YO/Prabhupada 0068 - Olukaluku gbodo se ise
[[Vaniquotes:Anyone who has got this material body, he has to work. Everyone has to work |Original Vaniquotes page in English]]
Lecture on SB 6.1.45 -- Laguna Beach, July 26, 1975
Nitai: "Ni le aye yi, ni iwon si iwon orisirisi ise olukaluku, boya o je nkan ti majemu tabi nkan ewo, bi won se ma ri laye miran na, eni kan na gege bi iwon-si-wonsi, oniruru nkan na, ere iwuwasi kadara re lati gbadun tabi lati jiya."
Prabhupāda:
- yena yāvān yathādharmo
- dharmo veha samīhitaḥ
- sa eva tat-phalaṁ bhuṅkte
- tathā tāvad amutra vai
- (SB 6.1.45)
Bee na ninu ori ese to koja a ti se alaye, dehavān na hy akarma-kṛt. Enikeni to ba ti gbe ara aye yi wo, gbodo se ise. Olukaluku gbodo se ise. Ninu ara emi na e gbodo se ise. Ninu ara aye yi na e gbodo se ise. Nitoripe ilana ti ise ni ti emi - emi ni okun ara - nitorina o laapon. Ara ti o wa laaye tumo si irin. Ise wa. Ko le joko lai ma ni nkan se. Won so ninu Bhagavad- Gita pe, "Iseju kan o gbodo koja lai ni nkan se. Iyen ni ami eda alaaye. Bee na ise sise yi nlo dede gegebi ara eni kokan. Aja nsare, eniyan na si nsare. Sugbon eniyan ro wipe oun laju pupo nitoripe o nsare lori oko. Awon mejeji nsare, sugbon eniyan ni iru ara kan to yato nipa ti o fi le se oko tabi keke , ti o si le fi sare O nro wipe "Mo nsare ni iyara to ga gan ju aja lo, nitorina mo je onilaju. Eyi ni ero okan ti ode oni. Ko le ye pe kini iyato to wa laarin si sare lori iyara adota maili tabi iyara maili marun tabi iyara egberun marun maili. Aaye na o lopin. Iyara eyikeyi ti e ba ri, o si wa laito. O wa laito.
Bee ni eyi ki ise ile-aye, ka ni "Nitoripe mo le sare yara ju aja lo, nitorina mo ti laju."
- panthās tu koṭi-śata-vatsara-sampragamyo
- vāyor athāpi manaso muni-puṅgavānāṁ
- so 'py asti yat-prapada-sīmny avicintya-tattve
- govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi
- (Bs. 5.34)
Iyara wa... Kini iyara wa fun? Nitoripe a fe lo si ibi kan, idi iyara re ni yen. Bee ni opin irinajo gan ni Govinda, Viishnu. Ati na te viduḥ svārtha-gatiṁ hi viṣṇu. Won nsare pelu iyara to yato, sugbon won o mo ibi ti o je ipin irinajo. Akewi nla kan ni orile ede wa, Rabindranath Tagore, o ko ohun kan - mo ka ohun na - nigba ti o wa ni London. Bee na ni orile ede yin, awon orile ede ilu oyinbo, awon oko ati ... won ma nsare pelu iyara to ga. Bee ni Rabindranath Tagore, o je akewi. O ba nro wipe "Orile ede awon Oyinbo yi kere gan, won si nsare pelu iyara to ga won ma lo subu sinu okun." O fiyesi bayi. Kilode ti won fi nsare yara yara? Bakanna, a nsare yara yara lati yori si orun apadi. Eyi ni ipo wa, nitoripe a o mo ibi ti o nse ipin irinajo. Ti mi o ba mo ipin irinajo ti mo si ngbiyanju lati wa oko mi pelu iyara pata pata, kini o ma yorisi? Opin re ma je ijamba nla. A gbodo mo idi re ti a se nsare. Gege bi odo ti o nsare ni iyara nla, ti o nsan, sugbon opin irinajo re ni okun. Nigbati odo ba kan okun, irinajo re ti dopin. Beena ni bakanna, a gbodo mo ibi ti onse opin irinajo. Opin irinajo ni Vishnu, Olorun. Awa je ti apa tese Olorun. A je... Ni ona kan tabi omiran, a ti subu si inu aye asan yi. Nitorina opin irinajo ile aye gbodo je lati pada si ile, lodo Baba wa loke. Iyen ni opin irinajo wa. Ko si opin irinajo meji. Bee na egbe ifokansin Olorun wa nko ni wipe "E fokan si opin igbesi aye yin." Ati pe kini igbesi aye eni? Lati pada sile, ni odo Baba loke. E ngba ona yi, ona idakeji, ti o nlo si agbegbe orun apadi. Iyen ki se opin irinajo yin. E wa gba ona yi, ti o pada si odo Oba loke ayeraye. Eyi ni ipolongo wa.