YO/Prabhupada 0042 - Ijemu ti iribomi yi, E mu ni pataki



Initiation Lecture Excerpt -- Melbourne, April 23, 1976

Prabhupāda: Ninu iwe Chaitanya Caritamrta, nigbati Chaitanya Maharaprabhu nko Srila Rupa Goswami, o so wipe,

ei rūpe brahmāṇḍa bhramite kona bhāgyavān jīva
guru-kṛṣṇa-kṛpāya pāya bhakti-latā-bīja
(CC Madhya 19.151)

Awon nkan elemi, won ti ara kan lo sinu ara miran leyin iku won. won si nrin kaakiri lati aye kan si imiran nigba kan ni aye ti o rele, nigba miran ni aye ti o ga Bayi ni nkan se nlo. Eyi ni a npe ni saṁsāra-cakra-vartmani. Lale ana a nse alaye, mṛtyu-saṁsāra-vartmani. Oro yi kan na ni won lo, mṛtyu-saṁsāra-vartmani. Igbesi aye ti o soro gidi gan, lati ku. Onikaluku nberu lati ku nitoripe ko si eni ti o mo nkan to ma se le leyin iku. Awon ti won je omugo, eranko ni won. Gege bi won se npa awon eranko, eranko miran nro wipe "Emi wa laabo" Nitorina eni keni ti o ba ni ogbon kinkin ko ni fe ku rara lati gba ara miran. Ti a ko si mo iru ara ti a ma tun gbe wo. Nitorina ijemu ti iribomi ni pa ore ofe ti Olorun ati iranse re, e ma se fi sere rara E mu ni Pataki. O je oun aaye nla. Bija tumo si eso, eso ti ifokansin.

Nitorina nkan ki nkan ti e ba ti fi se ileri niwaju oluwa, niwaju oluko igbala yin, niwaju ina, niwaju awon Vaisnavas, e ma se yana kuro ninu ileri na. Bayi ni e se le duro gbangba ni nu ile aye emi yin: ko si ibapo sina, ko si eran jije, ko si tete tita, ko si oti mimu - nkan merin ti alodi si yi - ati sise akepe Hare Krishna - nkan kan ti a gba lofin. Nkan merin rara ati nkan eyo kan ti a ni beni. Eyi o se ile aye yin ni aseyori. O ro pu po. Ko si soro se. Sugbon māyā ni agbara pupo, o si ma mu ni yana nigba miran. Nitorina ti maya ba nmura lati mu wa yana, e s'adura saa si Olorun. "Gba mi sile . Mo yonda ara mi, t'emi tokan ni mo yonda ara mi, daabo bo mi ni pa ti anu Re." Olorun o si fun yin ni abobo. Sugbon e o gbodo tase aaye yi. Ebe mi ni yi. Mo fun yin ni gbogbo ibukun ati inu rere mi. Nitorina e je ki a mu aaye ti ifokansin, bhakti-latā-bīja. Mālī hañā sei bīja kare āropaṇa. Ni igba ti a ba ri eso rere, a gbodo gbin sinu ile. Apeere kan niyi, bi igba ti e ba ri eso to dara ti ododo rose ti ko ni ifarawe, e si ma gbin sinu ile, e o si ma won omi si die die. Yi o si dagba. Bakanna eso yi le se mu dagba ni pa wi won omi si. Kini omi wiwon yi? Śravaṇa kīrtana jale karaye secana (CC Madhya 19.152). wiwon omi si eso na, bhakti-latā, oun ni śravaṇa-kīrtana, igboran ati iyin logo. Nitorina e ma gboro lati odo awon Sanyasis ati Vaisnavas ni dee de ni pa re. E ma se tase aaye yi. Ebe mi ni yi. E se pupo.

Awon Omo Eleyin: Eyin Srila Prabhupada logo!