YO/Prabhupada 0017 - Agbara imôlé ati agbara okunkun
Lecture on Sri Isopanisad, Mantra 1 -- Los Angeles, May 2, 1970
Awon agabara meji ni won nse isé ni ile aye yi: agbara imôlé ati agbara okunkun. Agbara okunkun tumô si wipe, orisi méjô nkan ipilese aye. Bhūmir āpo 'nalo vāyuḥ: (BG 7.4) ilé, omi, ina, atégun, ofurufu, ôkan, iye ati éléda. Gbogbo nkan won yi je alailemi. Ni bakanna, o félé, félélé, félélé, o si ri gbigidi, gbigidi. Gege bi omi se félé ju ilé, inaa na si wa félélé ju omi, atégun na si wa félélé ju inaa, bééni ofurufu tabi oru, sè félé ju atégun. Bakanna, iyè se félé ju oru oju ôrun, tabi ôkan sè félé ju oru oju ôrun. Okan... Se e mo, Mo ti fun yin ni aimoye igba apeere yi: iyara si ti okan. Egbe egberun maili ninu iseju kan lo le lô. Bee na bi o ba se félé si, bee lo se lagbara Bakanna, ni igbeyin, igba ti e ba wa si ona ti emi, félé, ninu ibi ti gbogbo nkan ti njade, ah, iyen lagbara pupo. Iyen ni agbara imole. Eyi se fi fun ni ninu Bhagavada-Gita Kini agbara imole naa? Agbara imole naa ni nkan élémi yi. Apareyam itas tu viddhi me prakṛtiṁ parā (BG 7.5). Olorun so wipe, "Awon won yii ni agbara okunkun. Niwaju eyi ni agbara imolé" Apareyam. Aparā tumo si ohun ti o rélé ju. Apareyam. "Gbogbo awon nkan ipilese aye ti a s'alaaye, won je awon agbara ti won rélé ju.. Niwaju eyi ni agbara ti o ga ju, Arjuna Mi otito" Kini eleyi? Jīva-bhūta mahā-bāho: "Awon nkan elemi yi." Awon na je agbara. Awa nkan élémi, awa na jé alagbara, sugbon alagbara to ga. Bawo lo se ga? Nitoripe yayedaṁ dhāryate jagat (BG 7.5). Agbara to ga nse akoso agbara to rélé. Nkan alailémi ko ni agbara. Oko ofurufu nla, irin isé to dara, nfo lo ke lo ke, ti a se pélu awon nkan alailémi. Sugbon afi ti agbara émi, awako ofurufu, ba wa nbé, ko ni iwulo. Ko wu lo. Fun égbe gbérun ôdun ôkô ofurufu a duro si okun ofurufu. Ko le maa fo afi bi nkan alagbara émi kekere, awakô ofurufu naa, ba wa fôwô kan. Nitorina kini isoro lati ni imo Olôrun? Ikan ti o wa daju bayi, pe ti irin isé ganganran nla yi... Opôlôpô awon irin isé ganganran nla nla, won ko le gbesé lai se wipe a fi ôwô agbara émi kan. Eniyan tabi nkan élémi. Bawo lé se lè ro pe gbogbo agbara ilè ayè yi se nse sé lai ni éni ti oun dari ré ? Bawo lé sè lè ronu baayi? Iyen o lè sèe sè. Nitori idi eyi awon eniyan ti iye won ku die kato, won ko le ni iyè bi Oluwa Olôrun to ga ju lô se ndari agbara ile ayè yi.