YO/Prabhupada 0043 - Ipinlẹ ilana ni Bhagavad-gita yi



Lecture on BG 7.1 -- Sydney, February 16, 1973

Prabhupāda:

(mayy āsakta-manaḥ pārtha)
yogaṁ yuñjan mad-āśrayaḥ
asaṁśayaṁ samagraṁ māṁ
yathā jñāsyasi tac chṛṇu
(BG 7.1)

Ese kan ni yi lati inu iwe mimo Bhagavad Gita, bawo ni a se le losiwaju ninu imo Krishna, imo sinu Olorun. Iwe mimo Bhagavad Gita, opolopo yin ni e ti gbo ni ipa iwe yi. O je iwe ti o gbajumo ti won si fi se kika ni gbogbo ori ile aye. Daju daju ni gbogbo orile ede ni a ti le ri orisirisi iwe ti won ti se lori Bhagavad Gita. Beeni Bhagavad Gita ni ipinle ilana lori egbe imo sinu Oluwa wa. Nkan ti a nkede gege bi imo sinu Olorun, iyen nje Bhagavad Gita nikan. Kii se pe a ti da nkan titun sile. Imo sinu Olorun ti wa nbe lati igba adaye baye, sugbon o kere julo lati igba bi egberun marun odun s'eyin, nigba ti Krishna wa s'aye yi, Oun fun ra re ko ni ni pa imo sinu Olorun, awon imoran ti O si fi sile, oun ni Bhagavad Gita Oseni laanu pe, won ti lo Bhagavad Gita yi ni ilokulo ni ona pupo lowo awon ti won pe ra won ni oloye ati oluko. Awon egbe oni pasanga, tabi awon alaigbagbo pe Olorun nbe, won ti tumo Bhagavad Gita ni bo se wu won. Nigba ti mo wa ni Amerika, arabinrin kan bi mi leere lai yan ikan ninu awon iwe Bhagavad Gita ni ede Oyibo fun lati ka. Sugbon ni tooto emi o le yan eyikeyi ninu won, nitori itumo won ti ko bori mu. Iyen lo fun mi ni okan lati ko Bhagavad Gita Fun Ra Re Eyi ti a si wa se yi, Bhagavad Gita Fun Ra Re, ti wa ni tite si ta ni ile itewe Macmillan, ile iwe ti o ga ju lo lori aye. Won si lo ni dede. A ti te Bhagavad Gita Fun Ra Re ni odun 1968, ni ipa kekere O si nta bi nkan miran. Olori isowo ti egbe ateweta Macmillan se royin pe awon iwe wa nta pupo pupo; awon miran nse ataku. Ni aipe yi na, ni odun 1972, a te sode Bhagavad Gita Fun Ra Re, ni pi pe Egbe Ateweta Macmillan te sode adota egberun apeere ni te-siwaju, sugbon won ta won tan ninu osu meta won si nse eto lati te ipa keji.