YO/Prabhupada 0011 - Eyan le gbadura si Krishna latinu Okan re



Lecture on BG 4.28 -- Bombay, April 17, 1974

Ninu Bhakti-rasāmṛta-sindhu, itan kan wa ni be... ki ti e se itan, ododo ni. Won se alaye nibe wipe alufa kan wa - ojise Oluwa ti o ni okiki ni. o fe se eto isin ti o da moran pupo, arcanā, ni nu ile ijosin, tempili. sugbon ko ni owo lati fi se eto nkan wonyi Sugbon ni ojo kan, o jo ko si inu ile eko iwe mimo Bhagavata o si gbo wi pe a le sin Olorun ni nu emi O ba gba aye yi nitori o ti nro iro yi lati igba kan bawo ni o se le sin Olorun pelu ayeye weriwe, sugbon ko lowo.

Nitori na, bi o se gbo oro yi, wipe a le sin olorun ni nu emi, bo ti se pari iwee re ninu odo Godavari, o ba joko si abe idi igi kan bèè lo ba bèrè si kô ipèpè to jowu nla, ninu ôkan rè, o si fi awon ilèkè se yaayi ipèpè naa ni bi ité Oluwa, o si bèrè si se asoju eto isin pelu omi odo Ganga, Yamuna, Godavari, Narmada ati Kaveri. Ni igba na ni o ba se ni arewa ibi itè Oluwa, lèyin na ni o wa se isin pèlu awon ododo ati ilèkè ododo.

Ni o ba si bèrè si wa ounjè, o sé paramānna, irèsi aladun. O wa fè tè wo, boya o gbo-na gan. Nitori wipe ni tutu ni won ma njè paramānna. Paramānna ki ise ounjè a jè gbigbona. Ni o ba ki ika rè bô irèesi aladun, ni o ba joo ni ika. Igba naa ni esin ninu emi rè wa si opin, nitori wipe ko si nkan kan. Ninu èmi rè nikan ni oti nsé gbogbo eto nkan won yi. Bee na... Sugbon o ri wipe ika rè joo na. Eyi wa daa loju ru.

Bayi ni, Nārāyaṇa lati Vaikuntha ilu Orun, bèrè si nrèrin. Laksimiji baa beéré, " Kilode ti èyin nrèrin? Ikan ninu awon omo èlèsin mi nse èsin mi ni bayi. Nitorina ran awon iranse mi lati lo gbe wa si Vaikuṇṭha."

Nitorina bhakti-yoga yi dara gan ni nitoripe, ti o ko ba tile ni nkan ini lati fun Oluwa ni esin to jooju o le se ninu emi-okan re. Eyi na si see se.