YO/Prabhupada 0067 - Awon Goswamis ma nsun fun wakati meji pere



Lecture on SB 1.16.26-30 -- Hawaii, January 23, 1974

Bee na iba ti egbe ifokansin Olorun se nlo siwaju, se nitori aanu iyanu ti Sri Chaitanya Mahaprabhu fun awon ti won ojiya talika ni igba ti Kali yi. Laijebe, lati di eni ti o nsokan Olorun ko se nkan ti o rorun rara. Nitorina awon ti won ni aye lati ti di eni ti nsokan Olorun nipa ti ore ofe Sri Chaitanya Mahaprabhu, won o gbodo pa aye na. Iyen a je pipa ara eni. E ma se subu. Ko soro rara. Nipa pipe Hare Krishna mantra nikan, ki se nigbogbo igba, wakati merin-le-logun, bo ti le je wipe Chaitanya Mahaprabhu fi se imoran, kīrtanīyaḥ sadā hariḥ (CC Adi 17.31), lati ma ke pe nigbogbo igba. Ilanna na ni yen. Sugbon a o le se yen nitoripe agbara ipa kali ti bo wa mole Nitorina bi o ti leri e se afa merin-dinlogun. E ma se laise, e ma se laise. Kini o soro nbe, afa merin-dinlogun? Bo ti le peju a gba yin ni wakati meji. E ni wakati merin-le-logun. Bi e ba fe sun, o dara , e sun, orun wakati mewa. Iyen ki se ohun ti a da nimoran. E ma se sun ju wakati mefa lo. Sugbon won fe sun. Won fe sun fun wakati merin-le-logun. Nkan ti won fe ni yen ni aye Kali. Sugbon, rara o. Nigba na e o si ma pa aye danu. A gbodo din awon ise yi ku, jije, sisun, bibaralo ati idabobo. Ni igbati ko ba si mo, iyen ni isepe.

Nitoripe awon nkan iwulo ti ara ni won yi. Jije , sisun, ibaralo, idabobo won je nkan iwulo ti ara. Sugbon emi ki se ara yi. Dehino 'smin yathā dehe kaumāram... (BG 2.13). Bee ni iriri yi ngba akoko kan. Sugbon nigbati a ba ndagbasoke ninu isokan Olorun, a gbodo mo ojuse wa . Sisun orun ti ko ju wakati mefa lo. O pe ju wakati mejo. O pe ju, fun awon ti won ko le se. Sugbon ki se wakati mewa, wakati mejila, wakati marun-din logun, rara. Ki wa ni iwulo ...? Enikan lo ri alagba olufokansin kan, o ba ri wipe alagba na si nsun ni ago mesan. O si je alagba olufokansin. Eh? A bi be ko? Bee na kini...? Iru olufokansin wo l'oun je? Olufokansin gbodo ji ni owuro kutu, ni bi ago merin. Titi ago marun, ko ti se ipari wiwe ati awon nkan miran. A si ma bere si ke pe Olorun ati awon... Eto wakati merin-le-logun gbodo wa nbe. Nitoina sisun o bo si. Awon Goswamis ma nsun fun wakati meji pere. Emi na si ma nkowe loru, mi o si nsun ju wakati meta lo. Sugbon nigba ko kan, mo tun le sun die. Ki se bi... Mi o farawe awon Goswamis. Iyen ko se se. Sugbon bi a ba se lagbara si, onikaluku gbodo yera fun. Kasi yera fun sisun pupo tumo si wipe ka jeun ni won ba, igba na ni a le yera fun. Jije, sisun. Leyin ounje, orun ni. Bee na ti a ba jeun pupo, nigba na sisun pupo. Ti a ba jeun ni won ba, a le din orun ku. Jije, sisun, ibaralo. Ti ibaralo a gbodo bila fun. Iyen je nkan ti a da lekun. Ere ife gbodo je iwon tu wonsi ni dede. Nitorina ni a se ni ipala yi, " Ko si iwa agbere" Ere ife, iyen a o so wipe, "Ma se" Enikeni le se. Nitorina ni ere ife tumo si aye abiyamo, ijolowo kekere. Ifayefun, "O dara gba iwe ifayefun yi." Sugbon ki se fun agbere. Nigba na iwo ko ni le se.

Bee na jije, sisun, ibaralo ati idabobo. Nipa ti idabobo, a nse idabobo ni ona pupo sugbon ogun si wa, ati laala ti idanida aye ... Orile ede yin nse idabobo dara dara, sugbon nsinyi ti ko si petrolu mo. E o le se idabobo mo. Bakanna, gbogbo nkan ni o le di rira ni gba ki igba. Bee ni ki e gboju le Olorun fun idabobo. Avaśya rakṣibe kṛṣṇa. Iyen ni iforibale. Iforibale, tumo si.... Olorun so wipe "Jowo ara re fun Mi," sarva-dharmān parityajya (BG 18.66). E je ki a ni igbagbo yi, wipe " Olorun nbi wa lere ki a jowo ara wa. Je ki njowo ara mi. Oun yi o si dabobo mi ninu ewu Iyen ni a npe ni iforibale.