YO/Prabhupada 0063 - Ki ndi onilu Mrdanga okiki



Arrival Lecture -- Dallas, March 3, 1975

Bee ni inu mi dun pupo lati ri ayika ti o wa nibi yi. Olori eko ni imo nipa ifokansin Olorun. Eko gidi ni yen. Ti a ba ti le ni oye wipe " Krishna, Olorun ni eni ti Atobijulo. O tobi, gbogbo wa ni a si wa ni abe Re. Bee na ojuse wa ni lati se ise fun. Gbolohun meji yi, ti o ba ye wa, nigba na aye wa ti di pipe. Ti a ba tile ko bi a se nsin Olorun Krishna, bi a se nse ife Re, bi a se le Fun laso wo, bi a se nse Fun ni onje to dara, bi a se le se lagege yeye pelu awon ileke ati ododo, bi a se le fori bale Fun, bi a se le ke pe oruko Re, nipa sise bayi, ti a ba tile ronu lasan, laisi eko-kè-ko kan a o si di eni pipe ninu gbogbo aye. Ifokansin Olorun Krishna ni yi. Ko gba eko A-B-D O kan gba ki a ni lati ni irapada okan. Bee ni ti a ba ti beere si to awon omode yi lati igba kekere won... Awa ni anfani lati ni eko bayi lati kekere lodo awon obi wa.

Opolopo awon eni mimo ni won ma nwa baba mi wa sile. Baba mi je Vaishnava. Bi o se je Vaishnava, o fe ki emi na je Vaishnava. Igba ki gba ti eni mimo kan ba wa, ni o ma nbi won lere, "E jowo e fun omo mi ni ibukun ki o le di ojise Radharani" Adura re ni yen. Ko fi ekan gbadura miran ju yen lo. O si ko mi bi won se lu ilu mrdanga. Mama mi lodi si. Awon olukoni meji ni won wa - ikan lati ko mi ni A-B-D, ikeji lati ko mi ni bi won se nlu ilu. Bee ni oluko kan ma duro bi ikeji se nko mi bi won se nlu ilu mrdanga. Bee na ni Mama mi se ma binu wipe "Kini iru nkan yi" Kilode ti o nko ni lilu mrdanga? Kini o ma fi lilu mrdanga se?" Sugbon o dabi wipe baba mi fe ki ndi onilu mrdanga okiki lojo iwaju. (Erin) Nitorina mo je baba mi ni gbese pupo, idi re niyi ti mo se fi ya iwe mi, iwe Krishna, soto Fun. O wu be. O wu ki nje oniwasu Bhagavata, Srimad Bhagavatam. ati onilu mrdanga, ati ki ndi iranse Radharani.

Bee ni gbogbo obi gbodo ni ironu kan na; bi beko a o gbodo di baba ati iya. Idamoran lati inu iwe mimo ni yen. Ey je mi mo ninu Srimad Bhagavatam, Afa Karun, pitā na sa syāj jananī na sa syād gurur na sa syāt sva-jano na sa syāt. Nipa sise bayi, ipari oro ni wipe, na mocayed yaḥ samupeta-mṛtyum. Ti enikan ko ba le gba omoleyin re sile lowo ojiji iku, ko gbodo di guru, oluko igbala. A ko gbodo di baba tabi iya ti a ko ba le se. Nipa sise bayi, ore kankan, ibatan kan kan, baba kankan, kosi..., ti enikan ko ba le ko enikeji re bi o se le ni igbala lowo iku. Nitori be iru eko yi je oun ini lori le gbogbo aye. Ati pe ibi to rorun si ni wipe a le yera fun ide ninu ibi, iku, arugbo ara, ati aisan yi, nipa ati di eni ti nfi Olorun sokan.