusa ti o ti njèra pèlu affa meji rè, bè lo se fô won mô ti o si tun won ta fun affa mèrin bi marun. Ni pa ona yi, ni atunwa, atunwa, atunwa, bèè ni arakunrin wa se eni ôrô ati olowo. Omo ar ile won kan jè ikan ninu awon omo èlèsin ijô wa. Ibile Nandi. Titi dô jô oni, awon idile Nandi yi nfi ounjè fun ôgôrun mèrin si ôgôrun marun eniyan lo jo jumô. Idile nla atôbatèlè ni won jè. Ati wi pe ofin idile won ni pe kia kia ti won ba ti bi ômô okunrin tabi obinrin, èsè kan naa ni won a fi egberun rupees sinu banki fun. bee na lojo igbeyawo re, won a si yanju egberun marun rupees naa pelu ere ori re fun. Bi beko, ko tun si ipin si wewe ipinle bukia re. ati wipe gbogbo awon ti won jo ngbe po ni won ri je, ni won si nri bi sun. Eyi ni ti won... Sugbon atilewa na, nkan ti mo fe wi ni pe, eni ti o da idile yi sile, Nandi, o bere ero aje ti re pelu oku eku pata pata.

Eyi ni ododo oro, ododo oro, pe ti eniyan ba fe gbe ni ominira re... Mo ri eyi ni Kalakuta. Paapa awon onisowo ti won talika, to ju bati mo won a gbe gbegiri, ḍāl Aapo ḍāl, won a si lo lati ojule kan si imiran, Ḍāl, je nkan ti o wa ni lilo kaa ki ri. Nitori eyi, to ju ba ti mo a se oro-aje ḍāl, ti o ba si di irole a gbe gallon kerosin. Nitori pe ni irole, oni kalu ku a ni lo re. Titi ojo oni a si le ri ni ile India, won... Ko si eni ti oun wa ise ati se ise osu. Bintin, nkan ki nkan to ba ni, a ma ta oja epaa tabi awusa. O ni nkan to nse. Bo ti wu kawi, Olorun nse eto fun eni kokan wa. Asise ni lati ro wipe "Arakunri yi ni onse eto aye mi.'" Rara. Śāstra, iwe mimo so wipe: eko yo bahūnāṁ vidadhāti kāmān. Eyi ni igbekele Oluwa, pe Olorun ti fun mi ni emi, Oun ni o ran mi wa. Nitorina, Oun yi o si ba mi gbe bukata mi. Nitorina gegebi agbara mi, je ki nwa nkan se, ati lati idi eyi, ikoso Olorun yi o si wa.