YO/Prabhupada 0074 - Kilode ti e gbodo je awon eranko



Lecture on BG 4.21 -- Bombay, April 10, 1974

Gbogbo nkan ni won se ni alaye ninu Bhagavad-Gita Bhagavad-Gita o ni wipe "Ka fi ategun gbe ." Rara o. Bhagavad-Gita so wipe, annād bhavanti bhūtāni (BG 3.14). Anna. Anna tumo si awon eso ounje. Eso ounje je nkan ti a ko le se alaini. Annād bhavanti bhūtāni. Bhagavad-Gita ko so rara wipe "iwo o gbodo jeun. E kan f'ategun gbe ki e si ma se yoga." Rara. Sugbon a gbodo jeun niwonsi. Iyen ni won se lofin. Yuktāhāra-vihārasya. A ko gbodo jeun l'aje ju, tabi ko kere ju. Ati nirāśīḥ. Nirāśīḥ tumo si lai ni ife inakuna. Nisinyi ife wa fun igbadun ara nposi pupo pupo. Iyen ko nse dede. Ti e ba fe se ise aye ni asepe, eyi ni won npe ni tapasya.

A le ni ero, sugbon e o le ma ni ero kero. Olukaluku lo ni otun lati jeun, koda awon eranko paapa. Olukaluku lo ni otun yi.. Sugbon nitoripe a nlero lati gbadun pupo. nitori idi eyi a o fun awon eranko l'aye lati se aye won ni bo se ye. kuku, se ni anfi awon eranko je. Eleyi ko l'ase. Eyi ni a npe ni nirasih. Kilode ti e gbodo je awon eranko? Iyen ki se aye olaju. Ni igbati ko si ounje, nigba ti won si je ara oko, won le je awon eranko. nitoripe won o mo bi won se d'ako ounje. Sugbon nigba ti ilaju ti de si arin awon omo eniyan, o le d'ako awon opo ounje to dara. o le s'eto awon malu, nipo ti o ma fi won je. O le ni miliki, miliki ti o sôpô. A le se orisirisi ounje lati inu miliki ati awon oka eso. Nitorina a ko gbodo l'ero kero lati gbadun pupo si.

Won si wa so nibi pe, kurvan nāpnoti kilbiṣam. Kilbisam tumo si ere igbesi aye elese. Kilbisam. Ti a ko ba l'ero nkan ju bi a se nilo, ni igba na ni a o ni lowo ninu oran. lowo ninu ipinu ese, kurvan api, bi o ti le je pe o nse ise. Bi e ba se nse se, nipa mimo se tabi nipa aimo, dandan ni pe e ma se nkan to ya sodi, ni paapa nkan elese, sugbon ti ero okan yin ba je bi e se le gbe igbesi aye to dara, nigba na kurvan nāpnoti kilbiṣam. Igbesi aye wa gbodo je lai si ere ese. Bi beko a ni lati jiya. sugbon won o ni igbagbo, bi o ti le je pe won nri opolopo ti won wa ninu aye elegbin. Nibo ni won ti nbo, ninu awon 8, 400, 000 eda aye? Awon iru ru eda pupo ni won gbe ile aye elegbin. Ni idaju, eranko na tabi eda alaye na o mo. sugbon awa omo eniyan, a gbodo mo idi ti o fi je igbesi aye to legbin. Iruju maya ni yi.

Ti eniyan ba ti le je, gege bi ... elede ngbe ninu idoti, o njegbe, sibe na, o nrora ri ni idunu pupo, o si nyodi yokun nitorina. Nigba ti eyan ba ni idunnu, "Inu mi dun pupo," a sanra si. bee na le se ma ri awon elede won yi, won sanra gan, sugbon kini won nje? Won njegbe won si ngbe nibi to legbin. Sugbon nro wipe " Inu wa dun pupo." Bee na etan maya tun ni yi. Enikeni to ba ngbe ninu igbesi aye elegbin, nipa iruju maya, o nro wipe nkan lo dede, pe oun wa dara dara. Sugbon eni ti o wa ni ipo giga, o ri wipe o ngbe ninu irinilara elegbin pupo.

Bee na iruju yi wa nbe, sugbon nipa imo, nipa egbe rere, nipa gbigba ilana lowo iwe mimo, lowo guru, lowo awon eniyan mimo, a gbodo l'oye iriri aye ki a si fi se iwa wu. Bee ni Olorun fi eyi se imoran, wipe nirasih, a o gbodo ni ero kero ife ki fe. ju awon nkan ti a nilo l'aye. Eyi ni a npe ni nirasih. Nirasih. Itumo miran ni wipe ko ni ife jaye jaye pupo l'okan. Iyen si se se nigba ti o ba wa ninu oye kikun wipe "Emi ki se ara yi. Emi okan ni emi nse. Nkan iwulo fun mi ni bi mo se le ni idagbasoke ninu imo ti émi. Igba yen lo le di nirasih. Awon nkan ero fun tapasya niyi, awe, ikorani nijahun.

Awon eniyan ti gbagbe nisinyi. Won o mo awon nkan ti a fi para mo. Sugbon nkan ti igbesi aye eniyan wa fun niyi. Tapo divyaṁ putrakā yena śuddhyet sattvaṁ yena brahma-saukhyam anantam (SB 5.5.1). Awon imoran ti iwe mimo niyi. Igbesi aye omo eniyan wa fun tapasya. Tapasya si...

Nitorina ninu asa Vediki ibere igbesi aye ni tapasya, brahmacari, brahmacari. A ran omo ile iwe lo si gurukula lati lo ko brahmacarya. Eyi ni tapasya, ki se aye to rorun. Sun lori ile, lati ma lo se itore aanu fun guru lati idile si idile.. Sugbon ko nre won. Nitoripe won je omode, ti won ba ko won ni ikora-janu won yi, won a lemi lati fi se iwa wu. Won npe gbogbo obirin ni "Mama". "Mama fun mi l'ore aanu" Won a si pada wa si odo guru. Gbogbo nkan ni se ti guru. Eyi ni igbesi aye brahmacari. Eyi ni tapasya. Tapo divyam (SB 5.5.1). Iyen ni ilaju Vediki wipe awon omode gbodo s'eyi lati ibeere igbesi aye won. won gbodo ko won ni tapasya, brahmacarya. Ikora-nijanu. Eni ti o nse brahmacari ko gbodo foju ri odo mobirin. Iyawo guru tabi alufa na je odo-mobirin, ko le lo ri iyawo guru. Eyi je awon nkan ti a lodi si. Nisinyi nibo lati ma ri iru brahmacarya na? Ko si brahmacari. Igba Kai ni yi. Ko si tapasya.