YO/Prabhupada 0087 - Ofin awon ohun elo ti Iseda



Sri Isopanisad Invocation Lecture -- Los Angeles, April 28, 1970

Bee ni. Gbogbo ohun ti o wa ni ile aye yi, ni won ni akoko. Be na ni ninu akoko yi iru ayipada mefa lo wa. Akoko ni ibisaye, ki o si dagba, ki o si duro, a tun wa tun ra re-bi, nigba na ni irehin, ati ipare. Eleyi ni ofin awon ohun elo ti iseda. Ododo wa s'aye, gege bi eehu, o si dagba, o ba duro fun bi ojo meji tabi meta, lo ba so eso, itunbi, lo ba si ndi gbigbe die die, o si pari. (ni ikoko) E joko sile ba yi. Bee ni a npe eleyi ni ṣaḍ-vikāra, iru ayipada mefa. Bee ni e ko le da eyi duro nipa ka-rohun-wi imo ijinle ti aye. Rara o. Eyi ni avidyaa. Awon eniyan nse iyanju lati gbara won sile, bee ni won se nsoro omugo pe nipa imo ijinle eniyan a di alaiku. Awon ara Russia so bayi. Bee ni eyi je avidyaa, aimokan. E ko le da ilana ti awon ofin ile aye duro. Nitorina won so ninu Bhagavad Gita wipe, daivī hy eṣā guṇamayī mama māyā duratyayā (BG 7.14). Awon ilana ohun elo ti iseda, eyi ti o je akojopo awon agbara meta - sattva-guna, rajo-guṇa, tamo-guṇa... Tri-guṇa. Itumo miran fun guna ni okun. Gege bi e ti se ri okun, won lo won po ni ona meta. L'akôkô okun tinrin, leyin na meta papô, won yi won ka, leyin na won tun ko meteta won yi won po, meteta lekansi. A di lile gidi gan. Bee ni awon agbara meta yi, sattva, raja, tamo-guna, won ti yi po. Leekansi won se irugbin, won tun yi po, won tun yi po. Ni ona yi fun igba ogorin-lekan ni won se d'ayidayida. Bee ni gunamayi maayaa, se ndi yin ni ide pupo pupo si. Bee ni e ko le ja de ninu ide ti ile aye yi. Idemole. Nitori eyi won npe ni apavarga. Ilana isokan Olorun yi tumo si wipe ka fi ona pavarga pare.

L'ana mo ns'alaye itumo nkan ti pavarga je fun Gargamuni. Pavarga yi tumo si ni ila ti abidi pa Se e mo, awon ti won se eko devanaagari yi. A-bi-di devanaagari wa, ka kha ga gha na ca cha ja jha na. Ni ona yi ona maarun, ila kan. Nigba na ni ese karun, o kan pa pha va bha ma. Bee ni pavarga yi tumo si pa. L'akoko ni pa. Pa tumo si parava, iparun. Gbogbo eniyan ngbiyanju, won se ijakadi gidigidi gan lati wa laaye, sugbon won ni iparun. Akoko, ni pavarga. Pa tumo si parava. Pha tun tele. Pha tumo si riru ose Gege bi esin, nigbati o ba se nse ise lile, e ri pe a ma po ito funfun lenu bi ose, awa na ni igba miran, ti o ba re wa gidi leyin ise lile, ahan a di gbigbe a si ma ruto ose. Bee ni gbogbo eniyan se nse ise kara kara ki won ba le ni igbadun, sugbon won pade iparun. Pa , pha, ati ba na. Ba tumo si igbekun. Bee na pa l'akoko, pha ni keji, igbekun wa tele niketa, o wa kan ba, bha. Bha tumo si lilu, iberu. O tun kan ma. Ma tumo si mrtyu, tabi iku. Bee ni ilana isokan Olorun yi je apavarga. Apa. A tumo si ko si. Pavaraga, awon eyi je aami ti ile aye yi, ti e ba si fi "a" yi kun, a-pavarga, iyen tumo si ipare