YO/Prabhupada 0034 - Oni kalu ku ngba imoran lati odo alase



Lecture on BG 7.1 -- Durban, October 9, 1975

Ori iwe Keje, "Imo eyi ti O ga ju lo Nkan meji lowa, eyi ti o ga ju lo ati nkan ti a fiwe. Aye a fi we ra ni yi. Ni ibi a ko le ni iye nkan a fi ti a ba fi won we ra won. Gbere ti a ba so wipe "Omo ni yi," baba gbodo wa. Gbere ti a ba so wi pe "Oko ni yi," iyawo gbodo wa nbe. Gbere ti a ba so wipe, "Iranse ni yi," oga gbodo wa nbe. Gbere ti a ba so wipe, "Ina wa nbi," okuku gbodo wa nbe. Eyi ni won pe ni aye a fi we ra. A le fi nkan ye ra wa ni ipa nkan miran to jora. Sugbon aye miran wa ti a npe ni aye ainifarawe. Nibe oga ati omo odo, nkan kan na ni won. Ko si iyato. Bi o ti le je wipe ikan je oga ati pe elomiran nje omo ise, sugbon ipo won o yato..

Nitorina iwe ori keje ti Bhagavad Gita nfun wa ni imo die ni ipa ti aye ainifarawe, imo ti o ga julo. Bi a se le ni imo yi, iyen ni eni ti o ga julo nso, Eni Akoko, Olorun. Krishna ni Eni Akoko ti O ga julo.

īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ
sac-cid-ānanda-vigrahaḥ
anādir ādir govindaḥ
sarva-kāraṇa-kāraṇam
(Bs. 5.1)

Eyi ni itumo Krishna ti Oluwa Brahma fun wa ninu iwe re ti a npe ni Brahma-samhita, iwe ti o ni ase gidi gan. Sri Chaitanya Mahaprabhu ri iwe yi mu lati isale India, O si fi han awon omo eleyin Re ni igba ti O pada de lati irin ajo isale orile ede India. Nitori eyi a gba iwe yi, Brahma Samhita , gege bi iwe ti o je alase gidi gan ni. Eyi ni eto wa fun imoran. A ngba imoran lati odo awon alase. Oni kalu ku ngba imoran lati odo alase, sugbon awon alase ti o wopo. ati pe eto wa lati gba imoran lati odo awon alase yato die Eto wa lati gba imoran l'odo awon alase tumo si wipe oun na ngba a l'owo alase ti isàju. Eniyan ko le so ara re di alase. Iyen ko se se. Ba yen o je ibawon. Mo ti fun yin ni apeere yi ni igba pupo, wipe omo ma nko ran lowo baba re. Omo a bere l'owo baba, "Baba kini eroo machini yi?" baba na a so wipe, "Omo mi owon, a npe ni eroo agbohun" Bayi ni omode se ngba imoran l'owo baba, "Eroo agbohun re." Bee na ni igba ti omo na ba so fun elomiran pe "Eroo agbohun ni yi," o wa lare. Bi o tile je wipe o je omode, sibe sibe, nitori wipe o ti gba eko re l'owo alase, oro re je ododo. Bakanna, ti a ba gba imoran l'owo alase, bi mo ti le je omode, sugbon oro mi yi o si je ododo. Eto imoran wa ni yin fun oye. A ki da 'gbon. Iyen ni eto ti Bhagavad Gita fi sile ninu iwe ori Kerin, evaṁ paramparā-prāptam imaṁ rājarṣayo viduḥ (BG 4.2). Eyi ni a npe ni parampara, atowo-dowo ijinle...

imaṁ vivasvate yogaṁ
proktavān aham avyayam
vivasvān manave prāha
manur ikṣvākave 'bravīt
(BG 4.1)

Evaṁ paramparā. Nitorina a le ni imo ti o ga ju lo ni igba ti ti a ba gbo l'owo eni ti O ga ju lo. Ko si eni na ninu aye a fiwe yi ti o le fun wa ni imoran ti O ga julo. Iyen o le se se. Nitori na ni ibi bayi a ngba oye ti aye ti ko ni ifarawe, imoran ti o ga ju lo, l'owo Eni Akoko, Eni ti O ga ju lo. Eni ti O ga ju lo tumo si: anādir ādir govindaḥ (Bs. 5.1). Oun ni eni atilèwa, sugbon Oun ko ni abinibi; nitorina o ga ju. A o gbodo ro wi pe Oun ni idi kan lati odo elomiran. Iyen ni Olorun. Bee ni ninu ori iwe yi, nitorina, a so wipe, śrī bhagavān uvāca, Eni ti O ga ju lo... Bhagavan tumo si Eniti O ga ju lo, ti ko gbokan le eni kan kan.