YO/Prabhupada 0073 - Vaikuntha tumo si ibi ti kosi iyonu
Lecture on BG 10.2-3 -- New York, January 1, 1967
Ki se wipe ninu egbe yi e gbodo se eleyi. E le ko bi won se nse nkan yi, e si le se nile. Eyin na le se iru awon ounje yi, ounje to dara, nile yin, fi se ore fun Olorun. Iyen ko soro rara. Ojojumo ni awa nwa ounje ti a si ma nfi se ore fun Olorun pelu adura,
- namo brahmaṇya-devāya
- go-brāhmaṇa-hitāya ca
- jagad-dhitāya kṛṣṇāya
- govindāya namo namaḥ
O pari. Ko soro rara. Olukaluku lo le se ounje ti o si le fi se ore fun Olorun ko to jee. nigba na e le joko pelu awon ojulumo tabi awon ore ki e si korin niwaju iworan Krishna.
- Hare Kṛṣṇa Hare Kṛṣṇa Kṛṣṇa Kṛṣṇa Hare Hare
- Hare Rāma Hare Rāma Rāma Rāma Hare Hare
ki e si gbe igbesi aye mimo. E wo iyorisi re. Ti gbogbo ile, ati gbogbo eniyan, ba gba ilana bi a se nloye Olorun, a di... Gbogbo aye kari lo ma di Vaikuntha. Vaikuntha tumo si ibi ti kosi aibale-okan. Vaikuntha. Vai tumo si laisi, Kuntha si tumo si aibale-okan. Ile aye yi ogun ni. Sadā samudvigna-dhiyām asad-grahāt (SB 7.5.5). Nitori pe a ti gba igbesi aye ti o wa fun igba die yi, nitori na a nse aifokan-bale ni gbogbo gba. Idakeji eyi ni o wa ni ipinle orun, ni bi ti won pe awon aye ibe ni Vaikuntha. Vaikuntha tumo si ni bi ti ko si iyonu.
Gbogbo wa ni a fe yege ninu aifokan-bale. Olukaluku nse yanju lati gba rara re sile ninu hila-hilo, sugbon ko mo bi o se le jade ninu iyonu yi. Wiwa abo ninu imu oti para ko wu lo lati gba eniyan sile ninu aibale okan. O je oogun. O je igbagbe. Ni igba miran, fun akoko kan a le gba gbe gbogbo nkan, sugbon to ba ya nigba ti e ba pada wa sinu oye yin aibale okan na ati awon nkan miran wa nbe. Nitori be eyi ko le ran yin lowo. Ti e ba fe ni idasile ninu awon nkan ti aibale-okan ti e si ba fe gidi gan aye ailopin pelu ayo ati imo, eyi ni ilana na, nigba na. Ilana na ni yi. E gbodo ni oye Olorun. Won fi se ni awiye nibi wipe na me viduḥ sura-gaṇāḥ (BG 10.2). Ko si eniti o le ni oye. Sugbon ona kan wa. Sevonmukhe hi jihvādau svayam eva sphuraty adaḥ (Brs. 1.2.234). Ona na ni yi. Ni opolopo ibi ni won ti se alaye ilana yi ninu Srimad Bhagavatama ni ona miran. Gege bi ni ipa kan won fi se ni mimo wipe:
- jñāne prayāsam udapāsya namanta eva
- jīvanti san-mukharitāṁ bhavadīya-vārtām
- sthāne sthitāḥ śruti-gatāṁ tanu-vāṅ-manobhir
- ye prāyaśo 'jita jito 'py asi tais tri-lokyām
- (SB 10.14.3)
O je afa ese ti o dara gan. Won so nibe wipe, ajita, ko si eni ti o le mo. Oruko miran fun Olorun ni Ajita. O tumo si Eniti enikan o le segun. Ko si eni ti o le sumo. Nitorina oruko re nje Ajita. Bee na ajita di eni ti won segun. Ajita jito 'py asi. Bi o ti le je wipe Olorun je eniti a ko le ri idi Re, beni O si je eni ti a ko le bori, sibe, O di eniti a segun. Bawo? Sthāne sthitāḥ.