YO/Prabhupada 0001 - Ki egbe wa fe s'egbe-gberun lona mewa
Lecture on CC Adi-lila 1.13 -- Mayapur, April 6, 1975
Chaitanya Mahaprabhu so fun gbogbo awon Asaju/Acaryas: Nityananda Prabhu, Avaita Prabhu, Srivas ati gbogbo awon omo leyin won pe gbogbo won ni won se iranse akede fun Sri Chaitanya Mahaprabhu Nitori naa e gbinyanju lati téle ilana awon asaju Nigba na ni igbesi aye yin o se aseyori. Ati lati di Asaju ko tile soro rara. Ni akoko lati di olufookansin tootô fun Asaju ré, téle ilana ré gidi gan O ni lati gbiyanju lati té é lôrun, ki o si se ijéri imôlé Krishna O pari. Ko soro rara. Gbiyanju lati téle ilana Olukô Imôlé, Guru Maharaja, ré, ki o si fi imole Krishna mon kari ayè. Eyi ni asé Oluwa Chaitanya.
- āmāra ajñāya guru hañā tāra' ei deśa
- yāre dekha tāre kaha 'kṛṣṇa'-upadeśa
- (CC Madhya 7.128)
"Ni pa titélè asé mi, iwo na a di olukô, guru" Ti a ba si télè ilana akose awon asaju pelu otitô ati ododo Ti asi gbiyanju lati jire imo Olorun, Krishna Yāre dekha tāre kaha 'kṛṣṇa'-upadeśa (CC Madhya 7.128). Ona meji ni Krishna-upadesa Upadesa tumo si ilana Ilana lati ôdô Krishna wa, ohun na ni Krishna upadesa ati ilana ti a gba nipa Krishna, eyi naa ni Krishna-upadesa Kṛṣṇasya upadeśa iti kṛṣṇa upadeśa. Samāsa, śāsti-tat-puruṣa-samāsa. Ati Kṛṣṇa viṣayā upadeśa, eyi na ni se Kṛṣṇa upadeśa. Bāhu-vrīhi-samāsa. Eyi ni ona lati se atupale ilana ede lilo Sanskrit ati itumô ré Nitori na Krishna upadesa ni (iwe mimo) Bhagavad-gita Oluwa fun ra ré ni oun fun wa ni ilana Eni ti oun se ihinrere Krishna-upadesa, gbôdô se atunwi oun ti Krishna ba wi, ni igba naa ni o di Asaju tabi Olukoni. Ko soro rara. Gbogbo ré a ti kô si lé A gbô dô se atunwi bi èyè awoko Bi ti èyè awoko gan-gan kô. Eyè awoko o mon itumo oun ti ohun sô, o kan un se atunwi lasan ni Sugbon eyin ni lati ni oye itumo yi bakannaa Bi beko bawo ni iwo o se se alaye? Nitori naa a fé se ihinrere imolé Olorun, Krishna Nibayi, e mura si lé lati se atunwi awon ilana Krishna dara dara, laini asise tabi abuku ninu Nigba naa, ni ôjô ôla... Ka gba wipe é ni égbaarun l'oni A so di egberun lona ogorun Eyi ni a fé. Leyin eyi egberun lona egberun, ati egbe- gberun lona mewa.
Awon Omo Ijô: Ogoo ni fun Oluwa! Ogoo!
Prabhupāda: Nipase eyi, ki yi osi owon awon asaju awon eniyan yio ni oye imôlé Olôrun, Krishna ni irôwô rôsè Nitori naa è feyi seto E ma se igberaga lori asan E téle ilana Asaju Ki é si tu ara yin di mimô, dagbasoke. Nigbayi a ti worun lati gbogun le Esu Beeni. Awon Asaju ti gbogun le Esu