YO/Prabhupada 0065 - Gbogbo won ni won ma ni idunnu



Arrival Lecture -- Gainesville, July 29, 1971

Alejo Arabinrin: Se aye wa fun awon miran ninu egbe yin awon ti won nsin Olorun lona ti ki setara ju pe ka ma ke pe oruko Olorun lojoojumo?

Prabhupada: Beeko, ona na ni pe, gege bi igba ti e ba won omi si abè igi, omi na a si lo kari sori awon ewe, awon eka ati owo igi, won a si maa tutu.. Sugbon ti e ba won omi sori ewe nikan, ewe na a gbe, awon owo igi na a si di gbi gbe. Ti e ba fi onje sinu, okun na a si lo kari sori ika, sori irun sori awon ekanna ati si gbogbo ara. Ti e ba si mu onje lowo lai fi sinu, a se ipadanu. Bee na gbogbo awon ise inurere won yi ja si ofo nitoripe ki se fun ife Olorun. Won nse iyanju ni gbogbo ona lati se ise fun omo araye, sugbon se ni won nse ibaje ninu iyanju ti ko nilari, nitoripe ko si ifokansin Olorun. Ti won ba si ko awon eniyan lati ni okan Olorun, nigbana gbogbo eniyan ni won ma ni idunnu lowo kanna. Eni keni ti o ba di omo egbe, enikeni ti o ba fi eti sile, enikeni ti o ba se idawopo - gbogbo won ni won ma ni idunnu. Bee na eto adanida ni eto wa. E ni ife Olorun, ti e ba si je amoye ninu ife Olorun, tinu tinu ni e ma fi ni ife gbogbo eniyan. Bi eni ti o ni okan Olorun, nitoripe o ni ife Olorun, o si ni ife awon eranko na. O ni ife awon eye, awon eranko igbo, gbogbo nkan. Sugbon fun awon aserere iru kiru, ife tumo si won ni ife awon omo eniyan kan, sugbon won npa awon eranko. Kilode ti won o ni'fe awon eranko? Nitori ibawon. Sugbon eni ti o ni okan Olorun ko ni pa eran lai lai, tabi ko tile fi iya je won. Bee na iyen ni ife ayeraye. Ti o ba ni ife arakunrin tabi arabinrin re, iyen ki ise ife gbogbo aye. Ife gbogbo aye tumo si wipe e ni ife eni kokan. A le se idagbasoke ife gbogbo aye yi nipa ifokansin Olorun, kiise nipa ona miran. Alejo

Arabinrin: Mo mo awon kan ninu awon olufokansin ti won ti ni lati yonda awon ojumo won, ka ma so ju beyen lo, pelu awon obi won ti aye yi, eyi si fun won ni idaro bakan, nitoripe k'oye awon obi won. Nissinyi, kini e so fun won lati ro won lenu?

Prabhupada: O dara, omo odokunrin ti o wa ninu ijo ifokansin Oluwa, o nse ise ti o dara julo fun awon obi, ara-ile, omo-ilu ati agbegbe re. Laije olufokansin olorun, ise wo ni won nse fun awon obi won? Ni igba pupo se ni won npinya. Sugbon, gege bi Prahlada se je onigbagbo nla. ti baba re si je kaferi to lokiki, ti o je be gan de bi ti baba re fi pade iku lowo Nrsimhadeva, sugbon Pralada Maharaja, nigbati Oluwa fun lase ko bere ibukun kan, o so wipe "emi ki ise onisowo, Alagba, pe nipa sise ise kan fun Yin emi a tun gba ere pada. E jowo e se mi ni gafara. Eyi te Nrsimhadeva lorun pupo : "Eyi ni onigbagbo ododo". Sugbon onigbagbo ododo yi beere lowo Olorun, "Oluwa mi, baba mi je kaferi, o si ti se opolopo ese, nitorina mo bebe ki baba mi le ni igbala." Nrsimhadeva ba so wipe, "Baba re ti ni igbala nitoripe iwo je omo re. Lai tile fojuto awon aise dede re, o ti ni igbala, nitori wipe iwo je omo re. Ki ise baba re nikan, sugbon baba baba re, baba re na titi di ipa keje seyin, gbogbo won ni won ti ni igbala." Bee ni ti vaisnava ba ya si inu idile kan, ki se baba re nikan ni yi o gba la, sugbon baba re, baba baba , ati be be-lo. Sugbon iyen ni ise ti o dara julo fun awon ara-ile, lati di eni ti oni okan Oluwa. Daju daju, eyi ti sele. Ikan ninu awon omo eleko mi, Kartikeya, iya re ni ife pupo fun egbe to be to fi je wipe igba ki igba ti o ba fe ri mama re Mama a so wipe, " Joko.. Mo nlo si ile ijo." Iru ibatan ti o wa larin won ni yen Sibe sibe, nitoripe odomokunrin yi, o je e ni ti o fokan sin Olorun o si ma nba iya re soro nipa Olorun ni aimoye igba. Igba ti iku sunmole fun iya, ni o ba bere lowo omo re, " Olorun Krishna re da ? O wa nbi? " Owo kan na lo si ku ni kia kia. Eyi tumo si wipe, o se iranti Olorun ni igba ikeyin re, o si ri igbala lese kanna Eyi je mi mo ninu iwe Bhagavad Gita, yaṁ yaṁ vāpi smaran loke tyajaty ante kalevaram (BG 8.6). Ni ojuju iku ti a ba se iranti Olorun, ni igba na ile aye ti je seyori. Bee na iya yi, nitori omo re, omo ti o je olufokansi Olorun, o ri igbala, laije pe oun fun rara re wa sinu ifokansin Olorun. Anfani na ni yi.