YO/Prabhupada 0060 - Emi ko le wa lati erupe



Room Conversation with Svarupa Damodara -- February 28, 1975, Atlanta

Prabhupāda: A so pe nigbati emi, eleda, wa nbe ninu atô. ti o ba si fi sinu ile omo obinrin, nigbana ni ara ma beere si dagba. Ni ibeere ni aye wa. Eyi wulo. Ati pe eda yi na je ipa ati ara eda atobiju. Nitorina ni atetekose ni Olorun wa. Janmādy asya yataḥ (SB 1.1.1). Athāto brahma jijñāsā. Nitorina a gbodo da imo yin sile ni aye aimowawu yi... Ati yato si eyi, kilode ti won o le se eda lati inu iyepe? Kini iwulo oro won? Wipe won o ti le se. Kini eri na pe eda elemi ti inu yepe wa? E le se ka ri.

Svarūpa Dāmodara: Eri won si wa ninu iwadi.

Prabhupāda: Ehn? Iyen ko logbon nnu. Ko logbon nnu. Eri yi, pe lati inu nkan elemi, ni eda ti nwa, eri ni yi, opolopo eri ni o wa. Omo eniyan, eranko, awon igi __ gbogbo nkan nti inu emi wa. Titi di isinsiyi, ko si eni ti o ri eniyan ti a se eda re lati inu okuta. Ko si eniti o ti ri iyen. Nigba miran a npe ni vṛścika-taṇdūla-nyāya. Se e mo eleyi? Vṛścika-taṇdūla-nyāya. Itumo Vṛścika ni akeeke, taṇdūla si tumo si iresi. Ni igba miran a ma ri ikete iresi, ti akeeke njade ninu re. Sugbon iyen o je wipe iresi ti bi mo akeeke. E o ti ri ni orile ede yin? Awa ti ri. Lati inu iresi, ikete iresi, akeeke kan, akeeke kekere, njade Otito re ni wipe, obi akeeke, mu eyin won sinu ikete iresi, ti eyin ba si setan, akeeke a jade, kii se pe iresi lo nmu akeeke jade. Nitori idi eyi won npe ni vṛścika-taṇdūla-nyāya. Vrscka tumosi akeeke, tandula si tumosi iresi. Nitorina, "Emi nwa lati inu erupe" - eyi la npe ni vṛścika-taṇdūla-nyāya. Emi ko le wa lati erupe. Yato si yen... Gege bi igbati emi ba wa, nkan elemi, ara a dagba, ara a yi pada tabi dagbasoke, bi e se ma nso. Sugbon ti omo na ba ku, tabi ti o ba jade bi alaisi ,nigba na ko si idagba soke. Nigbana yepe ndagba lori emi.