YO/Prabhupada 0066 - Oyeka gba oun ti Oluwa bafe

From Vanipedia
Jump to: navigation, search
Go-previous.png Previous Page - Video 0065
Next Page - Video 0067 Go-next.png

We Should Agree to Kṛṣṇa's Desires - Prabhupāda 0066


Lecture on BG 16.4 -- Hawaii, January 30, 1975

Nisinyi iyan wa ni ti a ba fe di olufokansin. tabi ti a ba fe duro bi elesu. Iyen ni asayan temi. Olorun so wipe " Iwo fi ise esu yi sile ki o si jowo ara re fun me. Iyen ni ife Olorun. Sugbon ti e ko ba finusokan pelu ife Olorun, ti e ba fe gbadun ife ara yin, bi bakanna, Olorun o lodi si, O ma fun yin ni awon ohun elo. Sugbon iyen ko dara. A gbodo finusokan fun awon ife Olorun. A o gbodo gba awon ife wa laye, ife satani, lati dagba soke. Iyen ni a npe ni tapasya. A gbodo fi awon ife wa sile. Iyen ni a npe ni irubo. A gbodo gba ife Olorun nikan. Iyen ni imoran ti Bhagavad Gita. Ki ise ife Arjuna lati ja, sugbon o je ife Olorun lati ja, o je nkan idakeji. Lopin gbogbo re Arjuna finusokan pelu ife Olorun; "Bee ni", kariṣye vacanaṁ tava (BG 18.73): "Bee ni, emi yi o se ife Re. Iyen ni ifokansin.

Eyi ni iyato larin ifokansin ati ayanmo. Karma tumo si pe ki nrise awon nkan ti mo fe, bhakti si tumo si wipe ki awon ife Olorun se se. Iyen lo je iyato. Nisinyi e le sayan yin, boya e fe ki awon nkan ti e fe se se tabi ti e ba fe ki ife ti Olorun se mu se. Bi e ba se ipinnu yin lati je ki ife Olorun se se, nigba na ile aye yin di aseyori. Iyen ni aye isokan Oluwa wa. " Ife Olorun ni; Mo gbodo se. Emi o ni se nkankan fun rara mi." Iyen ni aye Vrndavan. Awon ti won ngbe ninu ilu Vrndavan, won ngbiyanju lati se ife Olorun. Awon oluso-agutan, awon odo malu, awon malu, awon igi, awon ododo, omi, awon gopis, awon agba ilu, Iya Yashoda, Nanda, gbogbo won ni won se ise lati mu ife Olorun Krishna ni si se. Bi Vrndavan se ri ni yen. Bee na e le yi ile aye yi si Vrndavana. ti e ba ti pésé silè lati fohunsokan se ife Olorun. Iyen ni Vrndavan. Ti e ba si fe se ife ti yin, iyen ni ile aye asan. Eyi ni iyato na ti o wa larin nkan asan ati ti emi.