YO/Prabhupada 0010 - Ema farawe Krishna



Lecture on SB 7.9.9 -- Mayapur, February 16, 1976

Krishna... Awon egberun merin di logun aya, bawo ni won se di awon iyawo? E mon itan naa, awon opolopo arewa, egberun merin dilogun arewa, A ni nkan ti mo fe wi, ni pe, awon omo oba ti awon elesu, awon asura, ji gbe. Kini oruko elesu eda yi? Bhaumāsura, rara? Bee ni. Won wa ke pe Olorun wipe " A njiya, jaguda yi ji wa gbe. Jowo gba wa la." Bee ni Olorun, Krishna, se wa lati tu won sile, ti o si pa Bhaumasura naa, ati bi won se tu gbogbo awon omo obinrin na sile. Sugbon leyin ti won di ominira won tun duro si be. Ni igba na ni Krishna so fun won, "E le ma lo si ile obi yin" Won si dahun pe " Won ji wa gbe, nitori eyi a ko le ri oko fe mo" Ni orile ede India, asa yi si wa nbe. Ti obinrin, omoge, ko ba sun ile fun ojo kan tabi meji, Ko si eni ti o ma gba ni iyawo. Ko si eni ti o ma fi s'aya. Oti di eni ibaje. Asa yi si nlo titi di oni ni orile ede India Bee na ni won se ji won gbe fun opolopo ojo, tabi fun awon odun melo kan, Ni won ba fi oro won lo Krishna wipe " Awon obi wa na gan o ni gba wa pada, ati pe ko si eni ti o ma gba lati fe wa." Oro won si ye Krishna nipa wipe "Ipo won wa l'ewu. Bi o ti le je wipe won da won sile, won o ni ibi ti won ma lo" Ni igba na ni Krishna... nipa anu Re pupo, bhakta-vatsala. O bere lowo won, " Kini eyin fe nisinyi?" Wipe.. won so wipe " Gba owo mi. Bi bee ko, a ko ni ona miran lati duro si." Le se kan na ni Krishna wi pe: O dara be, e maa bo." Olorun ni yi. Ki nse wipe o fi awon egberun merin di logun aya won yi si nu aagbo-ile. Lese kan na ni O si ko egberun merin di logun aafin. Nitori wipe O ti gbaa gege bi aya, o gbodo se akoso re gege bi aya, Gege bi Iyalode, kii se wipe " Nitori wi pe won ko ni ona miran, nitorina ni won se wa si abo Mi. Mo le pa won mo bi mo se ri." Bee ko. Pelu gbogbo iyi gege bi iyalode, gegebi iyalode Krishna. Ati wipe le ekan si, O ro wipe "Awon egberun merin din logun aya... Ti mo ba da duro, bi eyo kan, ni bayi, awon iyawo Mi won ko le sumo Mi. Iko kan won lati duro egberun merin din logun ojo lati ri oko re. Rara O" O ba si ya ara re si ona egberun merin din logun Krishna. Olorun ni yi. Awon alailero, won da Krishna l'ebi pe o nse shi-na. Ko da bi ire. Iwo ko ti le le s'akoso iyawo kan, sugbon Oun se akoso egberun merin din logun awon iyawo ninu egberun merin din logun aafin. ati ni ona ara egberun merin din logun. Oni kalu ku won ni o ni itelorun. Olorun ni yi. A ni lati ni oye nkan ti a npe ni Olorun. E ma se farawe Olorun, Krishna. Ni alakoko e gbiyanju lati ni oye Olorun.