YO/Prabhupada 0076 - E o ri Olorun nibi gbogbo
Ratha-yatra -- San Francisco, June 27, 1971
Nigba ti awon oju wa ba di yiya si mimo nipa ife Olorun, a le Ri nibi gbogbo. Iyen ni imoran ti awon iwe mimo, sastras. A ni lati se agbekale agbara riri wa nipa sise ife ti Metalokan. Premāñjana-cchurita bhakti-vilocanena (Bs. 5.38). Nigba ti eniyan ba ti fese mule ninu idagbasoke isokan Olorun, o le ri Oluwa ni gbogbo igba ninu okan re ati nibi gbogbo ti o ba lo. Bee na egbe isokan Olorun yi je igbiyanju lati ko awon eniyan bi a se le ri Olorun, bi a se le ri Krishna. Olorun se ri ti a ba fi se iwa wu. Gege bi Olorun se so wipe, raso 'ham apsu kaunteya (BG 7.8). Olorun so wipe, "Emi ni adun omi;" Olukaluku wa, a nmu omi l'ojojumo. ki se l'ekan, l'eemeji, meta tabi to tun ju yen lo. Bee na gege ti a ba mu omi, ti a ba si ro wipe Olorun ni adun omi yi. kia kia ni a di olusokan Olorun. Lati di olusokan Olorun ki se nkan to soro. A kan ni lati fi se iwa wu.
Gege bi appere yi bi a se le fi isokan Olorun se wa wu. Nigba ku gba ti e ba mu omi, kete ti e ba ti ni itelorun, ti e ba ti pa oungbe yin, lesekese ti ba ro wipe oungbe yi, agbara ti o npa ni Olorun. Prabhāsmi śaśi sūryayoḥ. Olorun so wipe, " Emi ni imole-oorun. Emi ni imole- osupa." Bee na toju ba ti mo, gbogbo wa l'anri imole-oorun. Kété ti e ba ti ri imole-oorun, lesekese ni e ma ranti Olorun, "Olorun ni yi." kété ti e ba ti ri imole-osupa, lesekese ni e ma ranti "Olorun ni yi." Ni ona yi, ti e ba fi se iwa wu, opolopo apeere ni o wa nibe, opolopo apeere ninu Bhagavad-Gita, lori iwe keje, ti e ba fi pelepele ka won, bi a se nfi isokan Olorun se wa wu. Ni igba na, nigba ti e ba ti dagba ninu ife Olorun, e o ri Olorun ni bi gbogbo. Ko s'eni ti o ni lati ran yin lowo lati ri Olorun, sugbon Olorun a fi ara Re han yin, nipa ifokansin yin, nipa ife yin. Sevonmukhe hi jihvādau svayam eva sphuraty adaḥ (Brs. 1.2.234). Olorun, nigbati ọkan ba wa ni iṣẹ sise, nigbati eniyan ba mo pe, "Emi je iranse ayeraye ti Krishna, tabi Olorun," Olorun a si ran yin lowo bi e se le Ri. Bhagavad-Gita so nipa eyi.
- teṣāṁ satata-yuktānāṁ
- bhajatāṁ prīti-pūrvakam
- dadāmi buddhi-yogaṁ taṁ
- yena mām upayānti te
- (BG 10.10)