YO/Prabhupada 0040 - Eyi ni Eni to gaju lo



Lecture on BG 16.8 -- Tokyo, January 28, 1975

Awon egbe gberun ati aimoye elemi ni won wa, bee na ni ninu okan onikaluku won, ni Oun fi se ijoko. Sarvasya cāhaṁ hṛdi sanniviṣṭo mattaḥ smṛtir jñānam apohanaṁ ca (BG 15.15). Oun se abojuto won bayi. Nitorina ti a ba ro wipe Oun je alakoso bi ti wa, iyen je aimonuro wa. Oun ni Alakoso. Alakoso ti o wa. Pelu imo ainipekun ati awon oluranwo aimoye, pelu agbara ti ko ni opin ni Oun fi nse akoso. Awon oni pasanga wonyi, won o le ro wipe eda kan wa ti o le ni agbara ti ko ni opin. Idi re ni yi ti won fi di oni pasanga. O je nkan ti won ko le ro ni pa re. Awon oni pasanga, won ko le foju inu wo.... Won ti fi okan si wipe, "Ti enikan ba je eda eniyan, o gbodo dabi eniyan bi emi' Ti emi o ba le se nkan yi. Bakanna Oun na o le se." Nitori idi eyi omugo ni won. Avajānanti māṁ mūḍhāḥ (BG 9.11). Won nfi ara won we Olorun. Bi o se je eda eniyan, bakanna, Olorun na je eniyan. Ko le ye. Awon iwe mimo Vedas fi ye wa wipe "Bi otile je pe Oun je enikan, Oun ni onse abojuto aimoye eniyan." Eleyi o ye won. Eko yo bahūnāṁ vidadhāti kāmān. Pe enikan soso, Oun se abojuto egberun lona egbe-gberun ati aimoye eniyan. Gbogbo wa, eni kokan wa, eniyan la je. Eniyan ni mi, eniyan ni iwo. Enikan ni eera, Enikan ni ologbo. Aja enikan ni se, ati kokoro na enikan ni. Awon igi na je enikan. Eni ko kan wa je enikan. Eni ko kan wa je enikan. Enikan miran tun wa. Oun ni Olorun, Krishna. Enikan yi ni onse akoso gbogbo awon aimoye eda eniyan. Eyi ni Vediki... Eko yo bahūnāṁ vidadhāti kāmān, nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām (Kaṭha Upaniṣad 2.2.13). Eyi ni iroyin.

Nitorina Krishna tun so ninu Bagavad Gita pe, ahaṁ sarvasya prabhavo, mattaḥ sarvaṁ pravartate, iti matvā bhajante māṁ... (BG 10.8). Nitorina, ni igba ti onigbagbo ba ni oye to jo ju wipe "Eyi ni Eni to Ga Ju lo, ti o je olori, ti o je alakoso, ti o si nse abojuto gbogbo nkan," oun o si jowo ara re Fun, yi o si di olufokansin Re.